Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 71:1-6

71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
    dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò mi,
    níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
    nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
    ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
    Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.

Jeremiah 6:1-19

Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbèkùn

“Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò!
    Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu,
Ẹ fọn fèrè ní Tekoa!
    Kí ẹ gbé ààmì sókè lórí Beti-Hakeremu!
Nítorí àjálù farahàn láti àríwá,
    àní ìparun tí ó lágbára.
Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run,
    tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.
Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n.
    Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,
    olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”

“Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun!
    Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán!
Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,
    ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.
Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́
    kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”

Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀
    kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.
Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,
    nítorí pé ó kún fún ìninilára.
Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,
    náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.
Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀;
    nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.
Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀
    kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,
kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,
    tí kò ní ní olùgbé.”

Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli
    ní tónítóní bí àjàrà;
na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i
    gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”

10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti
    tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni
yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn
    ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,
    wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
11 Èmi kún fún ìbínú
    Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra.

“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti
    sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra
wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò
    mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó
    tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12 Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,
    oko wọn àti àwọn aya wọn,
nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi
    sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”
    ni Olúwa wí.
13 “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí
    ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn
ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,
    àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀
    sì kún fún ẹ̀tàn.
14 Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn
    mi bí ẹni pé kò tó nǹkan.
Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’
    nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
15 Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà
    ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò
ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú
    Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín
àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn
    lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,”
    ni Olúwa wí.

16 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò,
    ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́, ẹ béèrè
ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ,
    ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.
    Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’
17 Èmi yan olùṣọ́ fún un yín,
    mo sì wí pé:
‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’
    ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’
18 Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè
    kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí
    ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.
19 Gbọ́, ìwọ ayé!
    Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,
    èso ìrò inú wọn,
nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi,
    wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.

Heberu 12:3-17

Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.

Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. (A)Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,

“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa,
    kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí:
Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí,
    a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”

Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.

12 (B)Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; 13 (C)“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.

Ìkìlọ̀ lòdì sí kíkọ Ọlọ́run

14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa: 15 (D)Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “gbòǹgbò ìkorò” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. 16 (E)Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. 17 (F)Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.