Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Maskili ti Asafu.
74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
2 Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà
Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
3 Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.
4 Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;
5 Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
láti gé igi igbó dídí.
6 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
7 Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́
8 Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.
9 A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
kò sí wòlíì kankan
ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!
12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.
13 Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.
18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.
Ègún àti ìdájọ́
8 Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé
tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀
tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù
tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.
9 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:
“Ó dájú pé àwọn ilé ńláńlá
yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.
10 Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú
ìkòkò wáìnì kan wá,
nígbà tí òṣùwọ̀n homeri kan yóò mú
agbọ̀n irúgbìn kan wá.”
11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde
ní kùtùkùtù òwúrọ̀
láti lépa ọtí líle,
tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́
títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.
12 Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,
ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,
ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
13 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò
lọ sí ìgbèkùn
nítorí òye kò sí fún wọn,
ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ
yóò sì gbẹ.
14 Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,
ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,
nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí
pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.
15 Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
17 Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
18 Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,
àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,
19 sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,
jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,
jẹ́ kí ó súnmọ́ bí
jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,
kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”
20 Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,
tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,
tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.
21 Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn
tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.
22 Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu
àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
23 tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.
Ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò
4 Olùfẹ́, ẹ má ṣe gba gbogbo ẹ̀mí gbọ́, ṣùgbọ́n ẹ dán àwọn ẹ̀mí wò bí wọn ba ń ṣe tí Ọlọ́run: nítorí àwọn wòlíì èké púpọ̀ tí jáde lọ sínú ayé. 2 Èyí ni ẹ ó fi mọ Ẹ̀mí Ọlọ́run: gbogbo ẹ̀mí tí ó ba jẹ́wọ́ pé, Jesu Kristi wá nínú ara, ti Ọlọ́run ni: 3 (A)Gbogbo ẹ̀mí tí kò si jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wà nínú ara, kì í ṣe tí Ọlọ́run: èyí sì ni ẹ̀mí aṣòdì sí Kristi náà, tí ẹ̀yin ti gbọ́ pé ó ń bọ̀, àti nísinsin yìí ó sì tí de sínú ayé.
4 Ẹ̀yin ọmọ mi, ti Ọlọ́run ni yín, ẹ̀yin sì tí ṣẹ́gun wọn: nítorí ẹni tí ń bẹ nínú yin tóbi jú ẹni tí ń bẹ nínú ayé lọ. 5 (B)Tí ayé ni wọ́n, nítorí náà ni wọn ṣe ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ti ayé, ayé sì ń gbọ́ tí wọn. 6 (C)Ti Ọlọ́run ni àwa: ẹni tí ó bá mọ Ọlọ́run, ó ń gbọ́ tiwa; ẹni tí kì í ṣe ti Ọlọ́run kò ni gbọ́ ti wa. Nípa èyí ni àwa mọ ẹ̀mí òtítọ́, àti ẹ̀mí èké.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.