Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Tí ohùn “Má ṣe parun.” Ti Dafidi. Miktamu.
58 Ẹ̀yin ha ń sọ òdodo nítòótọ́
ẹ̀yin ìjọ ènìyàn?
Ǹjẹ́ ẹ̀yin ń ṣe ìdájọ́ tí ó ṣe títọ́
ẹ̀yìn ọmọ ènìyàn?
2 Bẹ́ẹ̀ kọ́, nínú ọkàn yín ẹ̀yìn ń gbèrò àìṣòdodo,
ọwọ́ yín sì tú ìwà ipá jáde ni ayé.
3 Ní inú ìyá wọn wá ni ènìyàn búburú tí ṣìnà,
lójúkan náà tí a ti bí wọn, wọn a máa ṣèké.
4 Oró wọn dàbí oró ejò,
wọn dàbí adití ejò paramọ́lẹ̀ tí ó di ara rẹ̀ ni etí,
5 tí kò ní gbọ́ ìpè àwọn atunilójú,
bí ó ti wù kí ó máa fi ọgbọ́n ṣe ìtujú tó.
6 Ká eyín ẹnu wọn, Ọlọ́run;
ní ẹnu wọn,
ká ọ̀gàn àwọn ọmọ kìnnìún, Olúwa.
7 Jẹ́ kí wọn parẹ́ bí omi tó ń sàn lọ;
nígbà tí ó bá fa ọfà rẹ̀, kí ọ̀kọ̀ wọn kí ó ṣẹ́.
8 Jẹ́ kí wọn rí bí ìgbín tí rẹ̀ dànù tí ó sì ṣègbé
bí ọmọ tí oṣù rẹ̀ kò pé, kí wọn má ṣe rí oòrùn.
9 Kí ìkòkò yín kí ó tó mọ ìgbóná ẹ̀gún;
bóyá ní tútù tàbí ní gbígbẹ, yóò fi ìjì gbá wọn lọ.
10 Olódodo yóò yọ̀ nígbà a bá ń gbẹ̀san wọn,
nígbà tí wọn bá wẹ ẹsẹ̀ wọn nínú ẹ̀jẹ̀ ènìyàn búburú.
11 Àwọn ènìyàn yóò wí pé,
“Lóòtítọ́ èrè àwọn ń bẹ fún olódodo;
lóòtítọ́ òun ni Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ ní ayé.”
23 “Báwo ni ìwọ ṣe wí pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́;
Èmi kò sá à tẹ̀lé àwọn Baali’?
Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì;
wo ohun tí o ṣe.
Ìwọ jẹ́ abo ìbákasẹ
tí ń sá síhìn-ín sọ́hùn-ún.
24 Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tí ń gbé aginjù
tí ń fa ẹ̀fúùfù ìfẹ́ sí i mu rẹ,
ta ni ó le è mú dúró ní àkókò rẹ̀?
Kí gbogbo àwọn akọ ẹran tí o wá a kiri kì ó má ṣe dá ara wọn lágara,
nítorí wọn yóò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.
25 Dá ẹsẹ̀ dúró láìwọ bàtà,
àti ọ̀fun rẹ nínú òǹgbẹ.
Ṣùgbọ́n ìwọ wí pé, ‘Asán ni!
Èmi fẹ́ràn àwọn ọlọ́run àjèjì,
àwọn ni èmi yóò tọ̀ lẹ́yìn.’
26 “Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójútì olè nígbà tí a bá mú u,
bẹ́ẹ̀ náà ni ojú yóò ti ilé Israẹli—
àwọn ọba àti àwọn ìjòyè wọn,
àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.
27 Wọ́n sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni baba mi,’
àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’
wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi,
wọn kò kọ ojú sí mi
síbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro,
wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’
28 Níbo wá ni àwọn ọlọ́run tí
ẹ ṣe fúnrayín ha a wà?
Jẹ́ kí wọ́n wá kí wọ́n sì
gbà yín nígbà tí ẹ bá
wà nínú ìṣòro! Nítorí pé
ẹ̀yin ní àwọn ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́
bí ẹ ti ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Juda.
29 “Kí ló dé tí o ṣe wá ń fi ẹ̀sùn kàn mí?
Gbogbo yín ni ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi,”
ni Olúwa wí.
30 “Nínú asán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín,
wọn kò sì gba ìbáwí.
Idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run,
gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.
31 “Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsi ọ̀rọ̀ Olúwa:
“Mo ha ti di aginjù sí Israẹli
tàbí mo jẹ ilẹ̀ olókùnkùn biribiri?
Èéṣe tí àwọn ènìyàn mi ṣe wí pé,
‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri;
àwa kì yóò tọ̀ ọ́ wá mọ́?’
32 Wúńdíá ha le gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀,
tàbí ìyàwó ohun ọ̀ṣọ́ ìgbéyàwó rẹ̀?
Síbẹ̀, àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi ní ọjọ́ àìníye.
33 Ìwọ ti jẹ́ ọlọ́gbọ́n tó nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́!
Àwọn obìnrin búburú yóò kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà rẹ
34 Lórí aṣọ rẹ ni wọ́n bá ẹ̀jẹ̀
àwọn tálákà aláìṣẹ̀
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò ká wọn mọ́
níbi tí wọ́n ti ń rùn wọlé
35 Síbẹ̀ nínú gbogbo èyí
ìwọ sọ wí pé, ‘Èmi jẹ́ aláìṣẹ̀
kò sì bínú sí mi.’
Èmi yóò mú ìdájọ́ mi wá sórí rẹ
nítorí pé ìwọ wí pé, ‘Èmi kò dẹ́ṣẹ̀.’
36 Èéṣe tí ìwọ fi ń lọ káàkiri
láti yí ọ̀nà rẹ padà?
Ejibiti yóò dójútì ọ́
gẹ́gẹ́ bí i ti Asiria
37 Ìwọ yóò sì fi ibẹ̀ sílẹ̀
pẹ̀lú kíkáwọ́ rẹ lé orí rẹ,
nítorí pé Olúwa ti kọ̀ àwọn
tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé sílẹ̀,
kì yóò sí ìrànlọ́wọ́ kankan
fún ọ láti ọ̀dọ̀ wọn.
7 Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn. 8 Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé.
9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbá yin kiri. Nítorí ó dára kí a mú yin lọ́kàn le nípa oore-ọ̀fẹ́, kì í ṣe nípa oúnjẹ nínú èyí tí àwọn tí ó ti rìn nínú wọn kò ní èrè. 10 Àwa ní pẹpẹ kan, níbi èyí tí àwọn ti ń sin àgọ́ kò ni agbára láti máa jẹ.
11 (A)Nítorí nígbà tí olórí àlùfáà bá mú ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹran wá si ibi mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀, òkú àwọn ẹran náà ni a o sun lẹ́yìn ibùdó. 12 Nítorí náà Jesu pẹ̀lú, kí ó lè fi ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀ sọ àwọn ènìyàn di mímọ́, ó jìyà lẹ́yìn ibodè. 13 Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a jáde tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí a máa ru ẹ̀gàn rẹ̀. 14 Nítorí pé àwa kò ní ìlú tí o wa títí níhìn-ín, ṣùgbọ́n àwa ń wá èyí tí ń bọ.
15 (B)Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.
17 Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríba fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìṣirò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.
18 Ẹ máa gbàdúrà fún wa: nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo. 19 Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà.
20 (C)Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùṣọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ayérayé, àní Olúwa wa Jesu. 21 Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ́ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jesu Kristi; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.