Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
40 Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀
ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,
àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú
wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
ó mú wọn rí àánú.
47 (A)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.
48 Olùbùkún ni Olúwa,
Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.
Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!
Ìparun tí n bọ̀ wá
17 Kó ẹrù rẹ kúrò láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀
ìwọ tí o ń gbé ní ìlú tí a dó tì.
18 Nítorí èyí ni Olúwa wí:
“Ní àkókò yìí,
èmi yóò gbọn àwọn tí ó ń gbé
ilẹ̀ náà jáde. Èmi yóò mú ìpọ́njú
bá wọn, kí wọn kí ó lè rí wọn mú.”
19 Ègbé ni fún mi nítorí ìpalára mi!
Ọgbẹ́ mi jẹ́ èyí tí kò lè sàn,
bẹ́ẹ̀ ni mọ sọ fún ara mi,
“Èyí ni àìsàn mi, mo sì gbọdọ̀ fi orí tì í.”
20 Àgọ́ mi bàjẹ́,
gbogbo okùn rẹ̀ sì já.
Àwọn ọmọ mi ti lọ lọ́dọ̀ mi, wọn kò sì sí mọ́
Kò sí ẹnìkankan tí yóò na àgọ́ mi ró mọ́,
tàbí yóò ṣe ibùgbé fún mi
21 Àwọn olùṣọ́-àgùntàn jẹ́ aṣiwèrè,
wọn kò sì wá Olúwa:
nítorí náà wọn kì yóò ṣe rere
àti pé gbogbo agbo wọn ni yóò túká.
22 Fetísílẹ̀! ariwo igbe ń bọ̀,
àti ìdàrúdàpọ̀ ńlá láti ilẹ̀ àríwá wá!
Yóò sì sọ ìlú Juda di ahoro,
àti ihò ọ̀wàwà.
Àdúrà Jeremiah
23 Èmi mọ̀ Olúwa wí pé ọ̀nà ènìyàn kì í ṣe ti ara rẹ̀,
kì í ṣe fún ènìyàn láti tọ́ ìgbésẹ̀ ara rẹ̀.
24 Tún mi ṣe Olúwa, pẹ̀lú ìdájọ́ nìkan
kí o má sì ṣe é nínú ìbínú rẹ,
kí ìwọ má ṣe sọ mí di òfo.
25 (A)Tú ìbínú rẹ jáde sórí àwọn orílẹ̀-èdè
tí kò mọ̀ ọ́n,
sórí àwọn ènìyàn tí wọn kò pe orúkọ rẹ.
Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,
wọ́n ti jẹ ẹ́ run pátápátá,
wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.
45 (A)Ó sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní etí gbogbo ènìyàn pé, 46 “Ẹ máa kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn akọ̀wé, tí wọ́n fẹ́ láti máa rìn nínú aṣọ gígùn, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu, àti ipò ọlá ní ibi àsè; 47 Àwọn tí ó jẹ ilé àwọn opó run, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn: àwọn wọ̀nyí náà ni yóò jẹ̀bi pọ̀jù.”
Oore opó
21 (B)Nígbà tí ó sì gbé ojú sókè, ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ ń fi ẹ̀bùn wọn sínú àpótí ìṣúra. 2 Ó sì rí tálákà opó kan pẹ̀lú, ó ń sọ owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì síbẹ̀. 3 Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, tálákà opó yìí fi sí i ju gbogbo wọn lọ: 4 Nítorí gbogbo àwọn wọ̀nyí fi sínú ẹ̀bùn Ọlọ́run láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìní wọn; ṣùgbọ́n òun nínú àìní rẹ̀ ó sọ gbogbo ohun ìní rẹ̀ tí ó ní sínú rẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.