Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 79:1-9

Saamu ti Asafu.

79 Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá ilẹ̀ ìní rẹ;
    wọ́n ti ba tẹmpili mímọ́ rẹ jẹ́,
    wọn di Jerusalẹmu kù sí òkìtì àlàpà.
Wọn ti fi ara òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ
    fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní oúnjẹ,
    ẹran-ara àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ fún ẹranko ilẹ̀.
Wọ́n tu ẹ̀jẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí omi
    yí Jerusalẹmu ká,
    kò sì ṣí àwọn tí yóò sìn wọ́n.
Àwa di ohun ẹ̀gàn sí àwọn tí ó yí wa ká,
    àbùkù àti ìfiṣe ẹlẹ́yà sí àwọn tí ó yí wa ká.

Nígbà wo, Olúwa? Ní ìwọ ó máa bínú títí láé?
    Yóò ti pẹ́ tó ti owú rẹ yóò ha jò bí iná?
Tú ìbínú rẹ jáde sí orílẹ̀-èdè
    tí kò ní ìmọ̀ rẹ,
lórí àwọn ìjọba
    tí kò pe orúkọ rẹ;
Nítorí wọ́n ti run Jakọbu
    wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ di ahoro.

Má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wa sí wa lọ́rùn
    jẹ́ kí àánú rẹ wá kánkán láti bá wa,
    nítorí tí a rẹ̀ wá sílẹ̀ gidigidi.
Ràn wá lọ́wọ́, Ọlọ́run Olùgbàlà wa,
    fún ògo orúkọ rẹ;
gbà wá kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì
    nítorí orúkọ rẹ.

Jeremiah 8:1-13

“ ‘Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, wọn yóò mú egungun àwọn ọba Juda àti egungun àwọn ìjòyè, egungun àwọn àlùfáà àti egungun àwọn wòlíì àti egungun àwọn olùgbé Jerusalẹmu kúrò nínú ibojì. A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀. Níbikíbi tí mo bá lé wọn lọ, gbogbo àwọn ìyókù wọn yóò fẹ́ ikú ju ìyè lọ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.’

Ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà

“Wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí:

“ ‘Bí ènìyàn bá ṣubú lulẹ̀
    wọn kì í padà dìde bí? Nígbà tí
ènìyàn bá yà kúrò ní ọ̀nà rẹ,
    kì í yí padà bí?
Èéṣe nígbà náà àwọn ènìyàn wọ̀nyí
    fi yà kúrò lọ́nà rẹ̀? Kí ló dé tí Jerusalẹmu
fi yà kúrò ní gbogbo ìgbà?
    Wọ́n rọ̀ mọ́ ẹ̀tàn, wọ́n kọ̀ láti yípadà.
Mo ti fetísílẹ̀ dáradára, wọn
    kò sọ ohun tí ó tọ́. Kò sí ẹnìkan tó
ronúpìwàdà nínú ìwà búburú rẹ̀,
    kí ó wí pé, “Kí ni mo ṣe?” Olúkúlùkù
    ń tọ ọ̀nà rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹṣin tó ń lọ sójú ogun.
Kódà, ẹyẹ àkọ̀ ojú ọ̀run mọ ìgbà
    tirẹ̀, àdàbà, alápáǹdẹ̀dẹ̀ àti lékèélékèé
mọ àkókò ìṣípò padà wọn. Ṣùgbọ́n àwọn
    ènìyàn mi kò mọ ohun tí Ọlọ́run wọn fẹ́.

“ ‘Báwo ni ẹ̀yin ṣe lè wí pé, “Àwa gbọ́n,
    nítorí a ní òfin Olúwa,” nígbà
tí ó jẹ́ pé kálámù èké àwọn
    akọ̀wé ti àwọn sọ ọ́ di ẹ̀tàn
Ojú yóò ti àwọn ọlọ́gbọ́n, a ó dà
    wọ́n láàmú, wọn yóò sì kó sí ìgbèkùn.
Nítorí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ Olúwa. Irú ọgbọ́n
    wo ló kù tí wọ́n ní?
10 Nítorí náà, èmi yóò fi ìyàwó wọn fún
    àwọn ọkùnrin mìíràn àti ilẹ̀ wọn
fún àwọn ẹlòmíràn láti èyí tó kéré
    jù dé èyí tó dàgbà jù, gbogbo wọn
ni èrè àjẹjù ń jẹ lógún; àwọn wòlíì
    àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ń hùwà ẹ̀tàn.
11 Wọ́n tọ́jú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́
    bí èyí tí kò jinlẹ̀.
“Àlàáfíà, àlàáfíà,” ni wọ́n ń wí,
    nígbà tí kò sí àlàáfíà.
12 Ǹjẹ́ wọ́n tijú fún ìṣe ìríra wọn? Bẹ́ẹ̀ kọ́,
    wọn kò ní ìtìjú rárá; wọn kò tilẹ̀ mọ
bí wọ́n ti ṣe ń tì jú. Nítorí náà
    wọn yóò ṣubú pẹ̀lú àwọn tó ti ṣubú,
a ó sì wó wọ́n lulẹ̀ nígbà tí a bá bẹ̀ wọ́n wò,
    ni Olúwa wí.

13 “ ‘Èmi yóò mú ìkórè wọn kúrò
    ni Olúwa wí.
Kì yóò sí èso lórí igi àjàrà,
    kì yóò sí ọ̀pọ̀tọ́ lórí igi, ewé wọn yóò sì rẹ̀ sílẹ̀.
    Ohun tí mo ti fi fún wọn ni à ó gbà kúrò.’ ”

Romu 8:31-39

Jíju aṣẹ́gun lọ

31 (A)Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32 (B)Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33 (C)Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. 34 (D)Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa? 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36 (E)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;
    À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”

37 (F)Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.