Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 94

94 Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san,
    Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.
Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé;
    san ẹ̀san fún agbéraga
    ohun tí ó yẹ wọ́n.
Báwo ní yóò ti pẹ́ tó,
    Olúwa
tí àwọn ẹni búburú
    yóò kọ orin ayọ̀?

Wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìgbéraga jáde;
    gbogbo àwọn olùṣe búburú
kún fún ìṣògo.
Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa:
    wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.
Wọ́n pa àwọn opó àti àlejò,
    wọ́n sì pa àwọn ọmọ aláìní baba,
Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i;
    Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”

Kíyèsi i, ẹ̀yin aláìlóye nínú àwọn ènìyàn
    ẹ̀yin aṣiwèrè, nígbà wo ni ẹ̀yin yóò lóye?
Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí?
    Ẹni tí ó dá ojú?
Ó ha lè ṣe aláìríran bí?
10 Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí?
    Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?
11 (A)Olúwa mọ èrò inú ènìyàn;
    ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

12 Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí
    ìwọ bá wí, Olúwa,
ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ;
13 Ìwọ gbà á kúrò nínú ọjọ́ ibi,
    títí a ó fi wa ihò sílẹ̀ fún ẹni búburú.
14 Nítorí Olúwa kò ní kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ sílẹ̀;
Òun kò sì ní kọ ilẹ̀ ìní rẹ̀ sílẹ̀.
15 Ìdájọ́ yóò padà sí òdodo,
    àti gbogbo àwọn ọlọ́kàn
    dídúró ṣinṣin yóò tẹ̀lé e lẹ́yìn.

16 Ta ni yóò dìde fún mi
    sí àwọn olùṣe búburú?
    Tàbí ta ni yóò dìde sí àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún mi?
17 Bí kò ṣe pé Olúwa fún mi ní ìrànlọ́wọ́,
    èmi fẹ́rẹ̀ máa gbé ní ilẹ̀ tí ó dákẹ́
18 Nígbà tí mo sọ pé “Ẹsẹ̀ mi ń yọ̀”,
    Olúwa, ìfẹ́ rẹ̀ ni ó tì mí lẹ́yìn.
19 Nígbà tí àníyàn ńlá wà nínú mi,
    ìtùnú rẹ̀ mú ayọ̀ sí ọkàn mi.

20 Ìjọba ìbàjẹ́ ha lè kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú rẹ
    ẹni tí ń fi òfin dì mọ́ ìwà ìkà?
21 Wọ́n kó ara wọn jọ sí olódodo
    wọ́n sì ń dá àwọn aláìṣẹ̀ lẹ́bi sí ikú.
22 Ṣùgbọ́n, Olúwa ti di odi alágbára mi,
    àti Ọlọ́run mi ni àpáta nínú ẹni
    tí mo ti ń gba ààbò.
23 Òun yóò san ẹ̀san ibi wọn fún wọn
    yóò sì pa wọ́n run nítorí búburú wọn
    Olúwa Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n run.

Jeremiah 14:1-10

Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà

14 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

“Juda káàánú,
    àwọn ìlú rẹ̀ kérora
wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,
    igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,
    wọ́n lọ sí ìdí àmù
ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.
    Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;
ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,
    wọ́n sì bo orí wọn.
Ilẹ̀ náà sán
    nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
    wọ́n sì bo orí wọn.
Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá
    fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
    torí pé kò sí koríko.
Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo
    wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò
ojú wọn kò ríran
    nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,
    wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.
Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,
    a ti ṣẹ̀ sí ọ.
Ìrètí Israẹli;
    ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,
èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà
    bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?
Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,
    bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?
Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,
    orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;
    má ṣe fi wá sílẹ̀.

10 Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:

“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;
    wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.
Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;
    yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,
    yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

Jeremiah 14:17-22

17 “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:

“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé
    ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;
nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,
    ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá
    pẹ̀lú lílù bolẹ̀.
18 Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,
    Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.
Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,
    èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.
Wòlíì àti Àlùfáà
    ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19 Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?
    Ṣé o ti ṣá Sioni tì?
Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú
    tí a kò fi le wò wá sàn?
A ń retí àlàáfíà
    ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,
ní àsìkò ìwòsàn
    ìpayà là ń rí.
20 Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa
    àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;
    lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.
21 Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;
    má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.
Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá
    kí o má ṣe dà á.
22 Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?
    Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnrarẹ̀ rọ òjò bí?
Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.
    Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,
nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

Luku 22:31-33

31 (A)Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: 32 (B)Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

33 (C)Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”

Luku 22:54-62

Peteru sẹ́ Jesu

54 (A)Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. 55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. 56 (B)Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”

58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”

Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”

59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”

60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! 61 (C)Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” 62 Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.