Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
14 Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,
gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,
nítorí ìwọ ni ìyìn mi.
15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:
“Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?
Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”
Ni Olúwa wí.
16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,
ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.
17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,
ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,
ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,
jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.
Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,
fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.
Pípa ọjọ́ ìsinmi mọ́
19 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ dúró ní ẹnu-ọ̀nà àwọn ènìyàn níbi tí àwọn ọba Juda ń gbà wọlé tí wọ́n ń gbà jáde àti ní gbogbo ẹnu-bodè Jerusalẹmu. 20 Sọ fún wọ́n pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba Juda àti gbogbo ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ẹ̀yin tí ń gbé ní Jerusalẹmu tí ń wọlé láti ẹnu ibodè yìí. 21 Báyìí ni Olúwa wí: Ẹ kíyèsi láti máa ru ẹrù lọ́jọ́ ìsinmi tàbí kí ẹ gbé wọlé láti ẹnu ibodè Jerusalẹmu. 22 Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín. 23 Síbẹ̀ wọn kò gbọ́ tàbí tẹ́tí sílẹ̀, wọ́n jẹ́ ọlọ́rùn líle; wọn kì í fẹ́ gbọ́ tàbí gba ìbáwí. 24 Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá kíyèsi láti gbọ́ tèmi ní Olúwa wí, tí ẹ kò sì gbe ẹrù gba ẹnu-bodè ìlú ní ọjọ́ ìsinmi, ṣùgbọ́n tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi, sí mímọ́, nípa pé ẹ kò ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ ní ọjọ́ náà. 25 Nígbà náà ni ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi yóò gba ẹnu ibodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹṣin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé. 26 Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Juda àti ní agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Benjamini, láti pẹ̀tẹ́lẹ̀, àti láti òkè, àti láti gúúsù wá, wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun, àti ọrẹ ẹran, àti tùràrí, àti àwọn tó mú ìyìn wá sí ilé Olúwa. 27 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá pa òfin mi mọ́ láti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, kí ẹ má sì ṣe ru ẹrùkẹ́rù bí ẹ̀yin yóò ṣe máa gba ẹnu ibodè Jerusalẹmu wọlé ní ọjọ́ ìsinmi, nígbà náà ni èmi yóò da iná tí kò ní ṣe é parun ní ẹnu-bodè Jerusalẹmu tí yóò sì jó odi agbára rẹ̀.’ ”
34 (A)“Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà. 35 Nítorí èmi wá láti ya
“ ‘ọmọkùnrin ní ipa sí baba rẹ̀,
ọmọbìnrin ní ipa sí ìyá rẹ̀,
àti aya ọmọ sí ìyakọ rẹ̀…
36 Ará ilé ènìyàn ni yóò sì máa ṣe ọ̀tá rẹ̀.’
37 (B)“Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi; 38 Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi. 39 Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.
40 (C)“Ẹni tí ó bá gbà yín, ó gbà mí, ẹni tí ó bá sì gbà mí gba ẹni tí ó rán mi. 41 Ẹni tí ó ba gba wòlíì, nítorí pé ó jẹ́ wòlíì yóò jẹ èrè wòlíì, ẹni tí ó bá sì gba olódodo nítorí ti ó jẹ́ ènìyàn olódodo, yóò jẹ èrè olódodo. 42 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ago omi tútù fún ọ̀kan nínú àwọn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí mu nítorí tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, kò ní pàdánù èrè rẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.