Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 2

(A)Èéṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń dìtẹ̀,
    àti tí àwọn ènìyàn ń ṣe rìkíṣí asán?
Àwọn ọba ayé péjọpọ̀
    àti àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀
    Olúwa àti sí Ẹni ààmì òróró rẹ̀.
Wọ́n sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí a fa ẹ̀wọ̀n wọn já,
    kí a sì ju ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wọn nù.”

Ẹni tí ó gúnwà lórí ìtẹ́ lọ́run rẹ́rìn-ín;
    Olúwa fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.
Nígbà náà ni yóò bá wọn wí ní ìbínú rẹ̀
    yóò sì dẹ́rùbà wọ́n ní ìrunú rẹ̀, ó wí pé,
“Èmi ti fi ọba mi sí ipò
    lórí Sioni, òkè mímọ́ mi.”

(B)Èmi yóò sì kéde ìpinnu Olúwa:

Ó sọ fún mi pé, “Ìwọ ni ọmọ mi;
    lónìí, èmi ti di baba rẹ.
(C)Béèrè lọ́wọ́ mi,
    Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè di ìní rẹ,
    òpin ilé ayé yóò sì jẹ́ ogún rẹ.
Ìwọ yóò fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn
    ìwọ yóò sì rún wọn wómúwómú bí ìkòkò amọ̀.”

10 Nítorí náà, ẹ̀yin ọba, ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n;
    ẹ gbọ́ ìkìlọ̀ ẹ̀yin alákòóso ayé.
11 Ẹ sin Olúwa pẹ̀lú ìbẹ̀rù
    ẹ sì máa yọ̀ pẹ̀lú ìwárìrì.
12 Fi ẹnu ko ọmọ náà ní ẹnu, kí ó má ba à bínú,
    kí ó má ba à pa yín run ní ọ̀nà yín,
nítorí ìbínú rẹ̀ lè ru sókè ní ẹ̀ẹ̀kan.
    Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó fi í ṣe ibi ìsádi wọn.

Jeremiah 18:12-23

12 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Kò ṣe nǹkan kan, àwa yóò tẹ̀síwájú nínú èrò wa, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, yóò hùwà agídí ọkàn búburú rẹ̀.’ ”

13 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:

“Ẹ béèrè nínú orílẹ̀-èdè,
    ẹni tí ó bá ti gbọ́ irú nǹkan wọ̀nyí ri?
    Ohun tí ó burú gidi ni wúńdíá Israẹli ti ṣe.
14 Ǹjẹ́ omi ojo dídì Lebanoni
    yóò ha dá láti máa sàn láti ibi àpáta?
Tàbí odò tí ó jìnnà, tí ó tútù,
    tí ó ń sàn, yóò ha gbẹ bí?
15 Nítorí àwọn ènìyàn mi gbàgbé mi,
    wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà asán,
tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn,
    àti ọ̀nà wọn àtijọ́.
    Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́,
    àti ní ojú ọ̀nà ti a kò ṣe
16 Ilẹ̀ wọn yóò wà lásán yóò sì di
    nǹkan ẹ̀gàn títí láé;
Gbogbo àwọn tí ó ń kọjá yóò bẹ̀rù,
    wọn yóò sì mi orí wọn.
17 Gẹ́gẹ́ bí afẹ́fẹ́ láti ìlà-oòrùn,
    Èmi yóò tú wọn ká lójú àwọn ọ̀tá wọn.
Èmi yóò sì kọ ẹ̀yìn sí wọn, n kì yóò kọjú sí wọn
    ní ọjọ́ àjálù wọn.”

18 Wọ́n sọ wí pé, “Wá, jẹ́ kí a lọ ṣọ̀tẹ̀ sí Jeremiah, nítorí òfin ìkọ́ni láti ẹnu àwọn àlùfáà kì yóò jásí asán, tàbí ìmọ̀ràn fún àwọn ọlọ́gbọ́n tàbí ọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì. Nítorí náà wá, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú pẹ̀lú ahọ́n wa, kí a má sì ṣe tẹ́tí sí ohunkóhun tí ó bá sọ.”

19 Dẹtí sí ọ̀rọ̀ mi Olúwa, gbọ́ ohun

    tí àwọn tí ó fi mí sùn ń sọ.
20 Ṣe kí a fi rere san búburú?
    Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi,
rántí pé mo dúró níwájú rẹ,
    mo sì sọ̀rọ̀ nítorí wọn, láti
    yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
21 Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn
    jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà
jẹ́ kí ìyàwó wọn kí ó di aláìlọ́mọ àti opó
    jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn
kí a sì fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
    wọn lójú ogun.
22 Jẹ́ kí a gbọ́ ohùn ẹkún láti ilé wọn
    nígbà tí ó bá mu àwọn jagunjagun
kọlù wọ́n lójijì nítorí wọ́n ti gbẹ́
    kòtò láti mú mi. Wọ́n ti dẹ okùn fún ẹsẹ̀ mi
23 Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa mọ
    gbogbo ète wọn láti pa mí,
má ṣe dárí ẹ̀bi wọn jì wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni má ṣe pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ.
    Jẹ́ kí wọn kí ó ṣubú níwájú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó sì ṣe sí wọn nígbà ìbínú rẹ.

1 Timotiu 3:14-4:5

14 Ìwé nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ sí ọ, mo sì ń retí àti tọ̀ ọ́ wá ní lọ́ọ́lọ́ọ́. 15 Ṣùgbọ́n bí mo bá pẹ́, kí ìwọ lè mọ̀ bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn láti máa hùwà nínú ilé Ọlọ́run, tì í ṣe ìjọ Ọlọ́run alààyè, ọ̀wọ́n àti ìpìlẹ̀ òtítọ́. 16 Láìṣiyèméjì, títóbi ní ohun ìjìnlẹ̀ ìwà-bí-Ọlọ́run:

ẹni tí a fihàn nínú ara,
    tí a dá láre nínú Ẹ̀mí,
ti àwọn angẹli rí,
    tí a wàásù rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
tí a gbàgbọ́ nínú ayé,
    tí a sì gbà sókè sínú ògo.

Àwọn ẹ̀kọ́ fun Timotiu

Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.