Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Ní ilé amọ̀kòkò
18 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá wí pe: 2 “Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.” 3 Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́. 4 Ṣùgbọ́n ìkòkò tí ó ń mọ láti ara amọ̀ bàjẹ́ ní ọwọ́ rẹ̀, nítorí náà ni amọ̀kòkò fi ṣe ìkòkò mìíràn, ó mọ ọ́n bí èyí tí ó dára jù ní ojú rẹ̀.
5 Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 6 (A)“Ẹyin ilé Israẹli, èmi kò ha lè ṣe fún un yín gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò yìí ti ṣe?” ni Olúwa wí. “Gẹ́gẹ́ bí amọ̀ ní ọwọ́ amọ̀kòkò bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin rí ní ọwọ́ mi, ẹ̀yin ilé Israẹli. 7 Bí ó bá jẹ́ ìgbà kan, tí èmi kéde kí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan di fífà tu láti dojúdé àti láti parun. 8 Tí orílẹ̀-èdè ti mo kìlọ̀ fún bá yípadà kúrò nínú ìwà búburú wọn, nígbà náà ni Èmi yóò yí ọkàn mi padà nínú àjálù tí mo ti rò láti ṣe sí wọn. 9 Ní ìgbà mìíràn tí èmi bá tún kéde láti tẹ̀dó tàbí gbin orílẹ̀-èdè kan tàbí ìjọba kan. 10 Bí ó bá sì ṣe búburú níwájú mi, tí kò sì gba ohùn mi gbọ́, nígbà náà ni èmi yóò yí ọkàn mi padà ní ti rere, èyí tí mo wí pé, èmi ó ṣe fún wọn.
11 “Ǹjẹ́ nísinsin yìí, sọ fún àwọn ènìyàn Juda àti àwọn olùgbé Jerusalẹmu wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa wí: Wò ó! Èmi ń gbèrò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlùkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rẹ̀ ṣe.’
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
Ìkíni
1 Èmi Paulu, ẹni tí a fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ó ń wàásù ìhìnrere Jesu Kristi àti Timotiu arákùnrin wa.
Sí Filemoni ọ̀rẹ́ wa ọ̀wọ́n àti alábáṣiṣẹ́ wa, 2 sí Affia arábìnrin wa, sí Arkippu ẹni tó jẹ́ jagunjagun fún àgbélébùú náà àti sí ìjọ àwọn Kristiani tí ó ń pàdé nínú ilé rẹ:
3 (A)Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi.
Ọpẹ́ àti Àdúrà
4 (B)Èmi máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tí mo bá rántí rẹ nínú àdúrà mi, 5 nítorí mo ń gbọ́ nípa ìgbàgbọ́ rẹ nínú Jesu Olúwa àti nípa ìfẹ́ rẹ sí àwọn ènìyàn mímọ́. 6 Èmi ń gbàdúrà pé, bí ìwọ ti ń ṣe alábápín nínú ìgbàgbọ́ rẹ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, pé kí ìgbàgbọ́ náà lè mú ọkàn wọn dúró gbọingbọin, gẹ́gẹ́ bí wọn ti rí àwọn ọ̀rọ̀ ohun rere tí ó ń bẹ nínú ayé rẹ, èyí tí ó ti ọ̀dọ̀ Kristi wá. 7 Ìfẹ́ rẹ ti fún mi ní ayọ̀ púpọ̀ àti ìgboyà, nítorí ìwọ, arákùnrin ti tu ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ lára.
Paulu bẹ̀bẹ̀ fún Onesimu
8 Nítorí náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nínú Kristi mo ní ìgboyà púpọ̀ láti pàṣẹ ohun ti ó yẹ kí ó ṣe fún ọ, 9 Síbẹ̀ nítorí ìfẹ́ èmí kúkú bẹ̀ ọ́. Èmi gẹ́gẹ́ bí Paulu, arúgbó, àti nísinsin yìí òǹdè Jesu Kristi. 10 (C)Èmí bẹ̀ ọ́ nítorí ọmọ mi Onesimu, ẹni tí ó di ọmọ nígbà tí mo wà nínú ìdè. 11 Nígbà kan rí, kò wúlò fún ọ, ṣùgbọ́n ní báyìí, ó ti wúlò fún ọ àti fún èmi pàápàá.
12 Èmi rán an nísinsin yìí, àní ẹni ọkàn mi padà sí ọ̀dọ̀ rẹ. 13 Èmi ìbá fẹ́ láti dá a dúró sọ́dọ̀ mi níhìn-ín, kí ó ba à dípò rẹ láti máa ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo wà nínú ìdè nítorí ìhìnrere 14 ṣùgbọ́n èmi kò fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá láìgba ìyọ̀ǹda ní ọwọ́ rẹ, kí oore tí ìwọ bá ṣe má ba à jẹ́ ìfipámúniṣe bí kò ṣe ìfìfẹ́ṣe. 15 Bóyá ìdí rẹ̀ tí òun fi yẹra kúrò lọ́dọ̀ rẹ fún ìgbà díẹ̀ ni pé kí ìwọ kí ó lè gbà á padà sọ́dọ̀ títí láé; 16 Kì í wá ṣe bí ẹrú mọ́, ṣùgbọ́n bí ẹni ti ó sàn ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Ó ṣọ̀wọ́n fún mi jọjọ, ṣùgbọ́n ó ṣọ̀wọ́n fún ọ jù nípa ti ara àti gẹ́gẹ́ bí arákùnrin nínú Olúwa.
17 Nítorí náà bí ìwọ bá kà mí sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tẹ́wọ́ gbà á bí ìwọ yóò ti tẹ́wọ́ gbà mí. 18 Bí ó bá ti ṣe ọ́ ní ibi kan tàbí jẹ ọ́ ní gbèsè ohun kan, kà á sí mi lọ́rùn. 19 Èmi Paulu, ni mo fi ọwọ́ ara mi kọ ìwé yìí; èmi yóò san án padà láì tilẹ̀ ní í sọ nípa pé ìwọ pàápàá jẹ mi ní gbèsè ara rẹ. 20 Èmi ń fẹ́, arákùnrin, pé kí èmi kí ó lè ni àǹfààní kan láti ọ̀dọ̀ rẹ nínú Olúwa; fi ayọ̀ rẹ kún ọkàn mi nínú Kristi. 21 Ìgbẹ́kẹ̀lé ti mo ní pé ìwọ yóò gbọ́rọ̀, ni mo fi kọ ìwé yìí ránṣẹ́ sí ọ. Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò ṣe ju bí mo ti béèrè lọ.
Àmúyẹ láti jẹ ọmọ-ẹ̀yìn
25 Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé, 26 (A)“Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kórìíra baba àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi. 27 (B)Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
28 “Nítorí ta ni nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀. 29 Kí ó má ba à jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà. 30 Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’
31 “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàárùn-ún pàdé ẹni tí ń mú ẹgbàáwàá bọ̀ wá ko òun lójú? 32 Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlàáfíà. 33 (C)Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.