Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu.
139 Olúwa, ìwọ tí wádìí mi,
ìwọ sì ti mọ̀ mí.
2 Ìwọ mọ̀ ìjókòó mi àti ìdìde mi,
ìwọ mọ̀ èrò mi ní ọ̀nà jíjìn réré.
3 Ìwọ yí ipa ọ̀nà mi ká àti ìdùbúlẹ̀ mi,
gbogbo ọ̀nà mi sì di mí mọ̀ fún ọ.
4 Nítorí tí kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ahọ́n mi,
kíyèsi i, Olúwa, ìwọ mọ̀ ọ́n pátápátá.
5 Ìwọ sé mi mọ́ lẹ́yìn àti níwájú,
ìwọ sì fi ọwọ́ rẹ lé mi.
6 Irú ìmọ̀ yìí jẹ ohun ìyanu fún mi jù;
ó ga, èmi kò le mọ̀ ọ́n.
13 Nítorí ìwọ ni ó dá ọkàn mi;
ìwọ ni ó bò mí mọ́lẹ̀ nínú ìyá mi.
14 Èmi yóò yìn ọ, nítorí tẹ̀rù tẹ̀rù àti tìyanu tìyanu ní a dá mi;
ìyanu ní iṣẹ́ rẹ;
èyí nì ni ọkàn mi sì mọ̀ dájúdájú
15 Ẹ̀dá ara mi kò pamọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ,
nígbà tí a dá mi ní ìkọ̀kọ̀.
Tí a sì ń ṣiṣẹ́ ní àràbarà ní ìhà ìsàlẹ̀ ilẹ̀ ayé,
16 ojú rẹ ti rí ohun ara mi
nígbà tí a kò tí ì ṣe mí pé:
àti nínú ìwé rẹ ni a ti kọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sí,
ní ọjọ́ tí a dá wọn,
nígbà tí wọn kò tilẹ̀ tí ì sí.
17 Ọlọ́run, èrò inú rẹ tí ṣe iyebíye tó fún mi,
iye wọn ti pọ̀ tó!
18 Èmi ìbá kà wọ́n,
wọ́n ju iyanrìn lọ ní iye:
nígbà tí mo bá jí,
èmi yóò wà lọ́dọ̀ rẹ síbẹ̀.
10 Háà! Ó ṣe tí ìyá mi bí mi:
ọkùnrin tí gbogbo ilẹ̀ dojúkọ tí wọ́n sì bá jà,
èmi kò wínni, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò yá lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni
síbẹ̀, gbogbo ènìyàn ló ń fi mí ré.
11 Olúwa sọ pé,
“Dájúdájú èmi ò dá ọ sí fún ìdí kan pàtó.
Dájúdájú mo mú kí àwọn ọ̀tá rẹ
tẹríba níwájú rẹ nígbà ibi àti ìpọ́njú.
12 “Ǹjẹ́ ẹnìkan lè fi ọwọ́ ṣẹ́ irin
irin láti àríwá tàbí idẹ?
13 “Gbogbo ọlá àti ìṣúra rẹ
ni èmi ó fi sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkógun láìgba
nǹkan kan nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ
jákèjádò orílẹ̀-èdè rẹ.
14 Èmi yóò fi ọ́ ṣẹrú fún àwọn ọ̀tá rẹ
ní ìlú tí ìwọ kò mọ̀ nítorí ìbínú
mi yóò rán iná tí yóò jó ọ.”
15 Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí o
sì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi lára
àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún
ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bí
mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n
Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi
Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí
Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn.
N ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;
mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà
lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18 Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,
tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?
Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,
gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?
19 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:
“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà
wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá
sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di agbẹnusọ
mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;
ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn
20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára
sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà
ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ
nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,
kí n sì dáàbò bò ọ́,”
ni Olúwa wí.
21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn
ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́
padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”
25 Mo kà á sí pé n kò lè ṣàìrán Epafiroditu arákùnrin mi sí yín, àti olùbáṣiṣẹ́ pọ̀ mi, àti ọmọ-ogun ẹlẹgbẹ́ mi, ìránṣẹ́ yín pẹ̀lú, tí ẹ rán láti ṣè ránṣẹ́ fún mi nínú àìní mi. 26 Nítorí tí ọkàn rẹ̀ fà sí gbogbo yín, ó sì kún fún ìbànújẹ́, nítorí tí ẹ̀yin gbọ́ pé ó ṣe àìsàn. 27 Nítòótọ́ ni ó ti ṣe àìsàn títí dé ojú ikú, ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti ṣàánú fún un; kì í sì í ṣe fún òun nìkan, ṣùgbọ́n fún èmi pẹ̀lú kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lórí ìbànújẹ́. 28 Nítorí náà ni mo ṣe ní ìtara láti rán an, pé nígbà tí ẹ̀yin bá sì tún rí i, kí ẹ̀yin lè yọ̀ àti kí ìkáyà sókè mi lè dínkù. 29 Nítorí náà, ẹ fi ayọ̀ púpọ̀ gbà á nínú Olúwa; kí ẹ sì máa bu ọlá fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. 30 Nítorí iṣẹ́ Kristi ni ó ṣe súnmọ́ ẹnu-ọ̀nà ikú, tí ó sì fi ẹ̀mí ara rẹ̀ wéwu, láti mu àìtó iṣẹ́ ìsìn yín sí mi kún.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.