Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 14

Fún adarí orin. Ti Dafidi.

14 (A)(B) Aṣiwèrè wí nínú ọkàn rẹ̀ pé,
    “Ko sí Ọlọ́run.”
Wọ́n díbàjẹ́, iṣẹ́ wọn sì burú;
    kò sí ẹnìkan tí yóò ṣe rere.

Olúwa sì bojú wolẹ̀ láti ọ̀run wá
    lórí àwọn ọmọ ènìyàn
bóyá ó le rí ẹni tí òye yé,
    ẹnikẹ́ni tó ń wá Ọlọ́run.
Gbogbo wọn sì ti yípadà, gbogbo wọn sì ti díbàjẹ́;
    kò sì ṣí ẹni tí ó ń ṣe rere,
    kò sí ẹnìkan.

Ǹjẹ́ olùṣe búburú kò ha ní ìmọ̀?

Àwọn tí ó ń pa ènìyàn mi jẹ bí ẹní jẹun;
    wọn kò sì ké pe Olúwa?
Wọ́n wà níbẹ̀, tí a bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rù,
    nítorí Ọlọ́run wà ní àwùjọ àwọn olódodo.
Ẹ̀yin olùṣe búburú da èrò àwọn tálákà rú,
    ṣùgbọ́n Olúwa ni ààbò wọn.

Ìgbàlà àwọn Israẹli yóò ti Sioni wá!
    Nígbà tí Olúwa bá mú ìkólọ àwọn ènìyàn rẹ̀ padà,
    jẹ́ kí Jakọbu kí ó yọ̀, kí inú Israẹli kí ó dùn!

Jeremiah 4:13-21

13 Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu
    kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle
ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ
    Ègbé ni fún wa àwa parun.
14 Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè
    Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?
15 Ohùn kan sì ń kéde ní Dani
    o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá.
16 “Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè,
    kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé:
‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá
    wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda.
17 Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,
    nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”
    ni Olúwa wí.
18 “Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ
    ló fa èyí bá ọ
ìjìyà rẹ sì nìyìí,
    Báwo ló ti ṣe korò tó!
    Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”

19 Háà! Ìrora mi, ìrora mi!
    Mo yí nínú ìrora.
Háà, ìrora ọkàn mi!
    Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,
n kò le è dákẹ́.
    Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,
    mo sì ti gbọ́ igbe ogun.
20 Ìparun ń gorí ìparun;
    gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun
lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi,
    tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.
21 Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun
    tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

Jeremiah 4:29-31

29 Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà
    gbogbo ìlú yóò sálọ.
Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó;
    ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ.
Gbogbo ìlú náà sì di ahoro;
    kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀.

30 Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán?
    Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo
kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.
    Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ
wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.

31 Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí,
    tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ
ọmọbìnrin Sioni tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀.
    Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé,
“Kíyèsi i mo gbé,
    Nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”

Johanu 10:11-21

11 (A)“Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere: olùṣọ́-àgùntàn rere fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 12 Ṣùgbọ́n alágbàṣe, tí kì í ṣe olùṣọ́-àgùntàn, ẹni tí àwọn àgùntàn kì í ṣe tirẹ̀, ó rí ìkookò ń bọ̀, ó sì fi àgùntàn sílẹ̀, ó sì fọ́n wọn ká kiri. 13 Òun sálọ nítorí tí ó jẹ́ alágbàṣe, kò sì náání àwọn àgùntàn.

14 “Èmi ni olùṣọ́-àgùntàn rere, mo sì mọ àwọn tèmi, àwọn tèmi sì mọ̀ mí. 15 (B)Gẹ́gẹ́ bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ọkàn mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn. 16 (C)Èmi sì ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kì í ṣe agbo yìí: àwọn ni èmi yóò mú wá pẹ̀lú, wọn yóò sì gbọ́ ohùn mi; wọn ó sì jẹ́ agbo kan, olùṣọ́-àgùntàn kan. 17 Nítorí náà ni Baba mi ṣe fẹ́ràn mi, nítorí tí mo fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, kí èmi lè tún gbà á. 18 (D)Ẹnìkan kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣùgbọ́n mo fi í lélẹ̀, mo sì lágbára láti tún gbà á. Àṣẹ yìí ni mo ti gbà wá láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”

19 (E)Nítorí náà ìyapa tún wà láàrín àwọn Júù nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí. 20 (F)Ọ̀pọ̀ nínú wọn sì wí pé, “Ó ní ẹ̀mí èṣù, orí rẹ̀ sì dàrú; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń gbọ́rọ̀ rẹ̀?”

21 (G)Àwọn mìíràn wí pé, “Ìwọ̀nyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù. Ẹ̀mí èṣù lè la ojú àwọn afọ́jú bí?”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.