Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 106:40-48

40 Nígbà náà ni Olúwa bínú sí àwọn ènìyàn rẹ̀
    ó sì kórìíra àwọn ènìyàn ìní rẹ̀
41 Ó sì fà wọ́n lé àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,
    àwọn ọ̀tá wọn sì jẹ ọba lórí wọn.
42 Àwọn ọ̀tá wọn sì ń pọ́n wọn lójú
    wọn sì mú wọn sìn lábẹ́ àṣẹ wọn.
43 Ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun gbà wọ́n,
    Síbẹ̀ wọ́n sì ń ṣọ̀tẹ̀ sí i
    wọ́n sì ṣòfò dànù nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
44 Ṣùgbọ́n ó kíyèsi wọn nítorí ìṣòro
    nígbà tí ó gbọ́ ẹkún wọn;
45 Ó rántí májẹ̀mú rẹ̀ nítorí wọn
    Nítorí agbára ìfẹ́ rẹ̀, ó ṣàánú wọn.
46 Lójú gbogbo àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn
    ó mú wọn rí àánú.

47 (A)Gbà wá, Olúwa Ọlọ́run wa,
    kí o sì ṣà wá jọ kúrò láàrín àwọn kèfèrí,
láti máa fi ọpẹ́ fún orúkọ mímọ́ rẹ
    láti máa ṣògo nínú ìyìn rẹ.

48 Olùbùkún ni Olúwa,
    Ọlọ́run Israẹli, láti ìrandíran.

Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kí ó wí pé, “Àmín!”

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa!

Jeremiah 10:1-16

Ọlọ́run àti àwọn òrìṣà

10 Gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ fún yín ẹ̀yin ilé Israẹli. Báyìí ni Olúwa wí:

“Má ṣe kọ́ ìwà àwọn kèfèrí,
    kí ààmì ọ̀run kí ó má sì dààmú yín,
    nítorí pé wọ́n ń dààmú orílẹ̀-èdè.
Nítorí pé asán ni àṣà àwọn ènìyàn,
    wọ́n gé igi láti inú igbó, oníṣọ̀nà
    sì gbẹ́ ẹ pẹ̀lú àáké rẹ̀.
Wọ́n fi fàdákà àti wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́.
    Wọ́n fi òòlù kàn án àti ìṣó
    kí ó má ba à ṣubú.
Wọ́n wé mọ́ igi bí ẹ̀gúnsí inú oko,
    òrìṣà wọn kò le è fọhùn.
Wọ́n gbọdọ̀ máa gbé
    wọn nítorí pé wọn kò lè rìn.
Má ṣe bẹ̀rù wọn;
    wọn kò le è ṣe ibi kankan
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò si lè ṣe rere kan.”

Kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ Olúwa;
    o tóbi orúkọ rẹ sì tóbi lágbára.
Ta ni kò yẹ kí ó bẹ̀rù rẹ ọba àwọn
    orílẹ̀-èdè? Nítorí tìrẹ ni, láàrín àwọn
ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní orílẹ̀-èdè àti
    gbogbo ìjọba wọn, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ.

Gbogbo wọn jẹ́ aláìlóye àti aṣiwèrè,
    wọ́n ń kọ́ ẹ̀kọ́ àwọn ère igi tí kò níláárí
Fàdákà tí a ti kàn ni a mú wá láti
    Tarṣiṣi, àti wúrà láti Upasi; èyí tí
àwọn oníṣọ́nà àti alágbẹ̀dẹ ṣe tí wọ́n
    kùn ní àwọ̀ aró àti elése àlùkò,
    èyí jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọlọ́gbọ́n oníṣọ̀nà.
10 Ṣùgbọ́n Olúwa ni Ọlọ́run tòótọ́,
    òun ni Ọlọ́run alààyè, ọba ayérayé.
Nígbà tí ó bá bínú, ayé yóò wárìrì;
    orílẹ̀-èdè kò lè fi ara da ìbínú rẹ̀.

11 “Sọ èyí fún wọn: ‘Àwọn ọlọ́run kéékèèkéé tí kò dá ọ̀run àti ayé ni yóò ṣègbé láti ayé àti ní abẹ́ ọ̀run.’ ”

12 Ọlọ́run dá ayé pẹ̀lú agbára rẹ̀,
    ó dá àgbáyé pẹ̀lú ọgbọ́n rẹ̀,
    ó mú kí ọ̀run kí ó fẹ̀ síta nípa òye rẹ̀.
13 Nígbà tí ó bá sán àrá, àwọn omi
    lọ́run a sì pariwo, ó mú kí ìkùùkuu ru
sókè láti òpin ayé: ó rán mọ̀nàmọ́ná pẹ̀lú òjò,
    ó sì ń mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.

14 Gbogbo ènìyàn jẹ́ aṣiwèrè àti aláìnímọ̀,
    ojú ti gbogbo alágbẹ̀dẹ níwájú ère rẹ̀,
nítorí ère dídá rẹ̀ èké ni,
    kò sì ṣí ẹ̀mí nínú rẹ̀.
15 Asán ni wọ́n, iṣẹ́ ìṣìnà;
    nígbà ìbẹ̀wò wọn, wọn yóò ṣègbé.
16 Ẹni tí ó bá jẹ́ ìpín Jakọbu kò sì dàbí èyí,
    nítorí òun ni ó ṣẹ̀dá ohun gbogbo
àti Israẹli tí ó jẹ́ ẹ̀yà ìjogún rẹ̀.
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.

1 Kọrinti 9:19-23

19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20 (A)Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21 (B)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 22 (C)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23 Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.