Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:49-56

Òfin Ọlọ́run ní ìrètí

49 Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
    nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.
50 Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí:
    ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.
51 Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró,
    ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.
52 Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa,
    èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.
53 Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú,
    tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.
54 Òfin rẹ ni ọ̀rọ̀ ìpìlẹ̀ orin mi
    níbikíbi tí èmi ń gbé.
55 Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa,
    èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
56 nítorí tí mo
    gba ẹ̀kọ́ rẹ gbọ́.

Jeremiah 32:36-44

36 “Ìwọ ń sọ̀rọ̀ nípa ti ìlú yìí pé, ‘Pẹ̀lú idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn ni à ó fi wọ́n fún ọba Babeli,’ ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ nìyìí: 37 Èmi ó kó wọn jọ láti gbogbo ilẹ̀ tí mo ti lé wọn kúrò ní ìgbà ìbínú àti ìkáàánú ńlá mi. Èmi yóò mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí; èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó máa gbé láìléwu. 38 (A)Wọn yóò jẹ́ ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn. 39 Èmi ó fún wọn ní ọkàn kan àti ìṣe kí wọn kí ó lè máa bẹ̀rù mi fún rere wọn àti fún rere àwọn ọmọ wọn tí ó tẹ̀lé wọn. 40 Èmi ò bá wọn dá májẹ̀mú ayérayé, èmi kò ní dúró láti ṣe rere fún wọn: Èmi ó sì jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rù mi, wọn kì yóò sì padà lẹ́yìn mi. 41 Lóòtítọ́, èmi ó yọ̀ nípa ṣíṣe wọ́n ní rere, èmi ó sì fi dá wọn lójú nípa gbígbìn wọ́n sí ilẹ̀ yìí tọkàntọkàn mi.

42 “Nítorí báyìí ni Olúwa wí: Gẹ́gẹ́ bí èmi ti mú gbogbo ibi ńlá yìí wá sórí àwọn ènìyàn yìí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó mú gbogbo rere tí èmi ti sọ nípa tiwọn wá sórí wọn. 43 Lẹ́ẹ̀kan sí i, pápá yóò di rírà ní ilẹ̀ yìí tí ìwọ ti sọ pé, ‘Ohun òfò ni tí kò bá sí ọkùnrin tàbí àwọn ẹran, nítorí tí a ti fi fún àwọn ará Babeli.’ 44 Wọn ó fi owó fàdákà ra oko, wọn yóò fi ọwọ́ sí ìwé, wọn ó dí pa pẹ̀lú ẹlẹ́rìí láti ilẹ̀ Benjamini àti ní ìlú kéékèèkéé tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda àti ní ìlú àwọn ìlú orí òkè, àti ni àwọn ẹsẹ̀ òkè, àti ní gúúsù, èmi ó mú ìgbèkùn wọn padà wá, ni Olúwa wí.”

Jakọbu 5:1-6

Ìkìlọ̀ fún àwọn aninilára ọlọ́rọ̀

Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin ọlọ́rọ̀, ẹ máa sọkún kí ẹ sì máa pohùnréré ẹkún nítorí òsì tí ó ń bọ̀ wá ta yín. Ọrọ̀ yín díbàjẹ́, kòkòrò sì ti jẹ aṣọ yín. Wúrà òun fàdákà yín díbàjẹ́; ìbàjẹ́ wọn ni yóò sì ṣe ẹlẹ́rìí sí yín, tí yóò sì jẹ ẹran-ara yín bí iná. Ẹ̀yin tí kó ìṣúra jọ de ọjọ́ ìkẹyìn. Kíyèsi i, ọ̀yà àwọn alágbàṣe tí wọ́n ti ṣe ìkórè oko yín, èyí tí ẹ kò san, ń ké rara; àti igbe àwọn tí ó ṣe ìkórè sì ti wọ inú etí Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ẹ̀yin ti jẹ adùn ní ayé, ẹ̀yin sì ti fi ara yín fún ayé jíjẹ; ẹ̀yin ti mú ara yín sanra de ọjọ́ pípa. Ẹ̀yin ti dá ẹ̀bi fún olódodo, ẹ sì ti pa á; ẹni tí kò kọ ojú ìjà sí yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.