Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 2:4-13

Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ìdílé Jakọbu
    àti gbogbo ẹ̀yin ará ilé Israẹli.

Báyìí ni Olúwa wí:

“Irú àìṣedéédéé wo ni baba yín rí lọ́wọ́ mi?
Tí wọ́n fi jìnnà sí mi?
    Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán,
    àwọn fúnrawọn sì di asán.
Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni Olúwa wà,
    tí ó mú wa jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
tí ó mú wa la aginjù já,
    tí ó mú wa la àárín pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti ihò,
ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn biribiri,
    ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kò sì tẹ̀dó sí?’
Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá
    láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀,
ṣùgbọ́n ẹ̀yin wọ inú rẹ̀, ẹ sì bà á jẹ́,
    ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
Àwọn àlùfáà kò béèrè wí pé,
    ‘Níbo ni Olúwa wà?’
Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí,
    àwọn olùṣọ́ sì ṣẹ̀ sí mi.
Àwọn wòlíì sì ń sọtẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà Baali,
    wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà asán.

“Nítorí náà, mo fi ẹ̀sùn kàn yín lẹ́ẹ̀kan sí i,”
    ni Olúwa wí.
    “Èmi ó sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ọmọ ọwọ́ rẹ
10 Rékọjá lọ sí erékùṣù àwọn ara Kittimu, kí ẹ sì wò ó,
    ránṣẹ́ lọ sí Kedari, kí ẹ sì kíyèsi gidigidi
kí ẹ wò bí irú nǹkan báyìí bá ń bẹ níbẹ̀?
11 Orílẹ̀-èdè kan ha á pa Ọlọ́run rẹ̀ dà?
    (Síbẹ̀, wọ́n kì í ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run)
àwọn ènìyàn mi ti pààrọ̀
    ògo wọn fún àwọn ère tí kò níyì.
12 Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
    kí ẹ sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù ńlá,”
    ni Olúwa wí.
13 “Àwọn ènìyàn mi ti dẹ́ṣẹ̀ méjì
    Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, Èmi
orísun omi ìyè, wọ́n sì ti
    ṣe àmù, àmù fífọ́ tí kò lè
    gba omi dúró.

Saamu 81:1

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
    Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!

Saamu 81:10-16

10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
    Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
    bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
    kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
    Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
    èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Heberu 13:1-8

Ìparí àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú náà

13 Kí ìfẹ́ ará kí o wà títí. (A)Ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣe àlejò; nítorí pé nípa bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn ṣe àwọn angẹli ní àlejò láìmọ̀. Ẹ máa rántí àwọn òǹdè bí ẹni tí a dè pẹ̀lú wọn, àti àwọn tí a ń pọn lójú bí ẹ̀yin tìkára yín pẹ̀lú tí ń bẹ nínú ara.

Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí: Nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́. (B)Kí ọkàn yín má ṣe fà sí ìfẹ́ owó, ki ohun tí ẹ ní tó yin; nítorí òun tìkára rẹ̀ ti wí pé,

“Èmi kò jẹ́ fi ọ́ sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kò jẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

(C)Nítorí náà ni àwa ṣe ń fi ìgboyà wí pé,

“Olúwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, èmi kì yóò bẹ̀rù;
    kín ni ènìyàn lè ṣe sí mi?”

Ẹ máa rántí àwọn tiwọn jẹ́ aṣáájú yín, tiwọn ti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún yín; kí ẹ máa ro òpin ìwà ayé wọn, kí ẹ sì máa ṣe àfarawé ìgbàgbọ́ wọn. Jesu Kristi ọ̀kan náà ni lánàá, àti lónìí, àti títí láé.

Heberu 13:15-16

15 (A)Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. 16 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín fun ni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ.

Luku 14:1

Jesu ní ilé Farisi kan

14 (A)Nígbà tí ó wọ ilé ọ̀kan nínú àwọn olórí Farisi lọ ní ọjọ́ ìsinmi láti jẹun, wọ́n sì ń ṣọ́ ọ.

Luku 14:7-14

Ó sì pa òwe kan fún àwọn tí ó pè é wá jẹun, nígbà tí ó ṣàkíyèsí bí wọ́n ti ń yan ipò ọlá; ó sì wí fún wọn pé: (A)“Nígbà tí ẹnìkan bá pè ọ́ wá sí ibi ìyàwó, má ṣe jókòó ní ipò ọlá; kí ó má ba à jẹ́ pé, a ó pe ẹni tí ó lọ́lá jù ọ́ lọ. Nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, a sì wí fún ọ pé, ‘Fún ọkùnrin yìí ní ààyè!’ Ìwọ á sì wá fi ìtìjú mú ipò ẹ̀yìn. 10 Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá pè ọ́, lọ kí o sì jókòó ní ipò ẹ̀yìn; nígbà tí ẹni tí ó pè ọ́ bá dé, kí ó lè wí fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, bọ́ sókè!’ Nígbà náà ni ìwọ ó ní ìyìn lójú àwọn tí ó bá ọ jókòó ti oúnjẹ. 11 (B)Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga, ni a ó rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ni a ó sì gbéga.”

12 (C)Nígbà náà ni ó sì wí fún alásè tí ó pè é pé, “Nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè má ṣe pe àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ, tàbí àwọn ọlọ́rọ̀ aládùúgbò rẹ̀; nítorí kí wọn má ṣe pè ọ́ padà láti san ẹ̀san padà. 13 (D)Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá ṣe àsè, pe àwọn tálákà, àwọn alábùkún ara, àwọn amúnkùn ún, àti àwọn afọ́jú: 14 Ìwọ ó sì jẹ́ alábùkún fún; nítorí wọn kò ní ohun tí wọn ó fi san án fún ọ: ṣùgbọ́n a ó san án fún ọ ní àjíǹde, àwọn olóòtítọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.