Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
10 Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?
2 Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
3 Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa
4 Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀;
5 Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
6 O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí;
Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”
7 (A)Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
8 Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò;
Ògo níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
9 Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”
12 Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
“Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;
pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀
tí a kò le è rí.
16 Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé;
àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
17 Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;
Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
18 Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,
kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,
kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.
27 “Nígbà tí ìwọ bá sọ gbogbo èyí fún wọn, wọn kì yóò gbọ́ tirẹ̀, nígbà tí ìwọ bá sì pè wọ́n, wọn kì yóò dáhùn. 28 Nítorí náà, sọ fún wọn pé ‘Èyí ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ti Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ tàbí kí ó ṣe ìgbọ́ràn sí ìbáwí. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ kò sí ní ètè wọn.
29 “ ‘Gé irun yín kí ẹ sì dàánù, pohùnréré ẹkún lórí òkè, nítorí Olúwa ti kọ ìran yìí tí ó wà lábẹ́ ìbínú rẹ̀ sílẹ̀.
Àfonífojì ìparun
30 “ ‘Àwọn ènìyàn Juda ti ṣe búburú lójú mi, ni Olúwa wí. Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́. 31 Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tofeti ní Àfonífojì Beni-Hinnomu láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò pàṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi. 32 Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí Àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ Àfonífojì Ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́ 33 Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. 34 (A)Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.
6 (A)Ní ọjọ́ ìsinmi mìíràn, ó wọ inú Sinagọgu lọ, ó sì ń kọ́ni, ọkùnrin kan sì ń bẹ níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ. 7 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi ń ṣọ́ ọ, bóyá yóò mú un láradá ní ọjọ́ ìsinmi; kí wọn lè rí ọ̀nà láti fi ẹ̀sùn kàn án. 8 Ṣùgbọ́n ó mọ èrò inú wọn, ó sì wí fún ọkùnrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde, kí o sì dúró láàrín.” Ó sì dìde dúró.
9 Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Èmi bi yín léèrè, Ó ha tọ́ láti máa ṣe rere ni ọjọ́ ìsinmi, tàbí láti máa ṣe búburú? Láti gba ọkàn là, tàbí láti pa á run?”
10 Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká, ó wí fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀: ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ̀ sípò gẹ́gẹ́ bí èkejì. 11 Wọ́n sì kún fún ìbínú gbígbóná; wọ́n sì bá ara wọn rò ohun tí àwọn ìbá ṣe sí Jesu.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.