Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Hosea 11:1-11

Ìfẹ́ Ọlọ́run sí Israẹli

11 (A)“Nígbà tí Israẹli wà ní ọmọdé mo fẹ́ràn rẹ̀,
    mo sì pe ọmọ mi jáde láti Ejibiti wá.
Bí a ti ń pe wọn,
    bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń sá kúrò lọ́dọ̀ mi,
wọn rú ẹbọ sí Baali,
    wọn sì fi tùràrí jóná sí ère fínfín.
Lóòtítọ́ mo kọ́ Efraimu pẹ̀lú ní ìrìn
    mo di wọ́n mú ní apá,
ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀
    pé mo ti mú wọn láradá.
Mo fi okùn ènìyàn fà wọ́n
    àti ìdè ìfẹ́.
Mo mú àjàgà kúrò ni ọrùn wọn
    Mo sì fi ara balẹ̀ fún wọn ni oúnjẹ.

“Ṣé wọn ò wá ní padà sí Ejibiti bí
    Ṣé Asiria kò sì ní jẹ ọba lé wọn lórí bí
    nítorí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti ronúpìwàdà?
Idà yóò kọ mọ̀nà ní gbogbo ìlú wọn
    yóò si bá gbogbo irin ẹnu odi ìlú wọn jẹ́
    yóò sì fi òpin sí gbogbo èrò wọn.
Àwọn ènìyàn mi ti pinnu láti pẹ̀yìndà kúrò lọ́dọ̀ mi
bí wọ́n tilẹ̀ pè wọ́n sọ́dọ̀ Ọ̀gá-ògo jùlọ,
    kò ní gbé wọn ga rárá.

“Báwo ni èmi ó ṣe fi ọ́ sílẹ̀, Efraimu?
    Báwo ni èmi ó ṣe yọ̀ǹda rẹ̀, Israẹli
Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Adma?
    Báwo ni mo ṣe lè ṣe ọ bi i Ṣeboimu?
Ọkàn mi yípadà nínú mi
    àánú mi sì ru sókè
Èmi kò ni mú ìbínú gbígbóná mi ṣẹ,
    tàbí kí èmi wá sọ Efraimu di ahoro.
Nítorí pé èmi ni Ọlọ́run, àní, èmi kì í ṣe ènìyàn
    Ẹni mímọ́ láàrín yín,
    Èmi kò ní í wá nínú ìbínú
10 Wọn yóò máa tẹ̀lé Olúwa;
    òun yóò bú ramúramù bí i kìnnìún
Nígbà tó bá bú
    àwọn ọmọ rẹ yóò wá ní ìwárìrì láti ìwọ̀-oòrùn.
11 Wọn ó wá pẹ̀lú ẹ̀rù
    bí i ẹyẹ láti Ejibiti
    bí i àdàbà láti Asiria
Èmi ó mú wọn padà sí ilé wọn,”
    ni Olúwa wí.

Saamu 107:1-9

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
    wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
    wọn ó máa gbé
Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
    ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
    tí wọn lè máa gbé
Ẹ jẹ́ kí wọn máa yin Olúwa nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ̀ àti nítorí iṣẹ́
    ìyanu rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn,
Nítorí tí ó tẹ́ ìfẹ́ ọkàn lọ́run
    ó sì fi ìre fún ọkàn tí ebi ń pa.

Saamu 107:43

43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí
    kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

Kolose 3:1-11

Àwọn òfin fún ìgbé ayé ìwà mímọ́

(A)Níwọ́n ìgbà tí a ti jí yín dìde pẹ̀lú Kristi ẹ máa ṣàfẹ́rí àwọn nǹkan tí ń bẹ lókè, níbi tí Kristi gbé wà tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Ẹ máa ronú àwọn ohun tí ń bẹ lókè kì í ṣe àwọn nǹkan tí ń bẹ ní ayé. Nítorí ẹ̀yin ti kú, a sì fi ìyè yín pamọ́ pẹ̀lú Kristi nínú Ọlọ́run. Nígbà tí Kristi, ẹni tí í ṣe ìyè yín yóò farahàn, nígbà náà ni ẹ̀yin pẹ̀lú yóò farahàn pẹ̀lú rẹ̀ nínú ògo.

Ẹ máa pa ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ ní ayé run: àgbèrè, panṣágà, ìwà àìmọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìwọra, nítorí pé ìwọ̀nyí jásí ìbọ̀rìṣà. Lórí àwọn wọ̀nyí ni ìbínú Ọlọ́run ń bọ̀ wá. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apá kan ayé yìí. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyí sílẹ̀: ìbínú, ìrunú, àrankàn, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín. Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ara yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀, 10 (B)tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé tuntun wọ̀, èyí tí a sọ di tuntun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dá a. 11 Níbi tí kò gbé sí Giriki tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìgbédè, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kristi ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

Luku 12:13-21

Ìtàn òmùgọ̀ ọlọ́rọ̀

13 Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”

14 Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, ta ni ó fi mí jẹ onídàájọ́ tàbí olùpíngún fún yín?” 15 (A)Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”

16 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 17 Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’

18 “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. 19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’

20 (B)“Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’

21 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.