Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 74

Maskili ti Asafu.

74 Ọlọ́run, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ wá sílẹ̀ títí láé?
    Èéṣe tí ìbínú rẹ̀ fi dìde sí àwọn àgùntàn pápá rẹ?
Rántí àwọn ènìyàn tí ìwọ ti rà nígbà àtijọ́,
    ẹ̀yà ilẹ̀ ìní rẹ, tí ìwọ ti rà padà
    Òkè Sioni, níbi tí ìwọ ń gbé.
Yí ẹsẹ̀ rẹ padà sí ìparun ayérayé wọn,
    gbogbo ìparun yìí tí ọ̀tá ti mú wá sí ibi mímọ́.

Àwọn ọ̀tá rẹ ń bú ramúramù
    láàrín ènìyàn rẹ,
wọ́n ń gbé àsíá wọn sókè fún ààmì;
Wọ́n ń rí bí ọkùnrin tí ó gbé àáké rẹ̀ sókè
    láti gé igi igbó dídí.
Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, iṣẹ́ ọnà fínfín,
    ni wọ́n fi àáké wó lulẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan náà.
Wọ́n sun ibi mímọ́ rẹ lulẹ̀
    wọ́n ba ibùgbé orúkọ rẹ jẹ́
Wọ́n wí ní ọkàn wọn. “Àwa ó run wọ́n pátápátá!”
    Wọ́n sun gbogbo ibi ìjọ́sìn Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà.

A kò fún wa ní ààmì iṣẹ́ ìyanu kankan;
    kò sí wòlíì kankan
    ẹnìkankan wa kò mọ ìgbà tí eléyìí yóò dà.
10 Àwọn ọ̀tá yóò ti kùn sí ọ pẹ́ tó, Ọlọ́run?
    Àwọn ọ̀tá yóò ha ba orúkọ rẹ jẹ́ títí láé?
11 Èéṣe tí ìwọ fi dá ọwọ́ rẹ dúró, ọwọ́ ọ̀tún rẹ?
    Mú un kúrò nínú ìṣẹ́po aṣọ rẹ kí o sì run wọ́n!

12 Ṣùgbọ́n ìwọ Ọlọ́run ni ọba mi láti ìgbà pípẹ́;
    Ó mú ìgbàlà wá sórí ilẹ̀ ayé.

13 Ìwọ ni ó la Òkun sílẹ̀ nípa agbára rẹ;
    Ìwọ fọ́ orí ẹ̀mí búburú nínú omi
14 Ìwọ fọ́ orí Lefitani túútúú, o sì fi ṣe oúnjẹ fun àwọn ẹ̀dá tí ń gbé inú ijù
    Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ sì ni alẹ́ pẹ̀lú;
    ìwọ fi ìdí oòrùn àti òṣùpá lélẹ̀.
15 Ìwọ ya orísun omi àti ìṣàn omi;
    Ìwọ mú kí odò tó ń sàn gbẹ
16 Tìrẹ ni ọ̀sán, tìrẹ ni òru pẹ̀lú;
    ìwọ yà oòrùn àti òṣùpá.
17 Ìwọ pààlà etí ayé;
    Ìwọ dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù.

18 Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
    bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́.
19 Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
    Má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé.
20 Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
    nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
21 Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
    jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ.
22 Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
    rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
23 Má ṣe gbàgbé ohùn àwọn ọ̀tá rẹ,
    bíbú àwọn ọ̀tá rẹ, tí ó ń pọ̀ sí i nígbà gbogbo.

Isaiah 27

Ìdáǹdè Israẹli

27 Ní ọjọ́ náà,

Olúwa yóò fi idà rẹ̀ jẹ ni ní yà
    idà rẹ̀ a mú bí iná tí ó tóbi tí ó sì lágbára
Lefitani ejò tí ń yọ̀ tẹ̀ẹ̀rẹ̀ n nì,
    Lefitani ejò tí ń lọ́ bìrìkìtì;
    Òun yóò sì pa ẹ̀mí búburú inú Òkun náà.

Ní ọjọ́ náà

“Kọrin nípa ọgbà àjàrà eléso kan.
    Èmi Olúwa ń bojútó o,
Èmi ó bomirin ín láti ìgbàdégbà.
    Èmi ó ṣọ́ ọ tọ̀sán tòru
    kí ẹnikẹ́ni má ba à pa á lára.
Inú kò bí mi.
    Bí ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n bá dojú ìjà kọ mí!
Èmi yóò dìde sí wọn ní ogun;
    Èmi yóò sì dáná sun gbogbo wọn.
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí wọn wá sọ́dọ̀ mi fún ààbò;
    jẹ́ kí wọ́n wá àlàáfíà pẹ̀lú mi,
    bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí wọn wá àlàáfíà pẹ̀lú mi.”

Ní ọjọ́ iwájú Jakọbu yóò ta gbòǹgbò,
    Israẹli yóò tanná yóò sì rudi
    èso rẹ̀ yóò sì kún gbogbo ayé.

Ǹjẹ́ Olúwa ti lù ú
    gẹ́gẹ́ bí ó ti lu àwọn tí ó lù ú bolẹ̀?
Ǹjẹ́ a ti pa á
    gẹ́gẹ́ bí a ti pa àwọn tí ó pa á?
Nípa ogun jíjà àti ìjìyà ti o le ni ó
    fi dojúkọ ọ́
pẹ̀lú ìjì gbígbóná ni ó lé e jáde,
    gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn fẹ́
Nítorí èyí báyìí ni ètùtù yóò ṣe wà
    fún ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu,
èyí ni yóò sì jẹ́ èso kíkún ti
    ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ rẹ:
Nígbà tí ó bá mú kí àwọn òkúta pẹpẹ
    dàbí òkúta ẹfun tí a fọ́ sí wẹ́wẹ́,
kì yóò sí ère Aṣerah tàbí pẹpẹ tùràrí
    tí yóò wà ní ìdúró.
10 Ìlú olódi náà ti dahoro,
    ibùdó ìkọ̀sílẹ̀, tí a kọ̀ tì
gẹ́gẹ́ bí aginjù;
    níbẹ̀ ni àwọn ọmọ màlúù ti ń jẹ oko
níbẹ̀ ni wọn ń sùn sílẹ̀;
    wọn sì jẹ gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ tán.
11 Nígbà tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ bá rọ, a ó ya wọn dànù
    àwọn obìnrin dé, wọ́n sì fi wọ́n dáná
nítorí aláìlóye ènìyàn ni wọn jẹ́;
    Nítorí náà ni ẹni tí ó dá wọn kì yóò ṣàánú fún wọn;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó mọ wọn kì yóò sì fi ojúrere wò wọ́n.

12 Ní ọjọ́ náà Olúwa yóò sì kó oore láti ìṣàn omi odo Eufurate wá títí dé Wadi ti Ejibiti, àti ìwọ, ìwọ ọmọ Israẹli, ni a ó kójọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. 13 (A)Àti ní ọjọ́ náà, a ó fun fèrè ńlá kan. Gbogbo àwọn tí ń ṣègbé lọ ní Asiria àti àwọn tí ń ṣe àtìpó ní Ejibiti yóò wá sin Olúwa ní òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.

Luku 19:45-48

Jesu nínú tẹmpili

45 (A)Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46 Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.”

47 (B)Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48 Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.