Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 71:1-6

71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
    Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
    dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
Jẹ́ àpáta ààbò mi,
    níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
    nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
    ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.

Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
    ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
    Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.

Jeremiah 1:1-3

Èyí ni ọ̀rọ̀ Jeremiah ọmọ Hilkiah ọ̀kan nínú àwọn àlùfáà ní Anatoti ní agbègbè ilẹ̀ Benjamini. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá ní ọdún kẹtàlá ní àkókò ìjọba Josiah ọmọ Amoni ọba Juda, Àti títí dé àsìkò Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda, títí dé oṣù karùn-ún ọdún kọkànlá Sedekiah ọmọ Josiah ọba Juda, nígbà tí àwọn ará Jerusalẹmu lọ sí ìgbèkùn.

Jeremiah 1:11-19

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ mí wá wí pé:

“Kí ni o rí Jeremiah?”

Mo sì dáhùn wí pé “Mo rí ẹ̀ka igi almondi.”

12 Olúwa sì wí fún mi pé, “Ó ti rí i bí ó ṣe yẹ, nítorí pé mo ti ń ṣọ láti rí i pé ọ̀rọ̀ mi wá sí ìmúṣẹ.”

13 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ mi wá ní ẹ̀ẹ̀kejì pé, “Kí ni o rí?” Mo sì dáhùn pé mo rí ìkòkò gbígbóná, tí ó ń ru láti apá àríwá.

14 Olúwa, sì wí fún mi pé, “Láti apá àríwá ni a ó ti mu ìdààmú wá sórí gbogbo àwọn tí ó ń gbé ní ilẹ̀ náà. 15 Mo sì ti ṣetán láti pe gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àríwá níjà,” ni Olúwa wí.

Àwọn ọba wọn yóò wá
    gbé ìtẹ́ wọn ró ní ojú ọ̀nà àbáwọlé
Jerusalẹmu. Wọn ó sì dìde sí gbogbo
    àyíká wọn àti sí gbogbo àwọn
    ìlú Juda.
16 Èmi yóò sì kéde ìdájọ́ mi lórí àwọn ènìyàn mi
    nítorí ìwà búburú wọn nípa kíkọ̀ mí sílẹ̀,
nípa rírúbọ sí ọlọ́run mìíràn
    àti sínsin àwọn ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe.

17 “Wà ní ìmúrasílẹ̀! Dìde dúró kí o sì sọ fún wọn ohunkóhun tí mo bá pàṣẹ fún wọn. Má ṣe jẹ́ kí wọ́n dẹ́rùbà ọ́, èmi yóò sì sọ ọ́ di ẹ̀rù níwájú wọn. 18 Ní òní èmi ti sọ ọ́ di ìlú alágbára, òpó irin àti odi idẹ sí àwọn ọba Juda, àwọn ìjòyè rẹ̀, sí àwọn àlùfáà àti àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà. 19 Wọn yóò dojú ìjà kọ ọ́, wọn kì yóò borí rẹ, nítorí wí pé èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì gbà ọ́,” ni Olúwa wí.

Luku 6:1-5

Olúwa ọjọ́ ìsinmi

(A)(B) Ní ọjọ́ ìsinmi kejì, Jesu ń kọjá láàrín oko ọkà; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì ń ya ìpẹ́ ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́. (C)Àwọn kan nínú àwọn Farisi sì wí fún wọn pé, “ki lo de tí ẹ̀yin fi ń ṣe èyí tí kò yẹ láti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi?”

(D)Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí ebi ń pa òun tìkára rẹ̀ àti àwọn tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀; (E)bi ó ti wọ ilé Ọlọ́run lọ, tí ó sì mú àkàrà ìfihàn tí ó sì jẹ ẹ́, tí ó sì fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú; tí kò yẹ fún un láti jẹ, bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà nìkan ṣoṣo?” Ó sì wí fún wọn pé, “Ọmọ ènìyàn ni Olúwa ọjọ́ ìsinmi.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.