Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
71 Nínú rẹ, Olúwa, ni mo ní ààbò;
Má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.
2 Gbà mí kí o sì tú mi sílẹ̀ nínú òdodo rẹ;
dẹ etí rẹ sí mi, kí o sì gbà mí.
3 Jẹ́ àpáta ààbò mi,
níbi tí èmi lè máa lọ,
pa àṣẹ láti gbà mí,
nítorí ìwọ ni àpáta àti odi agbára mi.
4 Gbà mí, Ọlọ́run mi, lọ́wọ́ àwọn olùṣe búburú,
ní ọwọ́ aláìṣòdodo àti ìkà ọkùnrin.
5 Nítorí ìwọ jẹ́ ìrètí mi, Olúwa Olódùmarè,
ìwọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé mi láti ìgbà èwe.
6 Mo gbẹ́kẹ̀lé ọ láti ìgbà ìbí mi;
Ìwọ mú mi jáde láti inú ìyá mi wá
èmi ó máa yìn ọ́ títí láé.
20 Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá,
tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré?
Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà,
ọrẹ yín kò sì wù mí.”
21 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú
àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn baba
àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n,
àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”
22 Báyìí ni Olúwa wí:
“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,
a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde
láti òpin ayé wá.
23 Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,
Wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú
wọ́n ń hó bí omi Òkun, bí wọ́n
ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ;
wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò
jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Sioni.”
24 Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,
ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa
bí obìnrin tí ń rọbí.
25 Má ṣe jáde lọ sí orí pápá
tàbí kí o máa rìn ní àwọn
ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà,
ìpayà sì wà níbi gbogbo.
26 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀,
kí ẹ sì sùn nínú eérú,
ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún
gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo
nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.
27 “Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́
irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin
tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí,
kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.
28 Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn.
Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì.
Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin,
wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.
29 Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan,
kí ó lè yọ́ òjé,
ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán;
a kò si ya ènìyàn búburú kúrò.
30 A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀,
nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”
Ní Tẹsalonika
17 Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà: 2 Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. 3 Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” 4 A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀.
5 Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. 6 Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. 7 Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” 8 Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. 9 Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.