Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Fún adarí orin. Ti Dafidi.
11 Ìgbẹ́kẹ̀lé mi wà nínú Olúwa.
Báwo ní ẹ̀yin ó ṣe sọ fún ọkàn mi pé:
“Fò gẹ́gẹ́ bi ẹyẹ lọ si orí òkè rẹ.
2 Wò ó nítorí náà, ènìyàn búburú fa ọfà rẹ̀;
wọn ti fi ọfà wọn sí ojú okùn
láti tafà níbi òjìji
sí àyà ẹni ìdúró ṣinṣin.
3 Nígbà tí ìpìlẹ̀ bá bàjẹ́
kí ni olódodo yóò ṣe?”
4 Olúwa ń bẹ nínú tẹmpili mímọ́ rẹ̀;
Olúwa ń bẹ lórí ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run.
Ó ń wo àwọn ọmọ ènìyàn;
ojú rẹ̀ ń yẹ̀ wọ́n wò.
5 Olúwa ń yẹ olódodo wò,
ṣùgbọ́n ènìyàn búburú àti àwọn tí o fẹ́ ìwà ipá
ni ọkàn rẹ̀ kórìíra.
6 Sí orí àwọn ènìyàn búburú ni yóò rọ̀jò
ẹ̀yín iná àti imí-ọjọ́ tí ń jó;
àti ìjì gbígbóná ní yóò jẹ ìpín wọn.
7 Nítorí, olódodo ní Olúwa,
o fẹ́ràn òdodo;
ẹni ìdúró ṣinṣin yóò sì rí i.
14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;
láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo
ọláńlá Olúwa.
15 Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;
gbé orúkọ Olúwa ga, àní
Ọlọ́run Israẹli,
ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun,
16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;
“Ògo ni fún olódodo n nì.”
Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé!
“Ègbé ni fún mi!
Alárékérekè dalẹ̀!
Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17 Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́,
ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà
yóò ṣubú sínú ihò,
ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò
ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú.
Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀
Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
19 Ilẹ̀ ayé ti fọ́
ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,
a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
20 Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,
ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;
Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù
tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.
21 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà
gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run
àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
22 A ó sì kó wọn jọ pọ̀,
gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò,
a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú,
a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
23 A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn;
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba
ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu,
àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.
41 Peteru sì wí pé, “Olúwa, ìwọ pa òwe yìí fún wa, tàbí fún gbogbo ènìyàn?”
42 (A)(B) Olúwa sì dáhùn wí pé, “Ta ni olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ìríjú náà, tí olúwa rẹ̀ fi jẹ olórí agbo ilé rẹ̀, láti máa fi ìwọ̀n oúnjẹ wọ́n fún wọn ní àkókò? 43 Ìbùkún ni fún ọmọ ọ̀dọ̀ náà, nígbà tí olúwa rẹ̀ bá dé, tí yóò bá a kí ó máa ṣe bẹ́ẹ̀. 44 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín yóò fi jẹ olórí ohun gbogbo tí ó ní. 45 Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá wí ní ọkàn rẹ̀, pé, ‘Olúwa mi fi ìgbà bíbọ̀ rẹ̀ falẹ̀!’ Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ àti sí mu àmupara: 46 Olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ náà yóò dé ní ọjọ́ tí kò retí rẹ̀, àti ní wákàtí tí kò dábàá, yóò sì jẹ ẹ́ ní yà gidigidi, yóò sì yan ipò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́.
47 (C)“Àti ọmọ ọ̀dọ̀ náà, tí ó mọ ìfẹ́ olúwa rẹ̀, tí kò sì múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, òun ni a ó nà púpọ̀. 48 Ṣùgbọ́n èyí tí kò mọ̀, tí ó ṣe ohun tí ó yẹ sí lílù, òun ni a ó lù níwọ̀n. Nítorí ẹnikẹ́ni tí a fún ní púpọ̀, lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a ó gbé béèrè púpọ̀: lọ́dọ̀ ẹni tí a bá gbé fi púpọ̀ sí, lọ́dọ̀ rẹ ni a ó gbé béèrè sí i.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.