Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 10

10 Èéha ti ṣe, Olúwa, tí ìwọ fi dúró ní òkè réré?
    Èéha ti ṣe, tí ìwọ fi ara rẹ pamọ́ ní ìgbà ìpọ́njú?

Nínú àrékérekè ni ènìyàn búburú tí mu aláìlera,
    ẹni ti ó mú nínú ìdẹ̀kùn àrékérekè rẹ̀.
Nítorí ènìyàn búburú ń ṣògo ìfẹ́ inú ọkàn rẹ̀;
    Ó bùkún olójúkòkòrò, ó sì ń kẹ́gàn Olúwa
Ènìyàn búburú kò lè rí nínú ìgbéraga rẹ̀;
    kò sí ààyè fún Ọlọ́run nínú gbogbo èrò rẹ̀;
Ọ̀nà rẹ̀ ń gún régé nígbà gbogbo;
    òun ń gbéraga, òfin rẹ̀ sì jìnnà sí i;
    òun kẹ́gàn àwọn ọ̀tá rẹ̀.
O wí fún ara rẹ̀, “Kò sí ohun tí ó lè mì mí;
    Inú mi yóò máa dùn nígbà gbogbo, èmi kò sì ní ní wàhálà.”

(A)Ẹnu rẹ̀ kún fún ègún àti irọ́ àti ìtànjẹ;
    wàhálà àti ohun búburú wà lábẹ́ ahọ́n rẹ̀.
Ó lúgọ ní bùba nítòsí ìletò;
    Ògo níbi ìkọ̀kọ̀ láti pa aláìṣẹ̀.
Ojú rẹ̀ ń ṣọ́ àwọn tálákà ní ìkọ̀kọ̀.
    Ó ba ní ní bùba bí i kìnnìún nínú pàǹtí;
Ó ba ní bùba láti mú àwọn aláìní ìrànwọ́;
    ó mú àwọn aláìlólùrànlọ́wọ́, ó sì wọ́ wọn lọ sínú àwọ̀n rẹ̀.
10 Ó ba, ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀;
    kí tálákà ba à le bọ́ sí ọwọ́ agbára rẹ̀.
11 Ó wí fún ara rẹ̀, “Ọlọ́run ti gbàgbé;
    Ó pa ojú rẹ̀ mọ́, òun kì yóò rí i láéláé.”

12 Dìde, Olúwa! Gbé ọwọ́ rẹ sókè, Ọlọ́run.
    Má ṣe gbàgbé àwọn olùpọ́njú.
13 Èéṣe tí ènìyàn búburú ṣe ń kẹ́gàn Ọlọ́run?
    Èéṣe tí o fi wí nínú ọkàn ara rẹ̀,
    “Kò ní pè mí láti ṣe ìṣirò”?
14 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni ó rí wàhálà àti ìrora;
    Ìwọ rò láti fi sí ọwọ́ rẹ.
Tálákà fi ara rẹ̀ jì fún ọ;
    Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àwọn aláìní baba.
15 Ṣẹ́ apá àwọn ènìyàn búburú àti ènìyàn ibi;
    pè é láti wá ṣírò fún ìwà ìkà rẹ̀
    tí a kò le è rí.

16 Olúwa ń jẹ ọba láé àti láéláé;
    àwọn orílẹ̀-èdè yóò ṣègbé lórí ilé rẹ.
17 Ìwọ́ gbọ́, Olúwa, ìfẹ́ àwọn tí a ni lára;
    Ìwọ gbà wọ́n níyànjú, ó sì gbọ́ igbe wọn,
18 Láti ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní baba àti àwọn ti a ni lára,
    kí ọkùnrin, tí ó wà ní ayé,
    kí ó má ṣe dẹ́rùbà ni mọ́.

Jeremiah 7:16-26

16 “Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ. 17 Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 18 Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè. 19 Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni Olúwa wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?

20 “ ‘Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò tú ìbínú àti ìrunú mi sí orílẹ̀ yìí ènìyàn àti ẹranko, igi, pápá àti èso orí ilẹ̀, yóò sì jó tí kò ní ṣe é pa.

21 “ ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: Tẹ̀síwájú kí ẹ kó ẹbọ sísun yín àti àwọn ẹbọ yòókù papọ̀ kí ẹ̀yin kí ó sì jẹ ẹran wọ́n fúnrayín. 22 Ní tòsí nígbà tí mo mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti tí mo sì bá wọn sọ̀rọ̀. N kò pàṣẹ fún wọn lórí ẹbọ sísun lásán. 23 Mo pàṣẹ fún wọn báyìí pé: Gbọ́ tèmi, èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi. Máa rìn ní ojú ọ̀nà tí mo pàṣẹ fún yín, kí ó lè dára fún yín. 24 Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, wọn kò sì fetísílẹ̀ dípò èyí wọ́n ń tẹ̀ sí ọ̀nà agídí ọkàn wọn. Dípò kí wọn tẹ̀síwájú wọ́n ń rẹ̀yìn. 25 Láti ìgbà tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní Ejibiti títí di òní, ni èmi ti ń rán àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì sí yín. 26 Wọn kò gbọ́ wọn kò sì fetísílẹ̀. Wọ́n wa ọrùn le, wọn wa ọrùn kì, wọ́n sì hu ìwà ìbàjẹ́ ju àwọn baba ńlá wọn.’

Ìfihàn 3:7-13

Sí ìjọ Filadelfia

(A)“Àti sí angẹli Ìjọ ni Filadelfia kọ̀wé:

Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòtítọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dafidi, ẹni tí ó ṣí, tí kò sí ẹni tí yóò tì; ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i:

Èmi mọ iṣẹ́ rẹ̀: kíyèsi i, mo gbe ìlẹ̀kùn tí ó ṣí kálẹ̀ níwájú rẹ̀, tí kò sí ẹni tí o lè tì í; pé ìwọ ni agbára díẹ̀, ìwọ sì pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, ìwọ kò sì sẹ́ orúkọ mi. (B)Kíyèsi i, èmi ó mú àwọn ti Sinagọgu Satani, àwọn tí wọ́n ń wí pé Júù ni àwọn, tí wọn kì í sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọn ń ṣèké; kíyèsi i, èmi ó mú kí wọn wá wólẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ rẹ̀, kí wọn sì mọ̀ pé èmi tí fẹ́ ọ. 10 Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò.

11 Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán: di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ. 12 (C)Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́: èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi. 13 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.