Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 81:1

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
    Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!

Saamu 81:10-16

10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
    Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
    bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
    kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
    Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
    èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

Jeremiah 11:1-17

11 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wá: “Fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí o sì sọ wọ́n fún àwọn ènìyàn Juda, àti gbogbo àwọn tó ń gbé ni Jerusalẹmu. Sọ fún wọn wí pé èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ègbé ni fún ẹni náà tí kò pa ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́. Àwọn májẹ̀mú tí mo pàṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, nígbà tí mo mú wọn jáde láti Ejibiti, láti inú iná alágbẹ̀dẹ wá.’ Mo wí pé, ‘Ẹ gbọ́ tèmi, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún un yín. Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ènìyàn mi: Èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run yín Nígbà náà ni Èmi ó sì mú ìlérí tí mo búra fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ; láti fún wọn ní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin,’ ilẹ̀ tí ẹ ní lónìí.”

Mo sì dáhùn wí pé, “Àmín, Olúwa.”

Olúwa wí fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda àti ní gbogbo òpópónà ìgboro Jerusalẹmu pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí, kí ẹ sì se wọn. Láti ìgbà tí mo ti mú àwọn baba yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá títí di òní, mo kìlọ̀ fún wọn lọ́pọ̀ ìgbà wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi.” Ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kọbi ara sí i dípò èyí wọ́n tẹ̀síwájú ni agídí ọkàn wọn. Mo sì mú gbogbo ègún inú májẹ̀mú tí mo ti ṣèlérí, tí mo sì ti pàṣẹ fún wọn láti tẹ̀lé, tí wọn kò tẹ̀lé wa sórí wọn.’ ”

Olúwa sì wí fún mi pé, “Ọ̀tẹ̀ kan wà láàrín àwọn ará Juda àti àwọn tí ń gbé ní Jerusalẹmu. 10 Wọ́n ti padà sí ìdí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn tí wọn kọ̀ láti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi, wọ́n ti tẹ̀lé àwọn ọlọ́run mìíràn láti sìn wọ́n. Ilé Israẹli àti ilé Juda ti ba májẹ̀mú tí mo dá pẹ̀lú àwọn baba ńlá wọn jẹ́. 11 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi yóò mu ibi tí wọn kò ní le è yẹ̀ wá sórí wọn, bí wọ́n tilẹ̀ ké pè mí èmi kì yóò fetí sí igbe wọn. 12 Àwọn ìlú Juda àti àwọn ará Jerusalẹmu yóò lọ kégbe sí àwọn òrìṣà tí wọ́n ń sun tùràrí sí; àwọn òrìṣà náà kò ní ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìgbà tí ìpọ́njú náà bá dé. 13 Ìwọ Juda, bí iye àwọn ìlú rẹ, bẹ́ẹ̀ iye àwọn òrìṣà rẹ; bẹ́ẹ̀ ni iye pẹpẹ tí ẹ̀yin ti tẹ́ fún sísun tùràrí Baali ohun ìtìjú n nì ṣe pọ̀ bí iye òpópónà tí ó wà ní Jerusalẹmu.’

14 “Má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí pé, Èmi kì yóò dẹtí sí wọn nígbà tí wọ́n bá ké pè mí ní ìgbà ìpọ́njú.

15 “Kí ni olùfẹ́ mi ní í ṣe ní tẹmpili mi,
    bí òun àti àwọn mìíràn ṣe ń hu oríṣìíríṣìí ìwà àrékérekè?
Ǹjẹ́ ẹran tí a yà sọ́tọ̀ lè mú ìjìyà kúrò lórí rẹ̀?
    Nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ búburú rẹ̀,
    nígbà náà jẹ́ kí inú rẹ̀ kí ó dùn.”

16 Olúwa pè ọ́ ní igi olifi
    pẹ̀lú èso rẹ tí ó dára ní ojú.
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ìjì líle
    ọ̀wọ́-iná ni yóò sun ún
    tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóò sì di gígé kúrò.

17 Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí ó dá ọ ti kéde ibi sí ọ, nítorí ilé Israẹli àti Juda ti ṣe ohun ibi, wọ́n sì ti mú inú bí mi, wọ́n ti ru ìbínú mi sókè nípa sísun tùràrí si Baali.

1 Peteru 3:8-12

Jíjìyà fún ṣíṣe iṣẹ́ rere

Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10 (A)Nítorí,

“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,
    ti yóò sì rí ọjọ́ rere,
kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,
    àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;
    kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,
    etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn:
ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.