Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 80:1-2

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Ti Safu. Saamu.

80 Gbọ́ tiwa, ìwọ olùṣọ́-àgùntàn Israẹli;
    ìwọ tí ó darí Josẹfu bí ọ̀wọ́ ẹran;
    ìwọ tí o jókòó lórí ìtẹ́ láàrín Kérúbù, tàn jáde
Níwájú Efraimu, Benjamini àti Manase.
    Ru agbára rẹ̀ sókè;
wá fún ìgbàlà wa.

Saamu 80:8-19

Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
    ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
    ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
    ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
    ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.

12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
    tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
    àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
    Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 Gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
    àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.

16 A gé àjàrà rẹ lulẹ̀, a ti fi iná sun ún;
    ní ìfibú, àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ṣègbé.
17 Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó wà lára ọkùnrin tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
    ọmọ ènìyàn tí ìwọ tí gbé kalẹ̀ fún ara rẹ.
18 Nígbà náà àwa kí yóò yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
    mú wa yè, àwa o sì máa pe orúkọ rẹ.

19 Tún wa yípadà, Olúwa Ọlọ́run alágbára;
    kí ojú rẹ̀ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,
    kí á ba à lè gbà wá là.

Isaiah 3:18-4:6

18 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá 19 gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú, 20 gbogbo gèlè, ẹ̀gbà ọrùn, ẹsẹ̀ àti àyà, àwọn ìgò tùràrí àti òògùn, 21 òrùka ọwọ́ àti ti imú, 22 àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́, 23 Dígí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.

24 Dípò òórùn dídùn, òórùn búburú ni yóò wá,
    okùn ni yóò wà dípò àmùrè,
orí pípá ni yóò dípò irun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́
    aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.
25 Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú,
    àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.
26 Àwọn bodè Sioni yóò sọkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀,
    nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.
Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje
    yóò dì mọ́ ọkùnrin kan
yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa
    a ó sì pèsè aṣọ ara wa;
sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá.
    Mú ẹ̀gàn wa kúrò!”

Ẹ̀ka Olúwa náà

(A)Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná. Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sórí òkè Sioni àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà. Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.

Matiu 24:15-27

15 (A)“Nítorí náà, nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí a ti ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, tí ó bá dúró ní ibi mímọ́, (ẹni tí ó bá kà á, kí òye kí ó yé e). 16 Nítorí náà, jẹ́ kí àwọn tí ó wà ní Judea sálọ sí àwọn orí òkè. 17 Kí ẹni tí ó wà lórí ilé rẹ̀ má ṣe sọ̀kalẹ̀ wá mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 18 Kí àwọn tí ó sì wà lóko má ṣe darí wá sí ilé láti mú àwọn aṣọ wọn. 19 Ṣùgbọ́n àánú ṣe mí fún àwọn obìnrin ti ó lóyún, àti fún àwọn tí ó ń fún ọmọ loyan ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì! 20 Ẹ sì máa gbàdúrà kí sísá yín má ṣe jẹ́ ìgbà òtútù, tàbí ọjọ́ ìsinmi. 21 Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.

22 “Lóòótọ́, àfi bí a ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú, gbogbo ẹ̀dá alààyè yóò ṣègbé. Ṣùgbọ́n nítorí ti àwọn àyànfẹ́ ni a ó fi ké ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì kúrú. 23 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún yín pé, ‘Wo Kristi náà,’ tàbí pé ó ti farahàn níhìn-ín tàbí lọ́hùn ún, ẹ má ṣe gbà á gbọ́. 24 Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn èké wòlíì yóò dìde. Wọn yóò sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ààmì àti ìyanu. Bí ó bá lè ṣe é ṣe wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run pàápàá jẹ. 25 Wò ó, mo ti kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀.

26 (B)“Nítorí náà, bí ẹnìkan bá sọ fún yín pé, ‘Olùgbàlà ti dé,’ àti pé, ‘Ó wà ní aginjù,’ ẹ má ṣe wàhálà láti lọ wò ó, tàbí tí wọ́n bá ní ó ń fi ara pamọ́ sí iyàrá, ẹ má ṣe gbà wọn gbọ́. 27 Nítorí bí mọ̀nàmọ́ná ti ń tàn láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni wíwá Ọmọ Ènìyàn yóò jẹ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.