Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 60

Fún adarí orin. Tí ohùn “Lílì ti Májẹ̀mú.” Miktamu ti Dafidi. Fún ìkọ́ni. Nígbà tí ó bá Aramu-Naharaimu àti Siria-Soba jà, àti nígbà tí Joabu yípadà tí ó sì pa ẹgbẹ̀rún méjìlá àwọn ará Edomu ní Àfonífojì Iyọ̀.

60 Ìwọ ti kọ̀ wá sílẹ̀,
    Ọlọ́run, ìwọ ti tú wa ká,
ìwọ ti bínú nísinsin yìí, tún ara rẹ yípadà sí wa.
Ìwọ ti mú ilẹ̀ wárìrì, ìwọ ti fọ́ ọ;
    mú fífọ́ rẹ̀ bọ̀ sípò, nítorí tí ó mì.
Ìwọ ti fi ìgbà ewu han àwọn ènìyàn rẹ;
    Ìwọ fún wa ní wáìnì tí ó máa ń ta wá gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
Àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, ní ìwọ fi ọ̀págun fún
    kí a lè fihàn nítorí òtítọ́. Sela.

(A)Fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbà wá, kí o sì ràn wá lọ́wọ́,
    kí a lè gba àwọn tí o fẹ́ là.
Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀:
    “Ní ayọ̀, èmi ó pọ Ṣekemu jáde
    èmi ó sì wọ́n Àfonífojì Sukkoti.
Tèmi ni Gileadi, tèmi sì ni Manase;
    Efraimu ni àṣíborí mi,
    Juda sì ni ọ̀pá àṣẹ mi.
Moabu ní ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi,
    lórí Edomu ní mo bọ́ bàtà mi sí;
    lórí Filistia ni mo kígbe ayọ̀.”

Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi nì?
    Ta ni yóò tọ́ mí lọ sí Edomu?
10 Kì í ha ń ṣe ìwọ, Ọlọ́run, tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀
    tí o kò sì bá ogun wa jáde mọ́?
11 Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀tá,
    nítorí asán ni ìrànlọ́wọ́ ènìyàn.
12 Nípa Ọlọ́run ni a óò ní ìṣẹ́gun,
    yóò sì tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Hosea 13

Ìbínú Olúwa sí Israẹli

13 Nígbà ti Efraimu bá ń sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn máa ń wárìrì,
    a gbé e ga ní Israẹli
    ṣùgbọ́n ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó ń sin òrìṣà Baali, ó sì kú.
Báyìí, wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀
    wọn fi fàdákà ṣe ère òrìṣà fúnrawọn
ère tí a fi ọgbọ́n dá àrà sí
    gbogbo wọn jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà
Wọn ń sọ nípa àwọn ènìyàn
    wọ̀nyí. Pé, Jẹ́ kí àwọn
    “Ènìyàn tí ń rú ẹbọ fi ẹnu
    ko àwọn ẹgbọrọ màlúù ni ẹnu.”
Nítorí náà wọn yóò dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀,
    bí ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù tó máa ń parẹ́,
    bí i èèpo ìyẹ̀fun tí afẹ́fẹ́ gbé láti ibi ìpakà
    bí èéfín tó rú jáde gba ojú fèrèsé.

“Ṣùgbọ́n Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ̀,
    ẹni tó mú ọ jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá.
Ìwọ̀ kì yóò sì mọ ọlọ́run mìíràn àfi èmi
    kò sí olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi
Mo ṣe ìtọ́jú rẹ ní aginjù
    ní ilẹ̀ tí ó gbẹ tí kò ní omi
Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹ
    Nígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéraga
    Nígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi.
Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìún
    Èmi yóò fi ara pamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.
Beari igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbà
    Èmi yóò bá wọn jà bí?
Èmi yóò sì fà wọ́n ya
    bí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya
    bi ẹranko búburú ni èmi yóò fa wọn ya.

“A ti pa ọ́ run, ìwọ Israẹli
    nítorí pé ìwọ lòdì sí mi, ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ.
10 Níbo ni ọba rẹ gbé wà nísinsin yìí kí ó bá à le gbà ọ là?
    Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà,
àwọn tí ẹ sọ pé,
    ‘Fún wa ní ọba àti ọmọ-aládé’?
11 Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín ní ọba,
    Nínú ìbínú gbígbóná mi, mo sì mú un kúrò.
12 Ẹ̀bi Efraimu ni a tí ko jọ
    gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀
13 Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá a
    Ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́n
Nígbà tí àsìkò tó,
    ó kọ̀ láti jáde síta láti inú.

14 “Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú.
    Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikú
Ikú, àjàkálẹ̀-ààrùn rẹ dà?
    Isà òkú, ìparun rẹ dà?

“Èmi kò ní ṣàánú mọ́.
15     Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀
afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yóò wá,
    Yóò fẹ́ wá láti inú aginjù
orísun omi rẹ̀ yóò gbẹ
    kànga rẹ̀ yóò gbẹ
pẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrù
    àti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀
16 Ará Samaria gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn,
    nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn.
Wọn ó ti ipa idà ṣubú;
    a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀,
    A ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”

Kolose 4:2-6

Àwọn ìlànà fún ìjọ

Ẹ fi ara yín jì fún àdúrà gbígbà, kí ẹ ṣọ́ra kí ẹ sì máa dúpẹ́; Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. (A)Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.