Add parallel Print Page Options

30 Bí Isaaki ti súre tán tí Jakọbu ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde kúrò ní ọ̀dọ̀ baba rẹ̀ ni Esau ti oko ọdẹ dé. 31 Òun pẹ̀lú ṣe ẹran dídùn, ó sì gbé e tọ baba rẹ̀ wá, ó sì wí fún un pé, “Baba mi, dìde jókòó, kí o sì jẹ nínú ẹran igbó tí mo ti ṣè, kí o sì súre fún mi.”

32 Isaaki baba rẹ̀ sì bi í wí pé, “Ìwọ ta ni?”

Ó sì dáhùn pé “Èmi Esau, àkọ́bí rẹ ni.”

33 Nígbà náà ni Isaaki wárìrì gidigidi, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni náà, tí ó ti pa ẹran igbó tí ó sì ti gbe wá fún mi, tí mo sì ti jẹ ẹ́ kí ó tó dé? Mo sì ti súre fún un, sì wò ó dájúdájú a ó sì bùkún un!”

34 Nígbà tí Esau gbọ́ ọ̀rọ̀ baba rẹ̀, ó ké, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún kíkorò, ó sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Baba mi súre fún èmi náà, àní fún èmi náà pẹ̀lú.”

35 Ṣùgbọ́n Isaaki wí pé, “Àbúrò rẹ ti fi ẹ̀tàn wá, ó sì ti gba ìbùkún rẹ lọ.”

36 (A)Esau sì wí pé, “Lásán ni a pe orúkọ rẹ̀ ní Jakọbu (Arẹ́nijẹ) bí? Ní ìgbà méjì yìí ni ó ti tàn mí jẹ: ní àkọ́kọ́, ó gba ogún ìbí mi, nísinsin yìí, ó tún gba ìbùkún mi! Háà! Baba mi, ṣe o kò wá fi ìre kankan sílẹ̀ fun mi ni?”

37 Isaaki sì dá Esau lóhùn pé, “Mo ti fi ṣe olórí rẹ àti àwọn ìbátan rẹ ni mo fi ṣe ìránṣẹ́ fún un, àti ọkà àti wáìnì ni mo ti fi lé e lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, kí ni ó tún kù tí ǹ bá tún fún ọ báyìí ọmọ mi?”

38 Esau sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Ṣe ìre kan ṣoṣo ni ìwọ ní lẹ́nu ni baba mi? Súre fún èmi náà, baba mi.” Esau sì sọkún kíkankíkan.

39 Isaaki baba rẹ̀ sì dá a lóhùn pé,

“Ibùjókòó rẹ
    yóò jìnnà sí ọ̀rá ilẹ̀,
    àti sí ibi ìrì ọ̀run láti òkè wá.
40 Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé,
    ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ,
ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára
    ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀
    kúrò lọ́rùn rẹ.”

Read full chapter