Chronological
Ìránṣẹ́ Olúwa Náà
49 (A)Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù:
gbọ́ èyí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè jíjìnnà réré:
kí a tó bí mi Olúwa ti pè mí;
láti ìgbà bíbí mi ni ó ti dá orúkọ mi.
2 Ó ṣe ẹnu mi bí idà tí a pọ́n,
ní abẹ́ òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́:
ó ṣe mí ní ọfà tí a ti dán,
ó sì fi mí pamọ́ sínú àpò rẹ̀.
3 Ó sọ fún mi pé, “ìránṣẹ́ mi ni ìwọ í ṣe,
Israẹli nínú ẹni tí n ó ti fi ògo mi hàn.”
4 (B)Ṣùgbọ́n èmi sọ pé, “Mo ti ṣe wàhálà lórí asán;
mo ti lo gbogbo ipá mi lórí asán àti ìmúlẹ̀mófo.
Síbẹ̀síbẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí mi ṣì wà lọ́wọ́ Olúwa,
èrè mi sì ń bẹ pẹ̀lú Ọlọ́run mi.”
5 Nísinsin yìí Olúwa wí pé
ẹni tí ó mọ̀ mí láti inú wá láti jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀
láti mú Jakọbu padà tọ̀ mí wá
àti láti kó Israẹli jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
nítorí pé a bọ̀wọ̀ fún mi ní ojú Olúwa
Ọlọ́run mi sì ti jẹ́ agbára mi
6 (C)Òun wí pé:
“Ó jẹ́ ohun kékeré fún ọ láti jẹ́ ìránṣẹ́ mi
láti mú ẹ̀yà Jakọbu padà bọ̀ sípò
àti láti mú àwọn ti Israẹli tí mo ti pamọ́.
Èmi yóò sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn kèfèrí,
kí ìwọ kí ó lè mú ìgbàlà mi wá
sí òpin ilẹ̀ ayé.”
7 Ohun tí Olúwa wí nìyìí—
Olùdáǹdè àti Ẹni Mímọ́ Israẹli—
sí ẹni náà tí a gàn tí a sì kórìíra
lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè,
sí ìránṣẹ́ àwọn aláṣẹ:
“Àwọn ọba yóò rí ọ wọn yóò sì dìde sókè,
àwọn ọmọ ọba yóò rí i wọn yóò sì wólẹ̀,
nítorí Olúwa ẹni tí í ṣe olóòtítọ́,
Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó ti yàn ọ́.”
Ìmúpadàbọ̀sípò Israẹli
8 (D)Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Ní àkókò ojúrere mi, èmi yóò dá ọ lóhùn,
àti ní ọjọ́ ìgbàlà, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́;
Èmi yóò pa ọ́ mọ́, n ó sì ṣe ọ́
láti jẹ́ májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn,
láti mú ilẹ̀ padà bọ̀ sípò
àti láti ṣe àtúnpín ogún rẹ̀ tí ó ti dahoro,
9 Láti sọ fún àwọn ìgbèkùn pé, ‘Ẹ jáde wá’
àti fún àwọn tí ó wà nínú òkùnkùn pé, ‘Ẹ gba òmìnira!’
“Wọn yóò máa jẹ ní ẹ̀bá ọ̀nà
àti koríko tútù lórí òkè aláìléwéko.
10 (E)Ebi kì yóò pa wọ́n bẹ́ẹ̀ ni òǹgbẹ kì yóò gbẹ wọ́n,
tàbí kí ooru inú aṣálẹ̀ tàbí oòrùn kí ó pa wọ́n.
Ẹni tí ó ṣàánú fún wọn ni yóò máa tọ́ wọn,
tí yóò sì mú wọn lọ sí ibi orísun omi.
11 Èmi yóò sọ gbogbo àwọn òkè-ńlá mi di ojú ọ̀nà
àti gbogbo òpópónà mi ni a ó gbé sókè.
12 Kíyèsi i, wọn yóò wá láti ọ̀nà jíjìn
àwọn díẹ̀ láti àríwá àti àwọn díẹ̀
láti ìwọ̀-oòrùn,
àwọn díẹ̀ láti ẹkùn Siene.”
13 (F)Ẹ hó fún ayọ̀, ẹyin ọ̀run;
yọ̀, ìwọ ilẹ̀ ayé;
bú sórin, ẹ̀yin òkè ńlá!
Nítorí Olúwa tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú
yóò sì ṣàánú fún àwọn ẹni
tí a ń pọ́n lójú.
14 Ṣùgbọ́n Sioni sọ pé, “Olúwa ti kọ̀ mí sílẹ̀,
Olúwa ti gbàgbé è mi.”
15 “Ǹjẹ́ abiyamọ ha le gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀
kí ó má sì ṣàánú fún ọmọ rẹ̀ tí ó ti bí?
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun le gbàgbé
Èmi kì yóò gbàgbé rẹ!
16 Kíyèsi i, mo ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi
ògiri rẹ wà níwájú mi nígbà gbogbo.
17 Àwọn ọmọ rẹ ti kánjú padà,
àti àwọn tí ó sọ ọ́ dahoro ti padà lẹ́yìn rẹ.
18 Gbójú rẹ sókè kí o sì wò yíká;
gbogbo àwọn ọmọkùnrin rẹ kórajọ
wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ.
Níwọ́n ìgbà tí mo bá wà láààyè,” ni Olúwa wí,
“Ìwọ yóò wọ gbogbo wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun ọ̀ṣọ́;
ìwọ yóò wọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ìyàwó.
19 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí run ọ́, a sì sọ ọ́ di ahoro
tí gbogbo ilẹ̀ rẹ sì di ìparun,
ní ìsinsin yìí, ìwọ yóò kéré jù fún àwọn ènìyàn rẹ,
bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ó jẹ ọ́ run ni yóò
wà láti ọ̀nà jíjìn réré.
20 Àwọn ọmọ tí a bí ní àkókò ọ̀fọ̀ rẹ
yóò sọ ní etígbọ̀ọ́ rẹ,
‘Ibi yìí ti kéré jù fún wa;
ẹ fún wa láyè sí i tí a ó máa gbé.’
21 Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní ọkàn rẹ pé,
‘ta ló bí àwọn yìí fún mi?
Mo ti ṣọ̀fọ̀ mo sì yàgàn;
A sọ mi di àtìpó a sì kọ̀ mí sílẹ̀.
Ta ló wo àwọn yìí dàgbà?
A fi èmi nìkan sílẹ̀,
ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí níbo ni wọ́n ti wá?’ ”
22 Ohun tí Olúwa Olódùmarè wí nìyìí:
“Kíyèsi i, Èmi yóò ké sí àwọn aláìkọlà
Èmi yóò gbé àsíá mi sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn;
Wọn yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín wá ní apá wọn
wọn yóò sì gbé àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin
ní èjìká wọn.
23 Àwọn ọba ni yóò jẹ́ alágbàtọ́ baba fún ọ,
àwọn ayaba wọn ni yóò sì jẹ́ ìyá-alágbàtọ́.
Wọn yóò foríbalẹ̀ ní iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ojú wọn dídàbolẹ̀;
wọn yóò máa lá erùpẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ rẹ.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa;
gbogbo àwọn tí wọ́n ní ìrètí nínú mi
ni a kì yóò jákulẹ̀.”
24 Ǹjẹ́ a le gba ìkógun lọ́wọ́ jagunjagun,
tàbí kí á gba ìgbèkùn lọ́wọ́ akíkanjú?
25 Ṣùgbọ́n ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Bẹ́ẹ̀ ni, a ó gba àwọn ìgbèkùn lọ́wọ́ àwọn jagunjagun,
àti ìkógun lọ́wọ́ àwọn akíkanjú;
Ẹni tí ó bá ọ jà ni èmi ó bá jà,
àti àwọn ọmọ rẹ ni èmi ó gbàlà.
26 Èmi yóò mú kí àwọn aninilára rẹ̀ jẹ
ẹran-ara wọn;
wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó
bí ẹni mu wáìnì.
Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn yóò mọ̀
pé Èmi, Olúwa, èmi ni Olùgbàlà rẹ,
Olùdáǹdè rẹ, Alágbára kan ṣoṣo ti Jakọbu.”
Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli àti ìgbọ́ràn ìránṣẹ́
50 Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá rẹ wà
èyí tí mo fi lé e lọ?
Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mi
ni mo tà ọ́ fún?
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́;
nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.
2 Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan?
Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn?
Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́?
Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí?
Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi Òkun,
Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀;
àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omi
wọ́n sì kú fún òǹgbẹ.
3 Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀
mo sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”
4 Olúwa Olódùmarè ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,
láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.
O jí mi láràárọ̀,
o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.
5 Olúwa Olódùmarè ti ṣí mi ní etí,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;
Èmi kò sì padà sẹ́yìn.
6 Mo ṣí ẹ̀yìn mi sílẹ̀ fún àwọn tí ó ń nà mí,
àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irùngbọ̀n mi;
Èmi kò fi ojú mi pamọ́
kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́yà àti ìyọṣùtì sí.
7 Nítorí Olúwa Olódùmarè ràn mí lọ́wọ́;
A kì yóò dójútì mí.
Nítorí náà ni mo ṣe gbé ojú mi ró bí òkúta akọ
èmi sì mọ pé, ojú kò ní tì mí.
8 Ẹni tí ó dá mi láre wà nítòsí.
Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀sùn kàn mí?
Jẹ́ kí a kojú ara wa!
Ta ni olùfisùn mi?
Jẹ́ kí ó kò mí lójú!
9 Olúwa Olódùmarè ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.
Ta ni ẹni náà tí yóò dá mi lẹ́bi?
Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;
kòkòrò ni yóò sì jẹ wọn run.
10 Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwa
tí ó sì ń gbọ́rọ̀ sí ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?
Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùn
tí kò ní ìmọ́lẹ̀,
kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa
kí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tanná
tí ẹ sì ń fi pèsè iná ìléwọ́ fún ara yín,
ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín,
àti nínú ẹta iná tí ẹ ti dá.
Èyí ni yóò jẹ́ tiyín láti ọwọ́ mi wá:
Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìrora.
Ìgbàlà ayérayé fún Sioni
51 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin tí ó ń lépa òdodo
àti ẹ̀yin tí ń wá Olúwa:
Wo àpáta, nínú èyí tí a ti gé yín jáde
àti ihò òkúta níbi tí a ti gbẹ́ yín jáde;
2 ẹ wo Abrahamu baba yín,
àti Sara, ẹni tó bí i yín.
Nígbà tí mo pè é, òun nìkan ni,
Èmi sì bùkún un, mo sì ṣọ́ ọ di ọ̀pọ̀lọpọ̀.
3 Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú
yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀;
Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni,
àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa.
Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀,
ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.
4 “Tẹ́tí sí mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;
gbọ́ tèmi, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè mi:
Òfin yóò ti ọ̀dọ̀ mi jáde wá;
ìdájọ́ mi yóò di ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè.
5 Òdodo mi ń bọ̀ wá kíkankíkan,
ìgbàlà mi ń bọ̀ lójú ọ̀nà,
àti apá mi yóò sì mú ìdájọ́ wá
sí àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwọn erékùṣù yóò wò mí
wọn yóò sì dúró ní ìrètí fún apá mi.
6 (G)Gbé ojú rẹ sókè sí àwọn ọ̀run,
wo ilẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀;
Àwọn ọ̀run yóò pòórá bí èéfín,
ilẹ̀ yóò sì gbó bí ẹ̀wù
àwọn olùgbé inú rẹ̀ yóò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn eṣinṣin.
Ṣùgbọ́n ìgbàlà mi yóò wà títí láé,
òdodo mi kì yóò yẹ̀ láé.
7 “Ẹ gbọ́ mi, ẹ̀yin tí ó mọ ohun òtítọ́,
ẹ̀yin ènìyàn tí ó ní òfin mi ní àyà yín:
Ẹ má ṣe bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn ènìyàn
tàbí kí ẹ̀rù èébú wọn já a yín láyà.
8 Nítorí kòkòrò yóò mú wọn lá bí aṣọ;
Ìdin yóò sì mú wọn jẹ bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
Ṣùgbọ́n òdodo mi yóò wà títí ayérayé,
àti ìgbàlà mi láti ìrandíran.”
9 Dìde, dìde! Kí o sì wọ ara rẹ ní agbára
Ìwọ apá Olúwa;
dìde gẹ́gẹ́ bí i ti ọjọ́ ìgbà n nì,
àti gẹ́gẹ́ bí i ti ìran àtijọ́.
Ìwọ kọ́ lo ké Rahabu sí wẹ́wẹ́
tí o sì fa ẹ̀mí búburú ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ?
10 Ìwọ kọ́ ni ó gbẹ omi Òkun bí
àti àwọn omi inú ọ̀gbun,
Tí o sì ṣe ọ̀nà nínú ìsàlẹ̀ Òkun
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹni ìràpadà yóò fi le là á kọjá?
11 Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá.
Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ;
ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn.
Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn
ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.
12 “Èmi, àní Èmi, èmi ni ẹni tí ó tù ọ́ nínú.
Ta ni ọ́ tí o fi ń bẹ̀rù ènìyàn ẹlẹ́ran ara,
àti ọmọ ènìyàn, tí ó jẹ́ koríko lásán,
13 tí ìwọ sì gbàgbé Olúwa ẹlẹ́dàá rẹ,
ẹni tí ó ta àwọn ọ̀run
tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,
tí ẹ sì ń gbé nínú ìpayà lójoojúmọ́
nítorí ìbínú àwọn aninilára,
tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ìpanirun?
Nítorí ibo ni ìbínú àwọn aninilára gbé wà?
14 Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí ń ṣojo la ó dá sílẹ̀ ní àìpẹ́ jọjọ
wọn kò ní kú sínú túbú wọn,
bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ṣe aláìní àkàrà.
15 Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
tí ó ń ru Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí
ìgbì rẹ̀ fi ń pariwo
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
16 Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ
mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́
Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀,
ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,
àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé,
‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”
Ago ìbínú Olúwa
17 Jí, jí!
Gbéra nílẹ̀ ìwọ Jerusalẹmu,
ìwọ tí o ti mu láti ọwọ́ Olúwa
ago ìbínú rẹ̀,
ìwọ tí o ti fà á mu dé gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀
tí ó n mú kí ènìyàn ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n.
18 Nínú gbogbo ọmọ tí ó bí
kò sí ọ̀kankan tí ó lè tọ́ ọ ṣọ́nà
nínú gbogbo ọmọ tí ó tọ́
kò sí èyí tí ó le fà á lọ́wọ́.
19 Àjálù ìlọ́po ìlọ́po yìí ti dé bá ọ—
ta ni yóò tù ọ́ nínú?
Ìparun àti ìdahoro, ìyàn àti idà
ta ni yó pẹ̀tù sí ọ lọ́kàn?
20 Àwọn ọmọkùnrin rẹ ti dákú;
wọ́n sùn sí oríta gbogbo òpópónà,
gẹ́gẹ́ bí etu tí a dé mọ́nú àwọ̀n.
Ìbínú Olúwa ti kún inú wọn fọ́fọ́
àti ìbáwí Ọlọ́run yín.
21 Nítorí náà ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́,
tí ọtí ń pa, ṣùgbọ́n kì í ṣe fún wáìnì
22 Ohun tí Olúwa Olódùmarè yín wí nìyìí,
Ọlọ́run rẹ, ẹni tí ó ń pa ènìyàn rẹ̀ mọ́,
“Kíyèsi i, mo ti mú un kúrò ní ọwọ́ rẹ
ago tí ó mú ọ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n;
láti inú ago náà, ẹ̀kún ìbínú mi,
ni ìwọ kì yóò mu mọ́.
23 Èmi yóò fi lé àwọn apọ́nilójú rẹ lọ́wọ́,
àwọn tí ó wí fún ọ pé,
‘Dọ̀bálẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí a ó fi máa rìn lórí rẹ.’
Ìwọ náà ṣe ẹ̀yìn rẹ gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀
gẹ́gẹ́ bí òpópónà láti máa rìn lórí i rẹ̀.”
52 (H)Jí, jí, Ìwọ Sioni,
wọ ara rẹ ní agbára.
Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀,
ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì.
Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́
kì yóò wọ inú rẹ mọ́.
2 Gbọn eruku rẹ kúrò;
dìde sókè, kí o sì gúnwà, Ìwọ Jerusalẹmu.
Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò,
ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.
3 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;
“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,
láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”
4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí.
“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi sọ̀kalẹ̀
lọ sí Ejibiti láti gbé;
láìpẹ́ ni Asiria pọ́n wọn lójú.
5 (I)“Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.
“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,
àwọn tí ó sì ń jẹ ọba lórí wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”
ni Olúwa wí.
“Àti ní ọjọọjọ́
orúkọ mi ni asọ̀rọ̀-òdì sí nígbà gbogbo.
6 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;
nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀
pé Èmi ni ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”
7 (J)Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè
ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìhìnrere ayọ̀ wá,
tí wọ́n kéde àlàáfíà,
tí ó mú ìhìnrere wá,
tí ó kéde ìgbàlà,
tí ó sọ fún Sioni pé,
“Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”
8 Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè
wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.
Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni,
wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.
9 Ẹ bú sí orin ayọ̀ papọ̀,
ẹ̀yin ahoro Jerusalẹmu,
nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú,
ó sì ti ra Jerusalẹmu padà.
10 (K)Olúwa yóò ṣí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀
ní ojú gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò rí
ìgbàlà Ọlọ́run wa.
11 (L)Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìn-ín-yìí!
Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!
Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.
12 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúrò
tàbí kí ẹ sáré lọ;
nítorí Olúwa ni yóò síwájú yín lọ,
Ọlọ́run Israẹli ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.
Ìpọ́njú àti ògo ìránṣẹ́ náà
13 Kíyèsi i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọ́gbọ́n;
òun ni a ó gbé sókè tí a ó sì gbéga
a ó sì gbé e lékè gidigidi.
14 Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bu ọlá fún un—
ìwò ojú rẹ ni a ti bàjẹ́ kọjá ti ẹnikẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́.
15 (M)Bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀-èdè ká,
àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítorí rẹ̀.
Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,
àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.
53 (N)Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́
àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?
2 Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn,
àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.
Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀
tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.
3 A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.
Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún
a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.
4 (O)Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ
ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,
síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,
tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.
5 (P)Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa
a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;
ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,
àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.
6 Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ,
ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀;
Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀
gbogbo àìṣedéédéé wa.
7 (Q)A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú,
síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;
a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,
àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.
8 Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,
ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?
Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.
9 (R)A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,
àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,
tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.
10 Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára
àti láti mú kí ó jìyà,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀
fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,
Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé
rẹ̀ yóò pẹ́ títí,
àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.
11 Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,
òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;
nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,
Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.
12 (S)Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá
òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,
nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú,
tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.
Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.