Chronological
Jotamu ọba Juda
27 Jotamu sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì di ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. 2 Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Ussiah ti ṣe, ṣùgbọ́n kìkì wí pé kò wọ ilé Olúwa. Àwọn ènìyàn síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi wọn. 3 Jotamu sì kọ́ ẹnu-ọ̀nà gíga ilé Olúwa ó sì ṣe iṣẹ́ lórí odi ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ofeli. 4 Ó sì kọ́ àwọn ìlú ní Juda òkè àti nínú igbó àti ilé ìṣọ́, ó mọ ilé odi.
5 Jotamu sì ṣẹ́ ogun lórí ọba àwọn ará Ammoni ó sì borí wọn. Ní ọdún náà àwọn ará Ammoni wọ́n sì san fún ọgọ́rùn-ún tálẹ́ǹtì fàdákà àti ẹgbàárùn-ún òṣùwọ̀n alikama àti ẹgbàárùn-ún barle. Àwọn ará Ammoni gbé e wá ní iye kan náà àti pẹ̀lú ní ọdún kejì àti ní ọdún kẹta.
6 Jotamu sì di alágbára nítorí ó rìn ní ọ̀nà tó tọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
7 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Jotamu, pẹ̀lú gbogbo àwọn ogun rẹ̀ pẹ̀lú ohun mìíràn tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé àwọn ọba Israẹli àti ti Juda. 8 Ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó jẹ ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. 9 (A)Jotamu sì sùn pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀ a sì sin ín ní ìlú Dafidi, Ahasi ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.
A bí ọmọ kan fún wa
9 (A)Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.
2 Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;
Lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú,
ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.
3 Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ
gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè,
gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀
nígbà tí à ń pín ìkógun.
4 Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
ìwọ ti fọ́ ọ túútúú
àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,
ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,
ọ̀gọ aninilára wọn.
5 Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun
àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,
ni yóò wà fún ìjóná,
àti ohun èlò iná dídá.
6 Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
a fi ọmọkùnrin kan fún wa,
ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.
A ó sì máa pè é ní: Ìyanu
Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára
Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.
7 Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi
àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,
nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,
pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo
láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ni yóò mú èyí ṣẹ.
Ìbínú Olúwa Sí Israẹli
8 Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
Yóò sì wá sórí Israẹli.
9 Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria—
tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga
àti gààrù àyà pé.
10 Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán,
a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀
ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
11 Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè.
12 Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run.
Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
Ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.
13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
sí ẹni náà tí ó lù wọ́n
bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
14 Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
kúrò ní Israẹli,
àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,
15 Àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
16 Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà
Àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.
17 Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,
nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,
ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.
Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
18 Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run,
yóò sì rán nínú pàǹtí igbó,
tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.
19 Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ
àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,
ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
20 Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,
ní apá òsì, wọn yóò jẹ
ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn.
Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.
21 Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase
wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda.
Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò
Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.
10 Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo
2 láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn
àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò
níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,
Wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn.
Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.
3 Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò
nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá?
Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?
Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?
4 Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn
tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa.
Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,
ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.
Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Asiria
5 (B)“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,
ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!
6 Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run
Mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú
láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun
láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
7 Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,
èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;
èrò rẹ̀ ni láti parun,
láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.
8 ‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
9 ‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?
Hamati kò ha dàbí i Arpadi,
àti Samaria bí i Damasku?
10 Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,
ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.
11 Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”
Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?
12 Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀. 13 Nítorí ó sọ pé:
“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí
àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.
Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
Mo sì ti kó ìṣúra wọn.
Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
14 Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè
kò sí èyí tí ó fi apá lu apá,
tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”
15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,
tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó?
Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,
tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
16 Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí
àwọn akíkanjú jagunjagun,
lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ
gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,
ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run
àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
18 Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
19 Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
yóò kéré níye,
tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
Àwọn ìyókù Israẹli
20 Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
Àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,
kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà
tí ó lù wọ́n bolẹ̀,
ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
Ẹni Mímọ́ Israẹli.
21 Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu
yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli
dàbí yanrìn ní Òkun,
ẹni díẹ̀ ni yóò padà.
A ti pàṣẹ ìparun
àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.
23 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí
gbogbo ilẹ̀ náà.
24 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,
“Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,
Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,
tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,
tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí
Ejibiti ti ṣe.
25 Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n,
fún ìparun wọn.”
26 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.
Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani
ní òkè Orebu,
yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi
gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.
27 Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín,
àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín
a ó fọ́ àjàgà náà,
nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.
28 Wọ́n wọ Aiati,
Wọ́n gba Migroni kọjá
Wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mikmasi.
29 Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,
“Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.”
Rama mì tìtì
Gibeah ti Saulu sálọ.
30 Gbé ohùn rẹ sókè, ìwọ ọmọbìnrin Galimu!
Dẹ etí sílẹ̀, ìwọ Laiṣa!
Ìwọ òtòṣì Anatoti!
31 Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ
Àwọn ènìyàn Gebimu ti fi ara pamọ́.
32 Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu
wọn yóò kan sáárá,
ní òkè ọmọbìnrin Sioni
ní òkè Jerusalẹmu.
33 Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára.
Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀
àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.
34 Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,
Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.
Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese
11 (C)Èèkàn kan yóò sọ láti ibi
kùkùté Jese,
láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan
yóò ti so èso.
2 (D)Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e
ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye
ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára
ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa
3 Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.
Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,
tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,
4 Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,
pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu
fún àwọn aláìní ayé.
Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,
pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
5 (E)Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀
àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.
6 (F)Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
7 Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
8 Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
9 Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.
10 (G)Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti Òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.
12 Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,
yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,
láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
13 Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,
àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,
Efraimu kò ní jowú Juda,
tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.
14 Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini
sí apá ìwọ̀-oòrùn,
wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn
ènìyàn apá ìlà-oòrùn.
Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,
àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.
15 Olúwa yóò sọ di gbígbé
àyasí Òkun Ejibiti,
pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,
kọjá lórí odò Eufurate.
Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje
tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn
yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.
16 Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù
tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,
gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli
nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.
Orin ìyìn
12 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé:
“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
ìwọ sì ti tù mí nínú.
2 Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
òun ti di ìgbàlà mi.”
3 Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
láti inú kànga ìgbàlà.
4 Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:
“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
kí o sì kéde pé a ti gbé
orúkọ rẹ̀ ga.
5 Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
6 Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
ti Israẹli láàrín yín.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.