Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 1-4

Ìran sí Juda àti Jerusalẹmu èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí ní àsìkò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah àwọn ọba Juda.

Ọlọ̀tẹ̀ orílẹ̀-èdè kan

Gbọ́ ẹ̀yin ọ̀run! Fi etí sílẹ̀, ìwọ ayé!
    Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀:
“Mo tọ́ àwọn ọmọ dàgbà,
    Ṣùgbọ́n wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
Màlúù mọ olówó rẹ̀,
    kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì mọ ibùjẹ olówó rẹ̀,
ṣùgbọ́n Israẹli kò mọ̀,
    òye kò yé àwọn ènìyàn mi.”

Á à! Orílẹ̀-èdè ẹlẹ́ṣẹ̀,
    àwọn ènìyàn tí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ń pa lẹ́rù,
Ìran àwọn aṣebi,
    àwọn ọmọ tó ti di aṣèbàjẹ́!
Wọn ti kọ Olúwa sílẹ̀
    wọn ti gan Ẹni Mímọ́ Israẹli,
wọn sì ti kẹ̀yìn sí i.

Èéṣe tí a ó fi tún lù yín mọ́?
    Èéṣe tí ẹ ò dẹ́kun ọ̀tẹ̀ ṣíṣe?
Gbogbo orí yín jẹ́ kìkì ọgbẹ́,
    gbogbo ọkàn yín sì ti pòruurù.
Láti àtẹ́lẹsẹ̀ yín dé àtàrí yín
    kò sí àlàáfíà rárá,
àyàfi ọgbẹ́ òun ìfarapa
    àti ojú egbò,
    tí a kò nù kúrò tàbí kí á dì tàbí kí a kùn ún ní òróró.

Orílẹ̀-èdè yín dahoro,
    a dáná sun àwọn ìlú yín,
oko yín ni àwọn àjèjì ti jẹ run
    lójú ara yín náà,
ni gbogbo rẹ̀ ṣòfò bí èyí tí
    àwọn àjèjì borí rẹ̀.
Ọmọbìnrin Sioni ni a fi sílẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí àtíbàbà nínú ọgbà àjàrà,
gẹ́gẹ́ bí abà nínú oko ẹ̀gúnsí,
    àti bí ìlú tí a dó tì.
Àyàfi bí Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    bá ṣẹ́ díẹ̀ kù fún wà,
a ò bá ti rí bí Sodomu,
    a ò bá sì ti dàbí Gomorra.

10 Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,
    ẹ̀yin aláṣẹ Sodomu,
tẹ́tí sí òfin Ọlọ́run wa,
    ẹ̀yin ènìyàn Gomorra!
11 “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín
    kín ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ yín jásí fún mi?” ni Olúwa wí.
“Mo ti ní ànító àti àníṣẹ́kù ẹbọ sísun
    ti àgbò àti ọ̀rá ẹran àbọ́pa,
Èmi kò ní inú dídùn
    nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù, ti àgùntàn
àti ti òbúkọ.
12 Nígbà tí ẹ wá farahàn níwájú mi,
    ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín,
    Gìrì gìrì ẹsẹ̀ nínú àgbàlá mi?
13 Ẹ má mú ọrẹ asán wá mọ́!
    Ìríra ni tùràrí yín jásí fún mi,
oṣù tuntun àti ọjọ́ ìsinmi àti àwọn àpéjọ,
    Èmi kò lè faradà á, ẹ̀ṣẹ̀ ni àpéjọ yín wọ̀nyí.
14 Ayẹyẹ oṣù tuntun yín àti àjọ̀dún tí a yàn,
    ni ọkàn mi kórìíra.
Wọ́n ti di àjàgà sí mi ní ọrùn,
    Ó sú mi láti fi ara dà wọ́n.
15 Nígbà tí ẹ bá tẹ́ ọwọ́ yín sókè ni àdúrà,
    Èmi yóò fi ojú mi pamọ́ fún un yín,
kódà bí ẹ bá gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdúrà,
    Èmi kò ni tẹ́tí sí i.

“Ọwọ́ yín kún fún ẹ̀jẹ̀.

16 “Wẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí ara yín mọ́.
    Ẹ mú ìwà ibi yín kúrò níwájú mi!
    Dáwọ́ àìṣedéédéé dúró,
17 kọ́ láti ṣe rere!
    Wá ìdájọ́ òtítọ́,
tu àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.
    Ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,
    gbà ẹjọ́ opó rò.

18 “Ẹ wá ní ìsinsin yìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàṣàrò,”
    ni Olúwa wí.
“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,
    wọn ó sì funfun bí i yìnyín,
bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,
    wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n òwú.
19 Tí ẹ̀yin bá fẹ́, tí ẹ sì gbọ́rọ̀,
    ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.
20 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,
    idà ni a ó fi pa yín run.”
Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.

21 Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!
    Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,
òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,
    ṣùgbọ́n báyìí àwọn apànìyàn!
22 Fàdákà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,
    ààyò wáìnì rẹ la ti bu omi là.
23 Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,
    akẹgbẹ́ àwọn olè,
gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀
    wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.
Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,
    ẹjọ́ opó kì í sì í dé iwájú wọn.

24 Nítorí náà ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    alágbára kan ṣoṣo tí Israẹli sọ wí pé:
“Á à! Èmi yóò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá mi
    n ó sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi.
25 Èmi yóò pa ọwọ́ mi dà sí ọ,
    èmi ó sì ku ìpẹ́pẹ́ rẹ dànù,
    n ó sì mú gbogbo ìdọ̀tí rẹ kúrò.
26 Èmi yóò mú àwọn adájọ́ rẹ bọ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí i ti àtijọ́,
    àti àwọn olùdámọ̀ràn rẹ̀ bí i ti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
    Lẹ́yìn náà ni a ó pè ọ ní ìlú òdodo, ìlú òtítọ́.”

27 A ó fi ìdájọ́ òtítọ́ ra Sioni padà,
    àti àwọn tí ó ronúpìwàdà pẹ̀lú òdodo.
28 Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ̀tẹ̀ àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó parun.
    Àwọn tí ó bá sì kọ Olúwa sílẹ̀ ni yóò ṣègbé.

29 “Ojú yóò tì yín nítorí igi óákù mímọ́
    èyí tí ẹ ní inú dídùn sí,
a ó kàn yín lábùkù nítorí àwọn ọgbà yìí
    tí ẹ ti yàn fúnrayín.
30 Ẹ ó sì dàbí igi óákù tí ewé rẹ̀ ti rọ,
    bí ọgbà tí kò ní omi.
31 Alágbára ọkùnrin náà yóò sì dàbí ohun ìdáná,
    iṣẹ́ rẹ̀ bí ẹ̀ṣẹ́-iná,
àwọn méjèèjì ni yóò jóná papọ̀,
    láìsí ẹni tí yóò lè pa iná yìí.”

Òkè Olúwa

Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu:

(A)Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́

òkè tẹmpili Olúwa ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè,
a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ,
    gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé,

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá Olúwa,
    àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu.
Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀,
    kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.”
Òfin yóò jáde láti Sioni wá,
    àti ọ̀rọ̀ Olúwa láti Jerusalẹmu.
Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
    yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.
Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀,
    wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.
Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́,
    bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.

Wá, ẹ̀yìn ará ilé e Jakọbu,
    ẹ jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Olúwa.

Ọjọ́ Olúwa

Ìwọ ti kọ àwọn ènìyàn rẹ sílẹ̀,
    ìwọ ilé Jakọbu.
Wọ́n kún fún ìgbàgbọ́ tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí ó ti ìlà-oòrùn wá,
    wọ́n ń wo iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn Filistini,
    wọ́n ń pa ọwọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn abọ̀rìṣà.
Ilẹ̀ wọn kún fún fàdákà àti wúrà,
    ìṣúra wọn kò sì ní òpin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ẹṣin,
    kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lópin.
Ilẹ̀ ẹ wọn kún fún ère,
    wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,
    èyí tí ìka ọwọ́ àwọn tìkára wọn ti ṣe.
Nítorí náà ni a ó ṣe rẹ ènìyàn sílẹ̀
    ìran ọmọ ènìyàn ni yóò sì di onírẹ̀lẹ̀,
    má ṣe dáríjì wọ́n.

10 Wọ inú àpáta lọ,
    fi ara pamọ́ nínú erùpẹ̀
kúrò nínú ìpayà Olúwa,
    àti ògo ọláńlá rẹ̀!
11 Ojú agbéraga ènìyàn ni a ó rẹ̀ sílẹ̀
    a ó sì tẹrí ìgbéraga ènìyàn ba,
    Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà.

12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan ní ìpamọ́
    fún gbogbo agbéraga àti ọlọ́kàn gíga
    nítorí gbogbo àwọn tí a gbéga (ni a ó rẹ̀ sílẹ̀),
13 nítorí gbogbo igi kedari Lebanoni, tó ga tó rìpó
    àti gbogbo óákù Baṣani,
14 nítorí gbogbo òkè gíga ńláńlá
    àti àwọn òkè kéékèèkéé,
15 fún ilé ìṣọ́ gíga gíga
    àti àwọn odi ìdáàbòbò,
16 fún gbogbo ọkọ̀ àwọn oníṣòwò
    àwọn ọkọ̀ tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
17 Ìgbéraga ènìyàn ni a ó tẹ̀ lórí ba
    a ó sì rẹ ìgbéraga ènìyàn sílẹ̀,
    Olúwa nìkan ṣoṣo ni a ó gbéga ní ọjọ́ náà,
18 gbogbo ère òrìṣà yóò pòórá.

19 Àwọn ènìyàn yóò sálọ sínú ihò àpáta
    àti sínú ihò ilẹ̀
kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa
    àti ògo ọláńlá rẹ̀,
    nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
20 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ènìyàn yóò máa sọ
    àwọn ère fàdákà àti ère wúrà
tí wọ́n ti yá fún bíbọ
    sí èkúté àti àwọn àdán,
21 Wọn yóò sálọ sínú ihò ìsàlẹ̀ àpáta
    àti sínú ihò pàlàpálá àpáta
kúrò lọ́wọ́ ìpayà Olúwa
    àti ògo ọláńlá rẹ̀,
    nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.

22 Dẹ́kun à ń gba ènìyàn gbọ́,
    èémí ẹni tó wà ní ihò imú rẹ̀.
Nítorí nínú kín ni a lè kà á sí?

Ìdájọ́ lórí i Jerusalẹmu àti Juda

Kíyèsi i, Olúwa,
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
fẹ́ mú ìpèsè àti ìrànlọ́wọ́ kúrò ní Jerusalẹmu àti Juda
    gbogbo ìpèsè oúnjẹ àti ìpèsè omi.
Àwọn akíkanjú àti jagunjagun,
    adájọ́ àti wòlíì,
    aláfọ̀ṣẹ àti alàgbà,
balógun àádọ́ta àti àwọn ènìyàn, onípò gíga
    olùdámọ̀ràn, oníṣọ̀nà tí ó dáńtọ́
    àti ògbójú oníṣègùn.

“Èmi ó sọ àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin di aláṣẹ wọn,
    ọ̀dọ́mọdé lásán làsàn ni yóò sì
    máa jẹ ọba lórí i wọn.”

Àwọn ènìyàn yóò sì máa pọ́n
    ọmọnìkejì wọn lójú
ẹnìkan sí ẹnìkejì rẹ̀, aládùúgbò
    sí aládùúgbò rẹ̀.
Àwọn ọ̀dọ́ yóò gbógun ti àwọn àgbàgbà,
    àwọn mẹ̀kúnnù yóò dìde sí ọlọ́lá.

Ọkùnrin kan yóò di ọ̀kan nínú àwọn
    arákùnrin rẹ̀ mú,
nínú ilé baba rẹ̀, yóò sì wí pé,
    “Ìwọ́ ní aṣọ, ìwọ máa ṣe olórí wa,
    sì mójútó àwọn ahoro wọ̀nyí!”
Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ náà ni yóò figbe bọnu pé,
    “Èmi kò ní àtúnṣe kan.
Èmi kò ní oúnjẹ, bẹ́ẹ̀ ni n ó ní aṣọ nílé,
    ẹ má fi mí ṣe olórí àwọn ènìyàn náà.”

Jerusalẹmu ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n
    Juda ń ṣubú lọ,
ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn lòdì sí Olúwa,
    láti mú ojú ògo rẹ̀ bínú.
Ìwò ojú wọn ń jẹ́rìí lòdì sí wọn,
    wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bí i Sodomu;
wọn ò fi pamọ́!
    Ègbé ni fún wọn!
    Wọ́n ti mú ìparun wá sórí ara wọn.

10 Ẹ sọ fún olódodo pé yóò dára fún wọn,
    nítorí ní àjẹgbádùn ni wọn yóò jẹ èso iṣẹ́ ẹ wọn.
11 Ègbé ni fún ènìyàn búburú! Ìparun wà lórí i wọn
    A ó sì san èrè iṣẹ́ tí ọwọ́ wọn ti ṣe fún wọn.

12 Àwọn ọ̀dọ́mọdé ni o ń pọ́n àwọn ènìyàn mi lójú
    àwọn obìnrin ń jẹ ọba lé wọn lórí.
Háà! Ènìyàn mi àwọn afinimọ̀nà yín ti ṣì yín lọ́nà,
    wọn sì mú yín kúrò ní ipa ọ̀nà yín.

13 Olúwa bọ sí ipò rẹ̀ ní ìtẹ́ ìdájọ́
    Ó dìde láti dá àwọn ènìyàn lẹ́jọ́.
14 Olúwa dojú ẹjọ́ kọ
    àwọn àgbàgbà àti àwọn olórí àwọn ènìyàn rẹ̀.
“Ẹ̀yin ni ẹ ti run ọgbà àjàrà mi,
    ogún àwọn tálákà ń bẹ̀ nínú ilé yín.
15 Kín ni èrò yín láti máa run àwọn ènìyàn mi túútúú
    tí ẹ sì fojú àwọn tálákà ni gbolẹ̀?”
    ni Olúwa wí, Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

16 Olúwa wí pé,
    “Àwọn obìnrin Sioni jẹ́ agbéraga,
wọn ń rìn lọ pẹ̀lú ọrùn tí ó nà tàntàn,
    tí wọn ń fojú pe ọkùnrin,
tí wọn ń sọ̀dí bí wọ́n ti ń yan lọ
    pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ tí ń mì wọnjanwọnjan lọ́rùn ẹsẹ̀ wọn.
17 Nítorí náà Olúwa yóò mú egbò wá sórí àwọn obìnrin Sioni,
    Olúwa yóò sì pá wọn ní agbárí.”

18 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò já ọ̀ṣọ́ wọn gbà kúrò ti ọwọ́ àti gèlè àti ẹ̀gbà ọrùn tí ó dàbí òṣùpá 19 gbogbo yẹtí, ẹ̀gbà ọwọ́ àti ìbòjú, 20 gbogbo gèlè, ẹ̀gbà ọrùn, ẹsẹ̀ àti àyà, àwọn ìgò tùràrí àti òògùn, 21 òrùka ọwọ́ àti ti imú, 22 àwọn àtàtà aṣọ, àwọ̀lékè, agbádá àti àpamọ́wọ́, 23 Dígí wọn, aṣọ funfun nigínnigín ìbòrí àti ìbòjú.

24 Dípò òórùn dídùn, òórùn búburú ni yóò wá,
    okùn ni yóò wà dípò àmùrè,
orí pípá ni yóò dípò irun ti a ṣe ní ọ̀ṣọ́
    aṣọ ọ̀fọ̀ ni yóò dípò aṣọ ẹ̀yẹ ìjóná dípò ẹwà.
25 Àwọn ọkùnrin rẹ yóò ti ipa idà ṣubú,
    àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lójú ogun.
26 Àwọn bodè Sioni yóò sọkún kíkorò, wọn ó ṣọ̀fọ̀,
    nítorí ó dahoro, yóò jókòó ní orí ilẹ̀.
Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje
    yóò dì mọ́ ọkùnrin kan
yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa
    a ó sì pèsè aṣọ ara wa;
sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá.
    Mú ẹ̀gàn wa kúrò!”

Ẹ̀ka Olúwa náà

(B)Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní Israẹli. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Sioni, àwọn tí o kù ní Jerusalẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní Jerusalẹmu. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin Sioni kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná. Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sórí òkè Sioni àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà. Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.