Chronological
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Babeli
13 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli
èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí:
2 Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu,
kígbe sí wọn, pè wọ́n
láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.
3 Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,
mo ti pe àwọn jagunjagun mi
láti gbé ìbínú mi jáde
àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.
4 Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,
gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,
gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè!
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ
àwọn jagunjagun fún ogun.
5 Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá
Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,
láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run.
6 Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí,
yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
7 Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,
ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.
8 Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,
ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,
wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.
Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà
ojú wọn á sì gbinájẹ.
9 Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀
ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú
àti ìrunú gbígbóná—
láti sọ ilẹ̀ náà dahoro,
àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
10 (B)Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn
kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn
àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
11 Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,
àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga
èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
12 Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn
ju ojúlówóo wúrà lọ,
yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.
13 Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;
ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀
láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.
14 Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
15 Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,
gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
16 Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,
gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó
àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.
17 Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn,
àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà
tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
18 Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;
wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé
tàbí kí wọn ṣíjú àánú wo àwọn ọmọdé.
19 Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba
ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli
ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀
gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.
20 A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́
tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;
Ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́,
olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
21 (C)Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀,
àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,
níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé
níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.
22 Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,
àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.
14 Olúwa yóò fi àánú hàn fún Jakọbu,
yóò tún Israẹli yàn lẹ́ẹ̀kan sí i
yóò sì fi ìdí wọn kalẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn tìkára wọn.
Àwọn àjèjì yóò darapọ̀ mọ́ wọn,
wọn yóò sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé e Jakọbu.
2 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà wọ́n
wọn yóò sì mú wọn wá sí ààyè e wọn.
Ilé Israẹli yóò gba àwọn orílẹ̀-èdè
gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin
ní ilẹ̀ Olúwa.
Wọn yóò kó àwọn akónilẹ́rú wọn ní ìgbèkùn
wọn yóò sì jẹ ọba lórí àwọn amúnisìn wọn.
3 Ní ọjọ́ tí Olúwa yóò fi ìtura fún un yín kúrò nínú ìpọ́njú àti ìyà àti ìdè ìkà, 4 ẹ ó sì fi ọ̀rọ̀ àbùkù yìí kan ọba Babeli pé:
Báwo ni amúnisìn ṣe wá sí òpin!
Báwo ni ìbínú rẹ̀ ṣe parí!
5 Olúwa ti dá ọ̀pá ìkà náà,
ọ̀pá àwọn aláṣẹ,
6 èyí tí ó ti lu àwọn ènìyàn bolẹ̀
pẹ̀lú ti kò dáwọ́ dúró,
nínú ìrunú ni ó ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè
pẹ̀lú ìgbónára tí kò lópin.
7 Gbogbo ilẹ̀ ni ó wà ní ìsinmi àti àlàáfíà,
wọ́n bú sí orin.
8 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn igi junifa àti àwọn
igi kedari ti Lebanoni
ń yọ̀ lórí rẹ wí pé,
“Níwọ́n bí a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ báyìí,
kò sí agégi tí yóò wá láti gé wa lulẹ̀.”
9 Ibojì tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni a ru sókè
láti pàdé rẹ ní ìpadàbọ̀ rẹ̀
ó ru ẹ̀mí àwọn tí ó ti lọ sókè láti wá kí ọ
gbogbo àwọn tí ó jẹ́ olórí ní ayé
ó mú kí wọn dìde lórí ìtẹ́ wọn
gbogbo àwọn tí ó jẹ ọba lórí àwọn orílẹ̀-èdè.
10 Gbogbo wọn yóò dáhùn,
wọn yóò wí fún ọ wí pé,
“Ìwọ pẹ̀lú ti di aláìlera, gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú
ìwọ náà ti dàbí wa.”
11 Gbogbo rẹ̀ ni ó di ìrẹ̀sílẹ̀ lọ sí ibojì,
pẹ̀lú ariwo àwọn dùùrù rẹ,
àwọn ìdin ni wọ́n fọ́nkálẹ̀ lábẹ́ rẹ
àwọn ekòló sì ti bò ọ́ mọ́lẹ̀.
12 Báwo ni ìwọ ṣe ṣubú lulẹ̀ láti ọ̀run wá,
ìwọ ìràwọ̀ òwúrọ̀, ọmọ òwúrọ̀ náà!
A ti sọ ọ́ sílẹ̀ sínú ayé
Ìwọ tí o ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba rí!
13 Ìwọ sọ nínú ọkàn rẹ pé,
“Èmi yóò gòkè lọ sí ọ̀run;
Èmi yóò gbé ìtẹ́ mi sókè
ga ju àwọn ìràwọ̀ Ọlọ́run,
Èmi yóò gúnwà ní orí òkè àpéjọ
ní ṣóńṣó orí òkè mímọ́.
14 Èmi yóò gòkè lọ rékọjá àwọn àwọsánmọ̀;
Èmi yóò ṣe ara mi gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá-ògo.”
15 Ṣùgbọ́n a ti rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ wọ inú ibojì lọ
lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun.
16 Àwọn tí ó rí ọ yóò tẹjúmọ́ ọ,
wọ́n ronú nípa àtubọ̀tán rẹ:
“Ǹjẹ́ èyí ni ẹni tí ó mi ayé tìtì
tí ó sì jẹ́ kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
17 Ẹni tí ó sọ ayé di aginjù,
tí ó sì pa ìlú ńláńlá rẹ̀ run
tí kò dá àwọn òǹdè rẹ̀ sílẹ̀ láti padà sílé?”
18 Gbogbo àwọn ọba orílẹ̀-èdè ni a tẹ́ sílẹ̀
ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú ibojì tirẹ̀.
19 Ṣùgbọ́n a jù ọ́ síta kúrò nínú ibojì
gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka igi tí a kọ̀sílẹ̀,
àwọn tí a pa ni ó bò ọ́ mọ́lẹ̀,
àwọn tí idà ti gún,
àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú òkúta inú ọ̀gbun.
Gẹ́gẹ́ bí òkú ó di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ní abẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀,
20 A kò ní sin ọ́ pẹ̀lú wọn,
nítorí pé o ti ba ilẹ̀ rẹ jẹ́
o sì ti pa àwọn ènìyàn rẹ.
Ìran àwọn ìkà
ni a kì yóò dárúkọ wọn mọ́.
21 Tọ́jú ibìkan tí a ó ti pa àwọn ọmọkùnrin rẹ
nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn,
wọn kò gbọdọ̀ dìde láti jogún ilẹ̀
kí wọ́n sì bo orí ilẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlú u wọn.
22 “Èmi yóò dìde sókè sí wọn,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
“Èmi yóò ké orúkọ rẹ̀ kúrò ní Babeli àti àwọn tí ó sálà,
àwọn ọmọ àti ìran rẹ̀,”
ni Olúwa wí.
23 Èmi yóò yí i padà sí ibùgbé àwọn òwìwí
àti sí irà;
Èmi yóò fi ọwọ́ ìparun gbá a,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Asiria
24 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti búra,
“Gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣètò, bẹ́ẹ̀ ni yóò rí,
àti bí mo ti pinnu, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì dúró.
25 Èmi yóò run Asiria ní ilẹ̀ mi,
ní àwọn orí òkè mi ni èmi yóò ti rún un mọ́lẹ̀.
Àjàgà rẹ̀ ni a ó mú kúrò lọ́rùn àwọn ènìyàn mi,
ẹrù u rẹ̀ ni ó mú kúrò ní èjìká wọn.”
26 Èyí ni ètò tí a pinnu rẹ̀ fún gbogbo ayé,
èyí ni ọwọ́ tí a nà jáde káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè.
27 Nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pète,
ta ni yóò sì ká a lọ́wọ́ kò?
Ọwọ́ọ rẹ ti nà jáde, ta ni ó sì le è fà á padà?
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì àwọn Filistini
28 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yí wá ní ọdún tí ọba Ahasi kú:
29 (D)Má ṣe yọ̀, gbogbo ẹ̀yin Filistia,
pé ọ̀pá tí ó lù ọ́ ti dá;
láti ibi gbòǹgbò ejò náà ni paramọ́lẹ̀
yóò ti hù jáde,
èso rẹ̀ yóò sì jẹ́ oró ejò tí í jóni.
30 Ẹni tí ó kúṣẹ̀ẹ́ jù yóò ní pápá oko,
àwọn aláìní yóò sì dùbúlẹ̀ láìléwu.
Ṣùgbọ́n gbòǹgbò o rẹ̀ ni èmi ó fi ìyàn parun,
yóò sì ké àwọn ẹni rẹ tí ó sálà kúrò.
31 Hu, ìwọ ẹnu-ọ̀nà! Kígbe, Ìwọ ìlú!
Yọ́ kúrò, gbogbo ẹ̀yin Filistia!
Èéfín kurukuru kan ti àríwá wá,
kò sì ṣí amóríbọ́ kan nínú ẹgbẹ́ wọn.
32 Kí ni ìdáhùn tí a ó fún
agbẹnusọ orílẹ̀-èdè náà?
“Olúwa ti fi ìdí Sioni kalẹ̀,
àti nínú rẹ̀ ni àwọn ènìyàn rẹ̀ tí
a ti pọ́n ọn lójú yóò ti rí ààbò o wọn.”
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu
15 (E)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu:
A pa Ari run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
A pa Kiri run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
2 Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
Gbogbo orí ni a fá
gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
3 Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
Wọ́n pohùnréré
Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4 Heṣboni àti Eleale ké sóde,
ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.
5 Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
Ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn
6 Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
àwọn koríko sì ti gbẹ,
gbogbo ewéko ti tán
ewé tútù kankan kò sí mọ́.
7 Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní
tí wọ́n sì tò jọ
wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́
odò Poplari.
8 Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé
ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
9 Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.
16 Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn
ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,
láti Sela, kọjá ní aginjù,
lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.
2 Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ
tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu
ní àwọn ìwọdò Arnoni.
3 “Fún wa ní ìmọ̀ràn
ṣe ìpinnu fún wa.
Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru,
ní ọ̀sán gangan.
Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,
má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han
4 Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,
jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”
Aninilára yóò wá sí òpin,
ìparun yóò dáwọ́ dúró;
òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.
5 Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,
ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀
ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.
Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,
yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.
6 Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,
ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,
gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
7 Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,
wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.
Sọkún kí o sì banújẹ́
fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.
8 Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,
bákan náà ni àjàrà Sibma rí.
Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè
wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,
èyí tí ó ti fà dé Jaseri
ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.
Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,
ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.
9 Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,
fún àwọn àjàrà Sibma.
Ìwọ Heṣboni, Ìwọ Eleale,
mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!
Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ
àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.
10 Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò
nínú ọgbà-igi eléso rẹ;
kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí
kígbe nínú ọgbà àjàrà:
ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,
nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.
11 Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,
àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.
12 Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,
ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;
Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà
òfo ni ó jásí.
13 Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu. 14 Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé: “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ní ti Damasku
17 (F)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku:
“Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́
ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
2 Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀
fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,
láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
3 Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,
àti agbára ọba kúrò ní Damasku;
àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá
gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
4 “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá;
ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
5 Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn
irúgbìn tí ó dúró jọ
tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—
àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní Àfonífojì ti Refaimu.
6 Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi,
tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù
sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,
mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”
ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
7 Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn
wọn yóò sì ṣíjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
8 Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,
èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́
tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.
9 Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.
10 Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
11 Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
ẹ mú kí wọ́n rúdí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.
12 Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú
ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,
nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,
a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,
àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
14 Ní aginjù, ìpayà òjijì!
Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!
Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,
àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.