Chronological
Ègbé ni fún àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti
31 Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí
Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́,
tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin
tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn
àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn,
ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì,
tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.
2 Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá;
òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ.
Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà,
àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.
3 Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti
wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.
Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde,
ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀,
ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;
àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.
4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké
àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀
bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn
tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀,
ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn
akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá
láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀.
5 Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu,
Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀
Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”
6 Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
7 Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe.
8 “Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá;
idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n.
Wọn yóò sì sá níwájú idà náà
àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.
9 Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù;
àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù asia náà,”
ni Olúwa wí,
ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Sioni,
ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.
Ìjọba òdodo náà
32 Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo
àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso.
2 Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́
àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,
gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀,
àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.
3 Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́,
àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.
4 Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,
àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
5 A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́
tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.
6 Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,
ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:
òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run
ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;
ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo
àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ
ni ó mú omi kúrò.
7 Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́,
ó ń gba èrò búburú
láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.
8 Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá
àti nípa èrò rere ni yóò dúró.
Àwọn obìnrin Jerusalẹmu
9 Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi
ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,
ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,
ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!
10 Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan
ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;
ìkórè àjàrà kò ní múnádóko,
bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí.
11 Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn
bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!
Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,
ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.
12 Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà,
fún àwọn àjàrà eléso
13 àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi
ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n—
bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura
àti fún ìlú àríyá yìí.
14 Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀,
ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì;
ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé,
ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá
oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,
15 títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,
àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá
àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.
16 Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀
àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.
17 Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà;
àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.
18 Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní ibùgbé àlàáfíà,
ní ibùgbé ìdánilójú,
ní àwọn ibi ìsinmi tí ó parọ́rọ́.
19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹsẹ
àti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹsẹ pátápátá,
20 báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó,
nípa gbígbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo,
àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti
àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.
Ìpọ́njú àti ìrànlọ́wọ́
33 Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun,
ìwọ tí a kò tí ì parun!
Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀,
ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́!
Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run;
a ó pa ìwọ náà run,
nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani,
a ó da ìwọ náà.
2 Olúwa ṣàánú fún wa
àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ.
Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀
ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.
3 Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,
nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.
4 Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè
gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;
gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.
5 A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga;
Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.
6 Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ
ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;
ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.
7 Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré
ẹkún ní òpópónà;
àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.
8 Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì,
kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà
A ti ba àdéhùn jẹ́,
a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,
a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.
9 Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,
ojú ti Lebanoni ó sì sá
Ṣaroni sì dàbí aginjù,
àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.
10 “Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.
“Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga,
ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
11 Ìwọ lóyún ìyàngbò,
o sì bí koríko;
èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.
12 A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;
bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”
13 Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun
tí mo ti ṣe;
Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!
14 Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni;
ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:
“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?
Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”
15 Ẹni tí ó ń rìn lódodo
tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,
tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,
tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn
tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi
16 Òun náà yóò gbé ní ibi gíga,
ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.
A ó mú oúnjẹ fún un,
omi rẹ̀ yóò sì dájú.
17 Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀
yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.
18 Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:
“Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?
Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?
Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”
19 Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́,
àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin,
pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.
20 Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa,
ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu,
ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;
àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu
tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.
21 Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ Alágbára kan fún wa.
Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńláńlá àti odò kéékèèkéé.
Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn,
ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.
22 Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa,
Olúwa ni onídàájọ́ wa,
Olúwa òun ni ọba wa;
òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.
23 Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀:
Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀,
wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn,
lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín
àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.
24 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Sioni tí yóò wí pé, “Ara mi kò yá,”
a ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.
Ìdájọ́ Ọlọ́run lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè
34 (A)Súnmọ́ tòsí,
ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́,
tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn
jẹ́ kí ayé gbọ́,
àti ẹ̀kún rẹ̀,
ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde.
2 Nítorí ìbínú Olúwa ń bẹ
lára gbogbo orílẹ̀-èdè,
àti ìrunú rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn:
o ti fi wọ́n fún pípa,
3 Àwọn ti a pa nínú wọn
ni a ó sì jù sóde,
òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde,
àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn
4 (B)Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́,
a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá,
gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀,
bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà,
àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́.
5 Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run,
kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu,
sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́.
6 Idà Olúwa kún fún ẹ̀jẹ̀
a mú un sanra fún ọ̀rá,
àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́,
fún ọ̀rá ìwé àgbò—
nítorí Olúwa ni ìrúbọ kan ní Bosra,
àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu.
7 Àti àwọn àgbáǹréré yóò
ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá,
àti àwọn ẹgbọrọ màlúù
pẹ̀lú àwọn akọ màlúù,
ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin,
a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá.
8 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san Olúwa ni,
àti ọdún ìsanpadà,
nítorí ọ̀ràn Sioni.
9 (C)Odò rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà,
àti eruku rẹ̀ di imí-ọjọ́,
ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì di ọ̀dà tí ń jóná.
10 A kì yóò pa á ní òru tàbí ní ọ̀sán,
èéfín rẹ̀ yóò gòkè láéláé:
yóò dahoro láti ìran dé ìran,
kò sí ẹnìkan tí yóò là á kọjá láé
àti láéláé.
11 Òwìwí aginjù, àti àkàlà ni yóò ni ín,
àti òwìwí àti ẹyẹ ìwò ni yóò máa gbé inú rẹ̀.
Ọlọ́run yóò sì na sórí Edomu
okùn ìwọ̀n ìparun
àti òkúta òfo.
12 Ní ti àwọn ìjòyè rẹ̀
ẹnìkan kì yóò sí níbẹ̀
tiwọn ó pè wá sí ìjọba,
gbogbo àwọn olórí i rẹ̀ yóò sì di asán.
13 Ẹ̀gún yóò sì hù jáde
nínú àwọn ààfin rẹ̀ wọ̀nyí,
ẹ̀gún ọ̀gán nínú ìlú olódi rẹ̀.
Yóò jẹ́ ibùgbé àwọn akátá
àti àgbàlá fún àwọn òwìwí.
14 Àwọn ẹranko ijù àti àwọn ìkookò ni yóò pàdé,
àti ewúrẹ́ igbó kan yóò máa kọ sí èkejì rẹ̀,
iwin yóò máa gbé ibẹ̀ pẹ̀lú,
yóò sì rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀.
15 Òwìwí yóò tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ síbẹ̀,
yóò yé, yóò sì pa,
yóò sì kójọ lábẹ́ òjìji rẹ̀:
àwọn gúnnugún yóò péjọ síbẹ̀ pẹ̀lú,
olúkúlùkù pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀.
16 Ẹ wá a nínú ìwé Olúwa, ẹ sì kà á:
Ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí kì yóò yẹ̀,
kò sí ọ̀kan tí yóò fẹ́ èkejì rẹ̀ kù:
nítorí Olúwa ti pàṣẹ
ẹnu rẹ̀ ló sì fi kó wọn jọ
Ẹ̀mí rẹ̀ ló sì fi tò wọ́n jọ.
17 Ó ti di ìbò fún wọn,
ọwọ́ rẹ̀ sì ti pín in fún wọn
nípa títa okùn,
wọn ó jogún rẹ̀ láéláé,
láti ìran dé ìran
ni wọn ó máa gbé inú rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.