Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Hosea 1-7

Ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Hosea ọmọ Beeri wá ní àkókò ìjọba Ussiah, Jotamu, Ahasi àti Hesekiah; àwọn ọba Juda àti ní àkókò ọba Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi ní Israẹli:

Ìdílé Hosea

Nígbà tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosea, Olúwa wí fún un pé, “Lọ, fẹ́ àgbèrè obìnrin kan fún ara rẹ, kí ó sì bí ọmọ àgbèrè fún ọ nípasẹ̀ àwọn ọkùnrin mìíràn, nítorí ilẹ̀ ti ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè púpọ̀ nípa yíyapa kúrò lọ́dọ̀ Olúwa.” Nígbà náà ni ó sì lọ, ó sì fẹ́ Gomeri ọmọbìnrin Diblaimu, ọmọbìnrin náà sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún un.

Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Hosea pé, “Pe orúkọ ọmọ náà ní Jesreeli, nítorí pé láìpẹ́ ni èmi yóò jẹ ìdílé Jehu ní ìyà fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn tó pa ní ìpakúpa ní Jesreeli, Èmi yóò sì mú ìjọba Israẹli wá sí òpin. Ní ọjọ́ náà ni Èmi yóò ṣẹ́ ọrun Israẹli ní Àfonífojì Jesreeli.”

(A)Gomeri sì tún lóyún, ó sì bí ọmọbìnrin kan. Olúwa sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-rúhámà, nítorí pé Èmi kò ní ṣàánú fún ilé Israẹli mọ́, Èmi kò sì ní dáríjì wọ́n. Síbẹ̀, èmi yóò ṣàánú fún ilé Juda, èmi ó gbà wọ́n—kì í ṣe nípa ọfà, idà tàbí ogun, ẹṣin tàbí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin bí kò ṣe nípa Olúwa Ọlọ́run wọn.”

Lẹ́yìn ìgbà tí ó gba ọmú lẹ́nu Lo-rúhámà, ó sì lóyún ó sì bí ọmọkùnrin mìíràn. Nígbà náà ni Olúwa sì sọ fún un pé, “Pe orúkọ rẹ̀ ní Lo-Ammi, nítorí pé ẹ kì í ṣe ènìyàn mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọ́run yín.

10 “Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Israẹli yóò pọ̀ bí i iyanrìn etí Òkun tí a kò le wọ́n, tí a kò sì le è kà, yóò sì ṣe. Ní ibi tí wọ́n ti sọ fún wọn pé. ‘Ẹ̀yin kì í ṣe ènìyàn mi,’ níbẹ̀ ni a ó ti máa pè wọ́n ní ‘ọmọ Ọlọ́run alààyè.’ 11 Àwọn ènìyàn Juda àti àwọn ènìyàn Israẹli yóò parapọ̀, wọn yóò sì yan olórí kan tí yóò jáde láti ilẹ̀ náà, nítorí pé ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesreeli yóò jẹ́.

“Sọ fún àwọn arákùnrin rẹ, ‘Ènìyàn mi,’ kí o sì wí fún àwọn arábìnrin rẹ ‘àyànfẹ́ mi.’

Ẹ̀sùn tí a fi kan ìyàwó aláìṣòótọ́

“Ẹ bá ìyá yín wí, ẹ bá a wí,
    nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi,
    Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀
    àti àìṣòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.
Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòhò
    Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ bí ọjọ́ tí a bí i.
Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀,
    Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀
    Èmi yóò sì fi òǹgbẹ gbẹ ẹ́.
Èmi kò ní fi àánú mi hàn sí àwọn ọmọ rẹ̀
    nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n jẹ́
Nítorí ìyá wọn ti hùwà àgbèrè,
    ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú.
Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi lẹ́yìn,
    tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi,
    ní irun àgùntàn mi àti ọ̀gbọ̀ mi,
    òróró mi àti ohun mímu mi.’
Nítorí náà, èmi ó fi ẹ̀gún dì í lọ́nà
    Èmi ó mọ odi yí i ká kí ó má ba à rọ́nà lọ.
Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn;
    Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn.
Nígbà náà ni yóò sọ pé,
    ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́
    nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsin yìí lọ.’
Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni
    àti ẹni tó fún un ní ọkà,
ọtí wáìnì tuntun àti òróró
    ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Baali.

“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n,
    èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀.
Èmi yóò sì gba irun àgùntàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà
    ti mo ti fi fún un láti bo ìhòhò rẹ̀.
10 Èmi yóò sì fi ìwà ìtìjú rẹ̀ hàn
    lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀
    kò sí ẹni tí yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi
11 Èmi yóò mú gbogbo ayọ̀ rẹ̀ wá sí òpin:
    àjọ̀dún ọdọọdún rẹ̀, oṣù tuntun rẹ̀,
    ọjọ́ ìsinmi, àti gbogbo àwọn àjọ̀dún tí a yàn.
12 Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run,
    èyí tí ó pè ní èrè rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀,
Èmi yóò sọ wọ́n di igbó,
    àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.
13 Èmi yóò bẹ̀ ọjọ́ Baalimu wò ní ara rẹ̀
    nínú èyí tó ń fi tùràrí jóná fún Baali;
tí ó fi òrùka etí àti ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́,
    tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ.
    Ṣùgbọ́n èmi ni òun gbàgbé,”
    ni Olúwa wí.

14 “Nítorí náà, èmi yóò tàn án
    Èmi ó sì mú u lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀
    Èmi ó fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀
15 Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un,
    Èmi yóò fi Àfonífojì Akori ṣe ìlẹ̀kùn ìrètí fún un.
Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Ejibiti.

16 “Yóò sì ṣe ní ọjọ́ náà,
    Ìwọ yóò pè mí ní ‘ọkọ mi’;
    Ìwọ kò sì ní pè mí ní ‘olúwa à mi mọ́,’
    ni Olúwa wí.
17 Èmi yóò mú orúkọ, àwọn òrìṣà Baali kúrò lẹ́nu rẹ̀;
    ìwọ kò sì ní rí orúkọ òrìṣà Baali pè mọ́
18 Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú
    fún wọn àti àwọn ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti
    àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀.
Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́
    Ọfà, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà
    kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
19 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi títí láé.
    Èmi ó fẹ́ ọ ní ìwà òdodo àti
    òtítọ́, ní ìfẹ́ àti àánú.
20 Èmi yóò fẹ́ ọ fún ara mi ní òtítọ́
    ìwọ yóò sì mọ Olúwa.

21 “Èmi yóò sì dáhùn ní ọjọ́ náà”
    ni Olúwa wí.
“Èmi yóò dá àwọn ọ̀run lóhùn
    àwọn ọ̀run yóò sì dá ilẹ̀ lóhùn;
22 Ilẹ̀ náà yóò sì dá ọkà,
    wáìnì tuntun àti òróró lóhùn
    Gbogbo wọn ó sì dá Jesreeli lóhùn.
23 Èmi ó sì gbìn ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà
    Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àánú Gbà.’
Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’
    ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”

Hosea bá ìyàwó rẹ làjà

Olúwa sì wí fún mi pé, “Tun lọ fẹ́ obìnrin kan tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀, àti panṣágà, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Olúwasì àwọn ọmọ Israẹli tí ń wo àwọn ọlọ́run mìíràn, tí wọ́n sì ń fẹ́ àkàrà èso àjàrà.”

Nítorí náà, mo sì rà á padà ní ṣékélì fàdákà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti homeri kan àti lẹ́tékì barle kan. Mo sì sọ fún un pé, “Ìwọ gbọdọ̀ máa gbé pẹ̀lú mi fún ọjọ́ pípẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè mọ́ tàbí kí o fẹ́ ọkùnrin mìíràn, èmi náà yóò sì gbé pẹ̀lú rẹ.”

Nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli yóò wà fún ọjọ́ pípẹ́ láìní ọba tàbí olórí, láìsí ìrúbọ tàbí pẹpẹ mímọ́, láìsí àlùfáà tàbí òrìṣà kankan. Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò padà láti wá Olúwa Ọlọ́run wọn àti Dafidi ọba wọn. Wọn yóò sì wá síwájú Olúwa pẹ̀lú ẹ̀rù, wọn ó sì jọ̀wọ́ ara wọn fún Olúwa àti ìbùkún rẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn.

Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan Israẹli

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Israẹli,
    nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùn
    kan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà.
“Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́
    Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà
Àfi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyàn
    olè jíjà àti panṣágà.
Wọ́n rú gbogbo òfin,
    ìtàjẹ̀ sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀.
Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogbo
    olùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.
Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀run
    àti ẹja inú omi ló ń kú.

“Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,
    kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹnìkejì
nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbí
    àwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà
Ẹ ń ṣubú lọ́sàn án àti lóru
    àwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lú yín
Èmi ó pa ìyá rẹ run
    Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀.

“Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀.
    Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi;
nítorí pé ẹ ti kọ òfin Ọlọ́run yín sílẹ̀
    Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí i
    bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.
    Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn mi
    Wọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
Yóò sì ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà rí
    Èmi ó jẹ gbogbo wọn ní yà nítorí ọ̀nà wọn.
    Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

10 “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;
    wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,
nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwa
sílẹ̀ 11     ‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè,
wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́
àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù 12     Wọ́n ń gba ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ère igi
ọ̀pá igi sì ń dá wọn lóhùn.
    Ẹ̀mí àgbèrè ti mú wọn ṣìnà
    wọ́n sì jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wọn.
13 Wọ́n ń rú ẹbọ lórí àwọn òkè ńlá,
    Wọ́n sì ń sun ọrẹ tùràrí lórí àwọn òkè kékeré
Lábẹ́ igi óákù, àti igi Poplari
    àti igi ẹlimuati onírúurú igi tí ìbòjú rẹ̀ dára
Nítorí náà àwọn ọmọbìnrin yín yóò ṣe àgbèrè
    àti àwọn àfẹ́sọ́nà yín yóò ṣe àgbèrè.

14 “Èmi kò ní jẹ àwọn ọmọbìnrin yín
    ní yà nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè
tàbí àwọn àfẹ́sọ́nà ọmọ yín,
    nígbà tí wọ́n bá ṣe àgbèrè
nítorí pé àwọn ọkùnrin pàápàá ń bá alágbèrè kẹ́gbẹ́.
    Wọ́n sì ń rú ẹbọ pẹ̀lú àwọn alágbèrè ojúbọ òrìṣà.
    Nítorí náà, ènìyàn tí kò bá ní òye yóò parun!

15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o ṣe àgbèrè ìwọ Israẹli
    Ìdájọ́ yìí wà fún un yín Ẹ má ṣe jẹ́ kí Juda di ẹlẹ́bi.

“Ẹ má ṣe lọ sí Gilgali.
    Ẹ má sì ṣe gòkè lọ sí Beti-Afeni
    ẹ má sì búra pé, ‘Bí Olúwa ti wà láààyè nítòótọ́!’
16 Àwọn ọmọ Israẹli ṣe agídí
    bí alágídí ọmọ màlúù
Báwo wá ni Olúwa ṣe fẹ́ bọ́ wọn
    bí àgùntàn ní pápá oko tútù?
17 Efraimu ti darapọ̀ mọ́
    òrìṣà Ẹ fi sílẹ̀!
18 Bí ohun mímu wọn bá tilẹ̀ tán
    wọ́n tún tẹ̀síwájú nínú àgbèrè
    Àwọn olórí wọn fẹ́ràn ohun ìtìjú ju ohun ìyìn lọ.
19 Ìjì ni yóò gbá wọn lọ.
    Gbogbo ìrúbọ wọn yóò sì kó ìtìjú bá wọn.

Ìdájọ́ n bọ̀ lórí Israẹli àti Juda

“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!
    Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!
    Ìdájọ́ yìí kàn yín:
Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa
    àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori
Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn
    gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
Mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu
    Israẹli kò sì pamọ́ fún mi
Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè
    Israẹli sì ti díbàjẹ́.

“Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè
    láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.
Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,
    wọn kò sì mọ Olúwa.
Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;
    Àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
    Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran
    àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,
wọn kò ní rí i,
    ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa
    wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.
Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,
    ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.

“Fọn fèrè ní Gibeah,
    kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni
    máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
Efraimu yóò di ahoro
    ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli
    Mo sọ ohun tí ó dájú.
10 Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
    máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
    wọn lórí bí ìkún omi.
11 A ni Efraimu lára,
    A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́
    nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà
12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu
    Mo sì dàbí ìdin ara Juda.

13 “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,
    tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀
ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,
    ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́
Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn
    bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná
14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,
    bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.
Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;
    Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi
    títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi
wọn yóò sì wá ojú mi
    nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

Àìronúpìwàdà Israẹli

“Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
    ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
    ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
    ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
    kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa
    Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
    Yóò jáde;
Yóò tọ̀ wá wá bí òjò
    bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

“Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
    Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
    bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.
    Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi
    Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
(B)Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
    àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.
Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú
    wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú
    tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.
Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;
tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu,
    tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.
10 Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù
    ní ilé Israẹli.
Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè
    Israẹli sì di aláìmọ́.

11 “Àti fún ìwọ, Juda
    A ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.

“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,

    nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá.
Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn
    ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta.
Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn,
    àwọn olè ń fọ́ ilé;
    àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;
Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé
    mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn:
Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá;
    wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.

“Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,
    àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn
Alágbèrè ni gbogbo wọn
    wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà
tí a dáwọ́ kíkoná dúró,
    lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa
    wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná
    ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò
    wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí,
ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru
    ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀.
Gbogbo wọn gbóná bí ààrò
    wọ́n pa gbogbo olórí wọn run,
gbogbo ọba wọn si ṣubú
    kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.

“Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;
    Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà
Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run
    ṣùgbọ́n kò sì mọ̀,
Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri
    bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i
10 Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí
kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa
    Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.

11 “Efraimu dàbí àdàbà
    tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n
tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí
    tó sì tún ń padà lọ si Asiria.
12 Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn
    Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run
Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀
    Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.
13 Ègbé ní fún wọn,
    nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ìparun wà lórí wọn,
    nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!
Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà.
    Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi
14 Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,
    Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn.
Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì
    ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
15 Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára,
    síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
16 Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo;
    wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́
Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú
    nítorí ìrunú ahọ́n wọn.
Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe
    ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.