Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Chronological

Read the Bible in the chronological order in which its stories and events occurred.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
2 Ọba 15

Asariah ọba Juda

15 Ní ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n tí Jeroboamu ọba Israẹli, Asariah ọmọ Amasiah ọba Juda sì bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba. (A)Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláàdọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jekoliah; ó wá láti Jerusalẹmu. Ó ṣe ohun tí ó dára lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe. Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò ṣí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn náà tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ àti sun tùràrí níbẹ̀.

(B)Olúwa sì kọlu ọba náà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀, títí di ọjọ́ tí ó kú, ó sì ń gbé ní ilé ọ̀tọ̀. Jotamu, ọmọ ọba sì tọ́jú ààfin, ó sì ń darí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Asariah, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda. Asariah sinmi pẹ̀lú àwọn baba a rẹ̀. A sì sin ín sí ẹ̀bá wọn ní ìlú ńlá ti Dafidi. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Sekariah ọba Israẹli

Ní ọdún kejì-dínlógójì Asariah ọba Juda. Sekariah ọmọ Jeroboamu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún oṣù mẹ́fà. Ó ṣe búburú lójú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba rẹ̀ tí ṣe. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.

10 Ṣallumu ọmọ Jabesi dìtẹ̀ sí Sekariah. Ó dojúkọ ọ́ níwájú àwọn ènìyàn, ó sì pa á, ó sì jẹ ọba dípò rẹ̀. 11 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Sekariah. Wọ́n kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli. 12 Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí a sọ fún Jehu jẹ́ ìmúṣẹ: “Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò jókòó lórí ìtẹ́ Israẹli títí dé ìran kẹrin.”

Ṣallumu ọba Israẹli

13 Ṣallumu ọmọ Jabesi di ọba ní ọdún kọkàn-dínlógójì Ussiah ọba Juda, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún oṣù kan. 14 Nígbà náà Menahemu ọmọ Gadi lọ láti Tirsa sí Samaria. Ó dojúkọ Ṣallumu ọmọ Jabesi ní Samaria, ó pa á ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

15 Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ṣallumu, àti ìdìtẹ̀ tí ó dì, a kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

16 Ní ìgbà tí Menahemu ń jáde bọ̀ láti Tirsa, ó dojúkọ Tifisa àti gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ìlú ńlá àti agbègbè rẹ̀, Nítorí wọn kọ̀ láti sí ẹnu ibodè. Ó yọ Tifisa kúrò lẹ́nu iṣẹ́, ó sì la inú gbogbo àwọn obìnrin aboyún.

Menahemu ọba Israẹli

17 Ní ọdún kọkàn-dínlógójì ti Asariah ọba Juda, Menahemu ọmọ Gadi di ọba Israẹli, ó sì jẹ ọba ní Samaria fún ọdún mẹ́wàá. 18 Ó ṣe búburú lójú Olúwa, ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá.

19 Nígbà náà, Pulu ọba Asiria, gbógun ti ilẹ̀ náà, Menahemu sì fún un ní ẹgbẹ̀rin tálẹ́ǹtì fàdákà láti fi gba àtìlẹ́yìn rẹ̀ àti láti fún ìdúró tirẹ̀ lágbára lórí ìjọba. 20 Menahemu fi agbára gba owó náà lọ́wọ́ Israẹli. Gbogbo ọkùnrin ọlọ́lá ní láti dá àádọ́ta ṣékélì fàdákà láti fún ọba Asiria. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Asiria padà sẹ́yìn, kò sì dúró ní ilẹ̀ náà mọ́.

21 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Menahemu, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé ọba Israẹli? 22 Menahemu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. Pekahiah ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

Pekahiah ọba Israẹli

23 Ní ọdún kẹ́ẹ̀dógún Asariah ọba Juda, Pekahiah ọmọ Menahemu di ọba Israẹli ní Samaria, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì. 24 Pekahiah ṣe búburú lójú Olúwa. Kò yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá. 25 Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Peka ọmọ Remaliah, dìtẹ̀ sí i. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gileadi pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pekahiah pẹ̀lú Argobu àti Arie ní odi ààfin ọba ní Samaria. Bẹ́ẹ̀ ni Peka pa Pekahiah, ó sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

26 Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pekahiah, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli.

Peka ọba Israẹli

27 Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Asariah ọba Juda, Peka ọmọ Remaliah di ọba Israẹli ní Samaria. Ó sì jẹ ọba fún ogún ọdún. 28 Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó fa Israẹli láti dá.

29 Ní ìgbà Peka ọba Israẹli, Tiglat-Pileseri ọba Asiria wá, ó sì mú Ijoni, Abeli-Beti-Maaka, Janoa, Kedeṣi àti Hasori. Ó gba Gileadi àti Galili pẹ̀lú gbogbo ilẹ̀ Naftali. Ó sì kó àwọn ènìyàn ní ìgbèkùn lọ sí Asiria. 30 Nígbà náà, Hosea ọmọ Ela, dìtẹ̀ sí Peka ọmọ Remaliah. Ó dojúkọ ọ́, ó sì pa á, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba ní ogún ọdún Jotamu ọmọ Ussiah.

31 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Peka, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Israẹli?

Jotamu ọba Juda

32 Ní ọdún keje Peka ọmọ Remaliah ọba Israẹli, Jotamu ọmọ Ussiah ọba Juda bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ ọba. 33 (C)Ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mẹ́rìn-dínlógún. Orúkọ ìyá rẹ̀ a máa jẹ́ Jeruṣa ọmọbìnrin Sadoku. 34 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ Ussiah ti ṣe. 35 Àwọn ibi gíga, bí ó ti wù kí ó rí, a kò ṣí wọn kúrò; Àwọn ènìyàn tẹ̀síwájú láti rú ẹbọ àti láti sun tùràrí níbẹ̀: Jotamu tún ìlẹ̀kùn gíga tó ń kọ́ ní ti ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe.

36 Fún ti ìyókù iṣẹ́ nígbà ìjọba Jotamu, àti ohun tí ó ṣe, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Juda? 37 (Ní ayé ìgbàanì, Olúwa bẹ̀rẹ̀ sí ní rán Resini ọba Siria àti Peka ọmọ Remaliah láti dojúkọ Juda). 38 (D)Jotamu sinmi pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀. A sì sin ín pẹ̀lú wọn ní ìlú ńlá Dafidi, ìlú ńlá ti baba rẹ̀. Ahasi ọmọ rẹ̀ sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

2 Kronika 26

Ussiah ọba Juda

26 (A)Nígbà náà gbogbo ènìyàn Juda mú Ussiah, ẹni tí ó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún wọ́n sì fi jẹ ọba ní ipò baba rẹ̀ Amasiah. Òun ni ẹni náà tí ó tún Elati kọ́, ó sì mú padà sí Juda lẹ́yìn ìgbà tí Amasiah ọba ti sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀.

Ussiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìn-dínlógún nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún méjìléláadọ́ta. Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Jekoliah; ó sì wá láti Jerusalẹmu. Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bi baba rẹ̀ Amasiah ti ṣe. Ó sì wá Olúwa ní ọjọ́ Sekariah, ẹni tí ó ní òye nínú ìran Ọlọ́run. Níwọ́n ọjọ́ tí ó wá ojú Olúwa, Ọlọ́run fún un ní ohun rere.

Ó sì lọ sí ogun pẹ̀lú Filistini ó sì wó odi Gati lulẹ̀, Jabne àti Aṣdodu. Ó sì kó ìlú rẹ̀ tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ Aṣdodu àti níbìkan láàrín àwọn ará Filistini. Ọlọ́run sì ràn án lọ́wọ́ lórí àwọn ará Filistini àti Arabia tí ń gbé ní Gur-baali àti lórí àwọn ará Mehuni. Àwọn ará Ammoni gbé ẹ̀bùn wá fún Ussiah, orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri títí ó fi dé àtiwọ Ejibiti, nítorí ó ti di alágbára ńlá.

Ussiah sì kọ́ ilé ìṣọ́ ní Jerusalẹmu níbi ẹnu-bodè igun, àti níbi ẹnu-bodè Àfonífojì àti níbi ìṣẹ́po odi ó sì mú wọn le 10 Ó sì tún ilé ìṣọ́ aginjù kọ́, ó sì gbẹ́ kànga púpọ̀, nítorí ó ni ẹran ọ̀sìn púpọ̀ ní ilẹ̀ ìsàlẹ̀ àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ó sì ní àwọn ènìyàn tí ń ṣiṣẹ́ ní pápá àti ọgbà àjàrà ní orí òkè ní ilẹ̀ ọlọ́ràá, nítorí ó fẹ́ràn àgbẹ̀ ṣíṣe.

11 Ussiah sì ní àwọn ẹgbẹ́ ogun tí wọ́n kọ́ dáradára, wọ́n múra tán láti lọ pẹ̀lú ẹgbẹgbẹ́ gẹ́gẹ́ bí iye kíkà wọn gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ Jeieli akọ̀wé àti Maaseiah ìjòyè lábẹ́ ọwọ́ Hananiah, ọ̀kan lára àwọn olórí ogun ọba. 12 Àpapọ̀ iye olórí àwọn alágbára akọni ogun jẹ́ ẹgbẹ̀tàlá (2,600). 13 Lábẹ́ olórí àti olùdarí wọn, wọ́n sì jẹ́ alágbára akọni ogun ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (307,500), tí ó ti múra fún ogun ńlá náà, àti alágbára ńlá jagunjagun kan láti ran ọba lọ́wọ́ sí ọ̀tá rẹ̀. 14 Ussiah sì pèsè ọ̀kọ̀, asà, akọ́rọ́, àti ohun èlò ìhámọ́ra ọrun títí dé òkúta kànnàkànnà fún ọwọ́ àwọn ọmọ-ogun. 15 Ní Jerusalẹmu ó sì ṣe ohun ẹ̀rọ ìjagun, iṣẹ́ ọwọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn, láti wà lórí ilé ìṣọ́ àti lórí igun odi láti fi tafà àti láti fi sọ òkúta ńlá. Orúkọ rẹ̀ sì tàn káàkiri, nítorí a ṣe ìrànlọ́wọ́ ìyanu fún un títí ó fi di alágbára.

16 Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí Ussiah jẹ́ alágbára tán, ìgbéraga rẹ̀ sì gbé e ṣubú. Ó sì di aláìṣòótọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì wọ ilé Olúwa láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí. 17 Asariah àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọgọ́rin alágbára àlùfáà Olúwa mìíràn sì tẹ̀lé e. 18 Wọ́n sì takò ọba Ussiah, wọn sì wí pé, “Kò dára fún ọ, Ussiah, láti sun tùràrí sí Olúwa. Èyí fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, ẹni tí ó ti yà sí mímọ́ láti sun tùràrí. Fi ibi mímọ́ sílẹ̀, nítorí tí ìwọ ti jẹ́ aláìṣòótọ́, ìwọ kò sì ní jẹ́ ẹni ọlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run.”

19 Ussiah, ẹni tí ó ní àwo tùràrí ní ọwọ́ rẹ̀ tó ṣetán láti sun tùràrí sì bínú. Nígbà tí ó sì ń bínú sí àwọn àlùfáà níwájú wọn, níwájú pẹpẹ tùràrí ní ilé Olúwa, ẹ̀tẹ̀ sì yọ jáde ní iwájú orí rẹ̀. 20 (B)Nígbà tí Asariah olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn àlùfáà yòókù sì wò ó, wọ́n sì rí i wí pé ó ní ẹ̀tẹ̀ níwájú orí rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì sáré gbé e jáde pẹ̀lúpẹ̀lú, òun tìkára rẹ̀ ti fẹ́ láti jáde, nítorí tí Olúwa ti kọlù ú.

21 Ọba Ussiah sì ní ẹ̀tẹ̀ títí di ọjọ́ ikú rẹ̀. Ó sì gbé ní ilé àwọn adẹ́tẹ̀, a sì ké e kúrò ní ilé Olúwa. Jotamu ọmọ rẹ̀ sì gba ipò rẹ̀, ó sì ń ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà.

22 Ìyókù iṣẹ́ ìjọba Ussiah láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni a kọ láti ọwọ́ wòlíì Isaiah ọmọ Amosi. 23 Ussiah sì sùn pẹ̀lú àwọn baba, rẹ̀ a sì sin sí ẹ̀gbẹ́ wọn nínú oko ìsìnkú fún ti iṣẹ́ tí àwọn ọba, nítorí àwọn ènìyàn wí pé “Ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀,” Jotamu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.