Add parallel Print Page Options

23 (A)Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí;
    kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.
Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,
    ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,
nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà,
    ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.

Read full chapter

48 Ọ̀run àti ayé àti gbogbo ohun tí ó wà nínú wọn,
    yóò sì kọrin lórí Babeli:
nítorí àwọn afiniṣèjẹ yóò wá sórí rẹ̀ láti àríwá,”
    ni Olúwa wí.

Read full chapter

12 (A)Nítorí náà ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ọ̀run,
    àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn.
Ègbé ni fún ayé àti Òkun;
    nítorí èṣù sọ̀kalẹ̀ tọ̀ yín wá ní ìbínú ńlá,
nítorí ó mọ̀ pé ìgbà kúkúrú sá ni òun ní.”

Read full chapter

20 (A)“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!
    Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!
    Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!
Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀
    nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”

Read full chapter