Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 28-29

Ègbé ni fún Efraimu

28 Ègbé ni fún adé ìgbéraga,
    fún àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
àti fún ìtànná rírọ, ẹwà ògo rẹ̀,
    tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú
    àti sí ìlú náà
    ìgbéraga àwọn tí ọtí wáìnì ń pa tí a rẹ̀ sílẹ̀
Kíyèsi i, Olúwa ní ẹnìkan tí ó le, tí ó sì lágbára,
    gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ́ yìnyín àti bí ìjì apanirun,
gẹ́gẹ́ bí àrọ̀dá òjò àti òjò tí ó mú ìkún omi wá,
    òun yóò fi tipátipá sọ ọ́ sílẹ̀.
Adé ìgbéraga àwọn ọ̀mùtí Efraimu,
    ni a ó fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
Òdòdó tí ó ń rọ náà tí í ṣe ẹwà ògo rẹ̀,
    tí ó tò sí orí àfonífojì ẹlẹ́tù lójú,
yóò dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó pọ́n ṣáájú ìkórè
    bí ẹnikẹ́ni bá ti rí i tí ó sì mú un ní ọwọ́ rẹ̀,
    òun a sì mì ín.

Ní ọjọ́ náà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    yóò jẹ́ adé tí ó lógo,
àti adé tí ó lẹ́wà
    fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù.
Òun yóò sì jẹ́ ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo
    fún ẹni tí ó jókòó ní ìtẹ́ ìdájọ́
àti orísun agbára
    fún àwọn ẹni tí ó ń dá ogun padà ní ẹnu ibodè.

Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí wáìnì
    wọ́n pòòrì fún ọtí líle,
Àwọn àlùfáà àti wòlíì ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n fún ọtí líle
    wọ́n ta gíẹ́ gíẹ́ fún ọtí wáìnì
wọ́n ń lọ́ bìrì bìrì fún ọtí líle,
    wọ́n ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nígbà tí wọ́n ń ríran,
    wọ́n kọsẹ̀ nígbà tí wọ́n ń mú ìpinnu wá.
Gbogbo orí tábìlì ni ó kún fún èébì
    kò sì ṣí ibìkan tí kò sí ẹ̀gbin.

“Ta ni ẹni náà tí ó ń gbìyànjú àti kọ́?
    Ta ni ó sì ń ṣàlàyé ìròyìn in rẹ̀ fún?
Sí àwọn ọmọdé tí a já lẹ́nu ọmú wọn,
    sí àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́nu ọmú.
10 Nítorí tí í ṣe: báyìí ni orí
    Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ
    díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn.”

11 (A)Ó dára báyìí, pẹ̀lú ètè àjèjì àti ahọ́n àìmọ̀
    Ọlọ́run yóò bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀
12 (B)àwọn tí ó sọ fún wí pé,
    “Èyí ni ibi ìsinmi, jẹ́ kí àwọn aláàárẹ̀ sinmi”;
àti pé, “èyí ni ibi ìsinmi”
    ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sílẹ̀.
13 Fún ìdí èyí, ọ̀rọ̀ Olúwa sí wọn yóò di pé
    Ṣe, kí o si túnṣe, ṣe kí o si túnṣe,
àṣẹ n gorí àṣẹ, àṣẹ n gorí àṣẹ
    díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò lọ tí wọn yóò tún ṣubú sẹ́yìn,
    wọn yóò fi ara pa, wọn yóò bọ́ sínú okùn
    a ó sì gbá wọn mú.

14 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,
    tí ń jẹ ọba lórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní Jerusalẹmu.
15 Ẹ fọ́n pé, “Àwa ti bá ikú mulẹ̀,
    pẹ̀lú ibojì ni àwa ti jọ ṣe àdéhùn.
Nígbà tí ìbáwí gbígbóná fẹ́ kọjá,
    kò le kàn wá lára,
nítorí a ti fi irọ́ ṣe ààbò o wa
    àti àìṣòótọ́ ibi ìpamọ́ wa.”

16 (C)Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“Kíyèsi i, èmi gbé òkúta kan lélẹ̀ ní Sioni, òkúta tí a dánwò,
    òkúta igun ilé iyebíye fún ìpìlẹ̀ tí ó dájú;
ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé
    kì yóò ní ìfòyà.
17 Èmi yóò fi ìdájọ́ ṣe okùn òṣùwọ̀n
    àti òdodo òjé òṣùwọ̀n;
yìnyín yóò gbá ààbò yín dànù àti irọ́,
    omi yóò sì kún bo gbogbo ibi tí
    ẹ ń fi ara pamọ́ sí mọ́lẹ̀.
18 Májẹ̀mú yín tí ẹ bá ikú dá ni a ó fa igi lé;
    àdéhùn yín pẹ̀lú ibojì ni kì yóò dúró.
Nígbà tí ìbínú gbígbóná náà bá fẹ́ kọjá,
    a ó ti ipa rẹ̀ lù yín bolẹ̀.
19 Nígbàkúgbà tí ó bá ti wá ni
    yóò máa gbé ọ lọ,
ni àràárọ̀, ní ọ̀sán àti ní òru,
    ni yóò máa fẹ́ kọjá lọ.”

Ìmòye ọ̀rọ̀-ìmọ̀ yìí
    yóò máa mú ìpayà ńlá wá.
20 Ibùsùn kúrú púpọ̀ fún ìnara lé lórí,
    ìbora kò fẹ̀ tó láti yí ara yín ká.
21 Olúwa yóò dìde sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
    ní òkè Peraṣimu
yóò ru ara rẹ̀ sókè gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe
    ní Àfonífojì Gibeoni—
láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀, abàmì iṣẹ́ ẹ rẹ̀,
    yóò ṣe iṣẹ́ rẹ̀, àní àjèjì iṣẹ́ rẹ̀.
22 Ní ìsinsin yìí ẹ dákẹ́ ẹlẹ́yà ṣíṣe,
    bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìdè e yín yóò le sí i;
Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ fún mi
    nípa àṣẹ ìparun ti ó ti pa lórí gbogbo ilẹ̀ náà.

23 Tẹ́tí kí o sì gbọ́ ohùn mi,
    fi ara balẹ̀ kí o sì gbọ́ ohun tí mo sọ.
24 Nígbà tí àgbẹ̀ kan bá tu ilẹ̀ láti gbìn
    yóò ha máa tulẹ̀ títí bi?
Ǹjẹ́ yóò ha máa tu ilẹ̀ kí
    ó sì máa jọ̀ ọ́ títí lọ bí?
25 Nígbà tí òun bá ti tẹ́ ojú ilẹ̀ rẹ̀ pẹrẹsẹ
    òun kò ha ń fúnrúgbìn dílì
kí ó sì fúnrúgbìn kummini ká?
    Kí ó sì gbin alikama lẹ́sẹẹsẹ,
barle tí a yàn,
    àti spelti ní ipò rẹ̀?
26 Ọlọ́run rẹ̀ tọ́ ọ ṣọ́nà
    ó sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà tó tọ́.

27 Nítorí a kò fi ohun èlò ìpakà dili,
    bẹ́ẹ̀ ni a kì í yí kẹ̀kẹ́ ẹrù kiri lórí kummini;
ṣùgbọ́n ọ̀pá ni a fi ń pa dili jáde,
    ọ̀gọ ni a sì lu kummini.
28 A gbọdọ̀ lọ ìyẹ̀fun kí a tó ṣe àkàrà;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì í máa pa á lọ títí láé.
Bí ó tilẹ̀ yí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ìpakà a rẹ̀ lórí i rẹ̀,
    àwọn ẹṣin rẹ̀ kò le lọ̀ ọ́.
29 Gbogbo èyí pẹ̀lú ti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wá,
    oníyanu ní ìmọ̀ràn àti ológo ní ọgbọ́n.

Ègbé ni fún ìlú Dafidi

29 Ègbé ni fún ọ, Arieli, Arieli,
    ìlú níbi tí Dafidi tẹ̀dó sí!
Fi ọdún kún ọdún
    sì jẹ́ kí àwọn àkọlùkọgbà àjọ̀dún un rẹ tẹ̀síwájú.
Síbẹ̀síbẹ̀ èmi yóò dó ti Arieli
    òun yóò ṣọ̀fọ̀ yóò sì sọkún,
    òun yóò sì dàbí pẹpẹ ọkàn sí mi.
Èmi yóò sì wà ní bùba yí ọ ká níbi gbogbo;
    Èmi yóò sì fi ilé ìṣọ́ yí ọ ká:
    èmi yóò sì fi iṣẹ́ ìdó ti ni mi dojúkọ ọ́.
Ní ìrẹ̀sílẹ̀, ìwọ ó sì máa sọ̀rọ̀ láti ilẹ̀ wá;
    ọ̀rọ̀ rẹ yóò sì máa kùn jáde láti inú erùpẹ̀.
Ohun rẹ yóò máa jáde bí i ti ẹnìkan tó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ láti ilẹ̀ jáde wá,
    láti inú erùpẹ̀ ni ohùn rẹ
    yóò máa wá wúyẹ́wúyẹ́.

Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀tá rẹ, yóò dàbí yanrìn kíkúnná,
    agbo àwọn aláìláàánú bí ìyàngbò tí a fẹ́ dànù.
    Lójijì, ní ìṣẹ́jú kan,
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò wá
    pẹ̀lú àrá, ilẹ̀-rírì àti ariwo ńlá
àti ẹ̀fúùfù líle àti iná ajónirun
    Lẹ́yìn náà,
    ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn tí gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó bá Arieli jà,
tí ó dojú ìjà kọ òun àti ilé olódi rẹ̀
    tí ó sì dó tì í,
yóò dàbí ẹni pé nínú àlá,
    bí ìran ní òru
àti bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa ń lá àlá pé òun ń jẹun,
    ṣùgbọ́n ó jí, ebi rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀;
tàbí bí ìgbà tí ẹni tí òǹgbẹ ń gbẹ lá àlá pé òun ń mu omi,
    ṣùgbọ́n nígbà tí ó jí, sì wò ó, ó dákú, òǹgbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè
    tí ń bá òkè Sioni jà.

Ẹ bẹ̀rù kí ẹnu kí ó yà yín,
    ẹ fọ́ ara yín lójú kí ẹ má sì ríran;
ẹ mutí yó kì í ṣe ọtí wáìnì,
    ẹ ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n, ṣùgbọ́n kì í ṣe ti ọtí líle.
10 Olúwa ti mú oorun ìjìká wá sórí i yín:
    ó ti dì yín lójú ẹ̀yin wòlíì;
    ó ti bo orí yín ẹ̀yin aríran.

11 Fún un yín gbogbo ìran yìí kò yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ tí a fi èdìdì dì sínú ìwé kíká. Bí ẹ bá sì fún ẹni tí ó lè ka ìwé kíká náà, tí ẹ sì sọ fún un pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò lè kà á; a ti dì í ní èdìdì.” 12 Tàbí bí ẹ bá fún ẹni tí kò lè ka ìwé kíká náà tí ẹ sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ka èyí,” òun yóò dáhùn pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n kà.”

13 (D)Olúwa wí pé:

“Àwọn ènìyàn yìí súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹnu wọn,
    wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ètè wọn,
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà sí mi.
    Ìsìn wọn si mi
ni a gbé ka orí òfin tí àwọn
    ọkùnrin kọ́ ni.
14 (E)Nítorí náà lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò ya
    àwọn ènìyàn yìí lẹ́nu
pẹ̀lú ìyanu lórí ìyanu;
    ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n ni yóò ṣègbé,
    ìmọ̀ àwọn onímọ̀ ni yóò pòórá.”
15 Ègbé ni fún àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun
    láti fi ètò wọn pamọ́ kúrò lójú Olúwa,
tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ẹ wọn nínú òkùnkùn
    tí wọ́n sì rò pé,
    “Ta ló rí wa? Ta ni yóò mọ̀?”
16 (F)Ẹ̀yin dojú nǹkan délẹ̀,
    bí ẹni pé wọ́n rò pé amọ̀kòkò dàbí amọ̀!
Ǹjẹ́ ohun tí a ṣe le sọ fún olùṣe pé
    “Òun kọ́ ló ṣe mí”?
Ǹjẹ́ ìkòkò lè sọ nípa amọ̀kòkò pé,
    “kò mọ nǹkan”?

17 Ní àìpẹ́ jọjọ, ǹjẹ́
    a kò ní sọ Lebanoni di pápá ẹlẹ́tù lójú
    àti pápá ẹlẹ́tù lójú yóò dàbí aginjù?
18 (G)Ní ọjọ́ náà adití yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ ìwé kíká náà,
    láti inú fìrífìrí àti òkùnkùn
    ni àwọn ojú afọ́jú yóò ríran.
19 Lẹ́ẹ̀kan sí i àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóò yọ̀ nínú Olúwa:
    àwọn aláìní yóò yọ̀ nínú Ẹni Mímọ́ ti Israẹli.
20 Aláìláàánú yóò pòórá,
    àwọn tí ń ṣẹlẹ́yà yóò di àwátì,
    gbogbo àwọn tí ó ní ojú ibi ni a ó ké lulẹ̀—
21 àwọn tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ kan mú ẹnìkan di ẹlẹ́bi,
    ẹni tí ń dẹkùn mú olùgbèjà ní ilé ẹjọ́
    tí ẹ fi ẹ̀rí èké dun aláìṣẹ̀ ní ìdájọ́.

22 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa, ẹni tí ó ra Abrahamu padà sọ sí ilé Jakọbu:

    “Ojú kì yóò ti Jakọbu mọ́;
    ojú wọn kì yóò sì rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23 Nígbà tí wọ́n bá rí i láàrín àwọn ọmọ wọn,
    àwọn iṣẹ́ ọwọ́ mi,
wọn yóò ya orúkọ mi sí mímọ́,
    wọn yóò tẹ́wọ́gbà mímọ́ Ẹni Mímọ́ Jakọbu
    wọn yóò dìde dúró ní ìbọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run Israẹli.
24 Gbogbo àwọn tí ń rìn ségesège ní yóò jèrè ìmọ̀;
    gbogbo àwọn tí ń ṣe àròyé yóò gba ìtọ́sọ́nà.”

Filipi 3

Kò sí ìgbẹ́kẹ̀lé ẹlẹ́ran ara

Ní àkótán ará, ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa wa. Kì í ṣe ìnira fún mi láti kọ̀wé ohun kan náà sí yín, ṣùgbọ́n fún yín ó jẹ́ ohun ààbò. Ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn ajá, ẹ kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ búburú, ẹ sì kíyèsára lọ́dọ̀ àwọn onílà. (A)Nítorí àwa ni onílà, tí ń sin Ọlọ́run nípa ti Ẹ̀mí, àwa sì ń ṣògo nínú Kristi Jesu, àwa kò sí ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ẹran-ara. (B)Bí èmi tìkára mi pẹ̀lú ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara.

Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ara, tèmi tilẹ̀ pọ̀: Ẹni tí a kọ nílà ní ọjọ́ kẹjọ, láti inú kùkùté Israẹli wá, láti inú ẹ̀yà Benjamini, Heberu láti inú Heberu wá; nítorí, ní ti òfin Farisi ni èmi; Ní ti ìtara, èmi ń ṣe inúnibíni sí ìjọ; ní ti òdodo tí ó wà nínú òfin, mo jẹ́ aláìlẹ́gàn.

Ṣùgbọ́n ohunkóhun tí ó ti jásí èrè fún mi, àwọn ni mo ti kà sí òfo nítorí Kristi. Nítòótọ́ láìṣe àní àní mo sì ka ohun gbogbo sí òfo nítorí ìtayọ ìmọ̀ Kristi Jesu Olúwa mi; nítorí ẹni ti mo ti ṣòfò ohun gbogbo, mo si kà wọn sí ohun tí kò ní èrè, kí èmi lè jèrè Kristi, Kí a sì lè bá mi nínú rẹ̀, láìní òdodo tí èmi tìkára mi, tí ó ti inú òfin wá, ṣùgbọ́n èyí tí ó ti inú ìgbàgbọ́ wá nínú Kristi, òdodo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; 10 Èmi mọ̀ ọ́n, àti agbára àjíǹde rẹ̀, àti láti jẹ́ alábápín nínú ìyà rẹ̀ nígbà tí mo bá fi ara mọ́ ọn nínú ikú rẹ̀; 11 nípasẹ̀ bẹ́ẹ̀ kí èmi lè ní àjíǹde kúrò nínú òkú.

12 Kì í ṣe pé ọwọ́ mi ti tẹ̀ ẹ́ ná, tàbí mo ti di pípé: ṣùgbọ́n èmi ń lépa sí i, bí ọwọ́ mi yóò lè tẹ èrè náà nítorí èyí tí a ti dì mímú pẹ̀lú, láti ọ̀dọ̀ Kristi Jesu wá. 13 Ará, èmi kò kara mi sí ẹni ti ọwọ́ rẹ̀ ti tẹ̀ ẹ́ ná: Ṣùgbọ́n ohun kan yìí ni èmi ń ṣe, èmi ń gbàgbé àwọn nǹkan tí ó ti kọjá. Lẹ́yìn náà mo ń nàgà wo àwọn nǹkan tí ó wà níwájú. 14 Èmi ń lépa láti dé òpin eré ìje náà fún èrè ìpè gíga Ọlọ́run nínú Kristi Jesu.

15 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí àwa tí a dàgbà nípa ti ẹ̀mí ni èrò yìí; bí ẹ̀yin bá sì ní èrò mìíràn nínú ohunkóhun, èyí náà pẹ̀lú ni Ọlọ́run yóò fihàn yín. 16 Kìkì pé, ki a ma gbe ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bi èyí ti a ri gba.

17 (C)Ará, ẹ jùmọ̀ ṣe àfarawé mi, ẹ ṣe àkíyèsí àwọn tí ń rìn bẹ́ẹ̀, àní bí ẹ ti ní wa fún àpẹẹrẹ. 18 Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ń rìn, nípasẹ̀ àwọn ẹni tí mo ti ń wí fún yín nígbàkúgbà, àní, tí mo sì ń sọkún bí mo ti ń wí fún yín nísinsin yìí, pé, ọ̀tá àgbélébùú Kristi ni wọ́n: 19 Ìgbẹ̀yìn wọn ni ìparun, ikùn wọn sì ni Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń ṣògo nínú ìtìjú wọn, àwọn ẹni tí ń tọ́jú ohun ti ayé. 20 Nítorí ìlú ìbílẹ̀ wá ń bẹ̀ ní ọ̀run: láti ibi ti àwa pẹ̀lú gbé ń fojúsọ́nà fún Olùgbàlà, Jesu Kristi Olúwa. 21 (D)Ẹni tí yóò sọ ara ìrẹ̀lẹ̀ wa di ọ̀tún kí ó lè bá ara ògo rẹ̀ mu, nípa agbára tí ó mú kí ó ṣe é ṣe fún un láti tẹ orí ohun gbogbo bá fún ara rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.