Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 43-44

Olùgbàlà Israẹli kan ṣoṣo

43 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí, ohun tí Olúwa wí nìyìí
    ẹni tí ó dá ọ, ìwọ Jakọbu
    ẹni tí ó mọ ọ́, Ìwọ Israẹli:
“Má bẹ̀rù, nítorí Èmi ti dá ọ nídè;
    Èmi ti pè ọ́ ní orúkọ; tèmi ni ìwọ ṣe.
Nígbà tí ìwọ bá ń la omi kọjá,
    Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ;
àti nígbà tí ìwọ bá ń la odò kọjá
    wọn kì yóò bò ọ́ mọ́lẹ̀.
Nígbà tí ìwọ bá la iná kọjá,
    kò ní jó ọ;
    ahọ́n iná kò ní jó ọ lára.
Nítorí Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    Ẹni Mímọ́ Israẹli Olùgbàlà rẹ;
Èmi fi Ejibiti ṣe ìràpadà rẹ,
    Kuṣi àti Seba dípò rẹ.
Nítorí pé o ṣe iyebíye àti ọ̀wọ́n níwájú mi,
    àti nítorí pé mo fẹ́ràn rẹ,
Èmi yóò fi ènìyàn rọ́pò fún ọ,
    àti ènìyàn dípò ẹ̀mí rẹ.
Má bẹ̀rù nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ;
    Èmi yóò mú àwọn ọmọ rẹ láti ìlà-oòrùn wá
    èmi ó sì kó ọ jọ láti ìwọ̀-oòrùn.
Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’
    Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’
Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá
    àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—
ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́,
    tí mo dá fún ògo mi,
    tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”

Sin àwọn tí ó ní ojú ṣùgbọ́n tí wọ́n fọ́jú jáde,
    tí wọ́n ní etí ṣùgbọ́n tí wọn dití.
Gbogbo orílẹ̀-èdè kó ra wọn jọ
    àwọn ènìyàn sì kó ra wọn papọ̀.
Ta ni nínú wọn tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí
    tí ó sì kéde fún wa àwọn nǹkan ti tẹ́lẹ̀?
Jẹ́ kí wọ́n mú àwọn ẹlẹ́rìí wọn wọlé wá
    láti fihàn pé wọ́n tọ̀nà
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn mìíràn yóò gbọ́, tí
    wọn yóò sọ pé, “Òtítọ́ ni.”
10 “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí,
    “Àti ìránṣẹ́ mi tí èmi ti yàn,
tó bẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi mọ̀ àti tí ẹ̀yin ó fi gbà mí gbọ́
    tí yóò sì yé e yín pé èmi ni ẹni náà.
Ṣáájú mi kò sí ọlọ́run tí a dá,
    tàbí a ó wa rí òmíràn lẹ́yìn mi.
11 Èmi, àní Èmi, Èmi ni Olúwa,
    yàtọ̀ sí èmi, kò sí olùgbàlà mìíràn.
12 Èmi ti fihàn, mo gbàlà mo sì ti kéde
    Èmi, kì í sì í ṣe àwọn àjèjì òrìṣà láàrín yín.
Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,” ni Olúwa wí, “Pé Èmi ni Ọlọ́run.
13     Bẹ́ẹ̀ ni, àti láti ayérayé Èmi ni ẹni náà.
Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ mi.
    Nígbà tí mo bá ṣe nǹkan, ta ni ó lè yí i padà?”

Àánú Ọlọ́run àti àìṣòdodo Israẹli

14 Èyí ni ohun tí Olúwa
    olùràpadà rẹ, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli;
“Nítorí rẹ Èmi yóò ránṣẹ́ sí Babeli
    láti mú wọn sọ̀kalẹ̀ wá gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá,
gbogbo ará Babeli
    nínú ọkọ̀ ojú omi nínú èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìgbéraga.
15 Èmi ni Olúwa, Ẹni Mímọ́ rẹ,
    Ẹlẹ́dàá Israẹli, ọba rẹ.”

16 Èyí ni ohun tí Olúwa
    Ẹni náà tí ó la ọ̀nà nínú Òkun,
    ipa ọ̀nà láàrín alagbalúgbú omi,
17 ẹni tí ó wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin jáde,
    àwọn jagunjagun àti ohun ìjà papọ̀,
wọ́n sì sùn síbẹ̀, láìní lè dìde mọ́,
    wọ́n kú pirá bí òwú-fìtílà:
18 “Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá;
    má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́.
19 Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun!
    Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí?
Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀
    àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá.
20 Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi,
    àwọn ajáko àti àwọn òwìwí,
nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀
    àti odò nínú ilẹ̀ sísá,
láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi,
21     àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi
    kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.

22 “Síbẹ̀síbẹ̀ ìwọ kò tí ì ké pè mí,
    ìwọ Jakọbu,
àárẹ̀ kò tí ì mú ọ nítorí mi
    ìwọ Israẹli.
23 Ìwọ kò tí ì mú àgùntàn wá fún mi fún ẹbọ sísun,
    tàbí kí o bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ẹbọ rẹ.
Èmi kò tí ì wàhálà rẹ pẹ̀lú ọrẹ ìyẹ̀fun
    tàbí kí n dààmú rẹ pẹ̀lú ìbéèrè fún tùràrí.
24 Ìwọ kò tí ì ra kalamusi olóòórùn dídùn fún mi,
    tàbí kí o da ọ̀rá ẹbọ rẹ bò mí.
Ṣùgbọ́n ẹ ti wàhálà mi pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ yín
    ẹ sì ti dààmú mi pẹ̀lú àìṣedéédéé yín.

25 “Èmi, àní Èmi, Èmi ni ẹni tí ó wẹ
    àwọn àìṣedéédéé rẹ nù, nítorí èmi fún ara mi,
    tí n kò sì rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ mọ́.
26 Bojú wo ẹ̀yìn rẹ fún mi,
    jẹ́ kí a jọ ṣe àríyànjiyàn ọ̀rọ̀ náà papọ̀;
    ro ẹjọ́ láti fihàn pé o kò lẹ́sẹ̀ lọ́rùn.
27 Baba yín àkọ́kọ́ dẹ́ṣẹ̀;
    àwọn agbẹnusọ yín ṣọ̀tẹ̀ sí mi.
28 Nítorí náà, èmi ti sọ àwọn olórí ibi mímọ́ náà di àìmọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi ti fi Jakọbu fún ègún
    àti Israẹli fún ẹ̀gàn.

Israẹli tí a yàn

44 “Ṣùgbọ́n gbọ́ nísinsin yìí, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi
    àti Israẹli, ẹni tí mo ti yàn.
Ohun tí Olúwa wí nìyìí
    ẹni tí ó dá ọ, ẹni tí ó ti mọ̀ ọ́n
láti inú ìyá rẹ wá,
    àti ẹni tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú:
Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu, ìránṣẹ́ mi,
    Jeṣuruni ẹni tí mo ti yàn.
Nítorí èmi yóò da omi sí ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ
    àti àwọn odò ní ilẹ̀ gbígbẹ;
Èmi yóò tú Ẹ̀mí mi sí ara àwọn ọmọ rẹ,
    àti ìbùkún mi sórí àwọn àrọ́mọdọ́mọ rẹ.
Wọn yóò dàgbàsókè gẹ́gẹ́ bí i koríko nínú pápá oko tútù,
    àti gẹ́gẹ́ bí igi Poplari létí odò tí ń sàn.
Ọ̀kan yóò wí pé, ‘Èmi jẹ́ ti Olúwa’;
    òmíràn yóò pe ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orúkọ Jakọbu;
bẹ́ẹ̀ ni òmíràn yóò kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀, ‘Ti Olúwa,’
    yóò sì máa jẹ́ orúkọ náà Israẹli.

Olúwa ni, kì í ṣe ère òrìṣà

(A)“Ohun tí Olúwa wí nìyìí
    ọba Israẹli àti Olùdáǹdè, àní
Olúwa àwọn ọmọ-ogun:
    Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìgbẹ̀yìn,
    lẹ́yìn mi kò sí Ọlọ́run kan.
Ta ni ó dàbí ì mi? Jẹ́ kí o kéde rẹ̀.
    Jẹ́ kí ó wí kí ó sì gbé síwájú mi
Kí ni ó ti ṣẹlẹ̀ láti ìgbà tí mo fi ìdí
    àwọn ènìyàn ìṣẹ̀ǹbáyé kalẹ̀,
àti kí ni ohun tí ń sì ń bọ̀
    bẹ́ẹ̀ ni, jẹ́ kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ohun tí ń bọ̀ wá.
Má ṣe wárìrì, má ṣe bẹ̀rù.
    Ǹjẹ́ èmi kò ti kéde èyí tí mo sì ti sọ
àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tipẹ́tipẹ́?
    Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan
ha ń bẹ lẹ́yìn mi?
    Bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí àpáta mìíràn; Èmi kò mọ ọ̀kankan.”

Gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère jásí asán,
    àti àwọn ohun tí wọn ń kó pamọ́
kò jámọ́ nǹkan kan.
    Àwọn tí yóò sọ̀rọ̀ fún wọn fọ́ lójú;
    wọ́n jẹ́ aláìmọ̀kan sí ìtìjú ara wọn.
10 Ta ni ó mọ òrìṣà kan tí ó sì ya ère,
    tí kò lè mú èrè kankan wá fún un?
11 Òun àti nǹkan rẹ̀ wọ̀nyí ni a ó dójútì;
    àwọn oníṣọ̀nà kò yàtọ̀, ènìyàn ni wọ́n.
Jẹ́ kí gbogbo wọn gbárajọ kí wọ́n sì
    fi ìdúró wọn hàn;
    gbogbo wọn ni a ó mú bọ́ sínú Ìpayà àti àbùkù.

12 Alágbẹ̀dẹ mú ohun èlò,
    ó fi ń ṣiṣẹ́ nínú èédú;
ó fi òòlù ya ère kan,
    ó ṣe é pẹ̀lú agbára apá rẹ̀,
Ebi ń pa á, àárẹ̀ sì mú un;
    kò mu omi rárá, ìrẹ̀wẹ̀sì dé bá a.
13 Gbẹ́nàgbẹ́nà fi ìwọ̀n wọ́n ọ́n
    ó sì fi lẹ́ẹ̀dì ṣe ààmì sí ara rẹ̀,
Ó tún fi ìfà fá a jáde
    ó tún fi òṣùwọ̀n ṣe ààmì sí i.
Ó gbẹ́ ẹ ní ìrí ènìyàn
    gẹ́gẹ́ bí ènìyàn nínú ògo rẹ̀,
    kí ó lè máa gbé nínú ilé òrìṣà.
14 Ó gé igi kedari lulẹ̀,
    tàbí bóyá ó mú sípírẹ́ṣì tàbí igi óákù.
Ó jẹ́ kí ó dàgbà láàrín àwọn igi inú igbó,
    ó sì le gbin igi páínì, èyí tí òjò mú kí ó dàgbà.
15 Ohun èlò ìdáná ni fún ènìyàn;
    díẹ̀ nínú rẹ̀ ni ó mú láti mú kí
ara rẹ̀ lọ́wọ́ọ́rọ́,
    ó dá iná ó sì fi ṣe àkàrà.
Ṣùgbọ́n bákan náà ni ó ṣe òrìṣà tí ó sì ń sìn ín;
    ó yá ère, ó sì ń foríbalẹ̀ fún un.
16 Ìlàjì igi náà ni ó jó nínú iná;
    lórí i rẹ̀ ni ó ti ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀,
ó dín ẹran rẹ̀ ó sì jẹ àjẹyó.
    Ó tún mú ara rẹ̀ gbóná ó sì sọ pé,
    “Á à! Ara mi gbóná, mo rí iná.”
17 Nínú èyí tí ó kù ni ó ti ṣe òrìṣà, ère rẹ̀;
    ó foríbalẹ̀ fún un, ó sì sìn ín.
Ó gbàdúrà sí i, ó wí pé,
    “Gbà mí, ìwọ ni Ọlọ́run mi.”
18 Wọn kò mọ nǹkan kan, nǹkan kan kò yé wọn;
    a fi ìbòjú bo ojú wọn, wọn kò lè rí nǹkan kan;
    bẹ́ẹ̀ ni àyà wọn sébọ́, wọn kò lè mọ nǹkan kan.
19 Kò sí ẹni tí ó dúró láti ronú,
    kò sí ẹni tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye
láti sọ wí pé,
    “Ìlàjì rẹ̀ ni mo fi dáná;
Mo tilẹ̀ ṣe àkàrà lórí èédú rẹ̀,
    Mo dín ẹran, mo sì jẹ ẹ́.
Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí n ṣe ohun ìríra kan
    nínú èyí tí ó ṣẹ́kù bí?
    Ǹjẹ́ èmi yóò ha foríbalẹ̀ fún ìtì igi?”
20 Ó ń jẹ eérú, ọkàn ẹlẹ́tàn ni ó ṣì í lọ́nà;
    òun kò lè gba ara rẹ̀ là, tàbí kí ó wí pé
    “Ǹjẹ́ nǹkan tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún mi yìí irọ́ kọ́?”

21 “Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu
    nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli.
Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,
    ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.
22 Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru,
    àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀.
Padà sọ́dọ̀ mi,
    nítorí mo ti rà ọ́ padà.”

23 (B)Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí Olúwa ló ti ṣe èyí;
    kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.
Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,
    ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,
nítorí Olúwa ti ra Jakọbu padà,
    ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.

A ó tún máa gbé Jerusalẹmu

24 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí
    Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́
    láti inú ìyá rẹ wá:

“Èmi ni Olúwa
    tí ó ti ṣe ohun gbogbo
    tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run
    tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
25 (C)ta ni ó ba ààmì àwọn wòlíì èké jẹ́
    tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀,
tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀
    tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
26 ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde
    tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,

“ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘a ó máa gbé inú rẹ̀,’
    àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’
    àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’
27 ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,
    èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
28 ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi
    àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;
òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,”
    àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”

1 Tẹsalonika 2

Iṣẹ́ Paulu ní ìjọ Tẹsalonika

Ẹ̀yin pàápàá mọ̀ ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán. (A)Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìhìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle. Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè. Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìhìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò. (B)A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa. (C)A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín. (D)Ṣùgbọ́n àwa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrín yín tí a sì ṣe ìtọ́jú yín.

Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀, (E)bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìhìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa. Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín. 10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 11 (F)Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ 12 (G)ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.

13 (H)Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 14 Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù, 15 (I)àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn 16 (J)nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìhìnrere dúró láàrín àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń di púpọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.

Paulu n fẹ́ láti rí àwọn ìjọ Tẹsalonika

17 (K)Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín. 18 Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Paulu, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n èṣù ú dè wá lọ́nà. 19 (L)Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó ṣògo níwájú Jesu Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ́ ni? 20 (M)Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.