Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 53-55

53 (A)Ta ni ó ti gba ìròyìn in wa gbọ́
    àti ta ni a ti fi apá Olúwa hàn fún?
Òun dàgbàsókè níwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ irúgbìn,
    àti gẹ́gẹ́ bí i gbòǹgbò tí ó jáde láti inú ìyàngbẹ ilẹ̀.
Òun kò ní ẹwà tàbí ògo láti fà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀,
    kò sí ohun kankan nínú àbùdá rẹ̀
    tí ó fi yẹ kí a ṣàfẹ́rí i rẹ̀.
A kẹ́gàn rẹ̀ àwọn ènìyàn sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    ẹni ìbànújẹ́, tí ó sì mọ bí ìpọ́njú ti rí.
Gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan tí àwọn ènìyàn ń fojú pamọ́ fún
    a kẹ́gàn rẹ, a kò sì bu ọlá fún un rárá.

(B)Lóòtítọ́ ó ti ru àìlera wa lọ
    ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa pẹ̀lú,
síbẹ̀ a kà á sí ẹni tí Ọlọ́run lù,
    tí ó lù, tí a sì pọ́n lójú.
(C)Ṣùgbọ́n a sá a lọ́gbẹ́ nítorí àìṣedéédéé wa
    a pa á lára nítorí àìṣòdodo wa;
ìjìyà tí ó mú àlàáfíà wá fún wa wà lórí i rẹ̀,
    àti nípa ọgbẹ́ rẹ̀ ni a fi mú wa láradá.
Gbogbo wa bí àgùntàn, ti ṣìnà lọ,
    ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ti yà sí ọ̀nà ara rẹ̀;
Olúwa sì ti gbé e ka orí ara rẹ̀
    gbogbo àìṣedéédéé wa.

(D)A jẹ ẹ́ ní yà, a sì pọ́n ọn lójú,
    síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀;
a mú un wá gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́-àgùntàn sọ́dọ̀ alápatà,
    àti gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí ó dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀,
    síbẹ̀ kò ya ẹnu rẹ̀.
Pẹ̀lú ìpọ́nlójú àti ìdánilẹ́jọ́ ni a mú un jáde lọ,
    ta ni ó sì le sọ nípa ìrànlọ́wọ́ rẹ̀?
Nítorí a ké e kúrò ní ilẹ̀ àwọn alààyè;
    nítorí àìṣedéédéé àwọn ènìyàn mi ni a ṣe lù ú.
(E)A fún un ní ibojì pẹ̀lú àwọn ìkà,
    àti pẹ̀lú àwọn ọlọ́rọ̀ ní ikú rẹ̀,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò hùwà jàgídíjàgan kan,
    tàbí kí a rí ẹ̀tàn kan ní ẹnu rẹ̀.

10 Síbẹ̀, ó wu Olúwa láti pa á lára
    àti láti mú kí ó jìyà,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fi ayé rẹ̀
    fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,
Òun yóò rí àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀ àti ọjọ́ ayé
    rẹ̀ yóò pẹ́ títí,
    àti ète Olúwa ni yóò gbèrú ní ọwọ́ rẹ̀.
11 Lẹ́yìn ìpọ́njú ẹ̀mí rẹ̀,
    òun yóò rí ìmọ́lẹ̀, ààyè yóò sì tẹ́ ẹ lọ́rùn;
nípa ìmọ̀ rẹ̀ ìránṣẹ́ mi olódodo yóò dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ láre,
    Òun ni yóò sì ru àìṣedéédéé wọn.
12 (F)Nítorí náà èmi yóò fún un ní ìpín pẹ̀lú àwọn ẹni ńlá
    òun yóò sì pín ìkógun pẹ̀lú àwọn alágbára,
nítorí pé òun jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ fún ikú,
    tí a sì kà á mọ́ àwọn alárékọjá.
Nítorí ó ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀,
    ó sì ṣe ìlàjà fún àwọn alárékọjá.

Ògo ọjọ́ iwájú ti Sioni

54 (G)“Kọrin, ìwọ obìnrin àgàn,
    ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;
bú sí orin, ẹ hó fún ayọ̀,
    ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;
nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoro
    ju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”
    ni Olúwa wí.
Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,
    fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,
má ṣe dá a dúró;
    sọ okùn rẹ di gígùn,
    mú òpó rẹ lágbára sí i.
Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn àti sí òsì;
    ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀-èdè,
    wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.

“Má ṣe bẹ̀rù, ìtìjú kò ní ṣubú lù ọ́.
    Má ṣe bẹ̀rù ìdójútì, a kì yóò kàn ọ́ lábùkù.
Ìwọ yóò gbàgbé ìtìjú ìgbà èwe e rẹ
    Ìwọ kì yóò sì rántí ẹ̀gàn ìgba-opo rẹ mọ́.
Nítorí Ẹlẹ́dàá rẹ ni ọkọ rẹ
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀
Ẹni Mímọ́ Israẹli ni Olùràpadà rẹ;
    a sì ń pè é ní Ọlọ́run gbogbo ayé.
Olúwa yóò pè ọ́ padà
    àfi bí ẹni pé obìnrin tí a kọ̀sílẹ̀
tí a sì bà lọ́kàn jẹ́
    obìnrin tí a fẹ́ ní ọ̀dọ́,
    tí a sì wá jákulẹ̀” ni Olúwa wí.
“Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóò
    mú ọ padà wá.
Ní ríru ìbínú.
    Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,
ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kun
    Èmi yóò ṣíjú àánú wò ọ́,”
    ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

“Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Noa,
    nígbà tí mo búra pé àwọn omi
Noa kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.
    Bẹ́ẹ̀ ni nísinsin yìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.
10 Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlá
    tí a sì ṣí àwọn òkè kékeré nídìí,
Síbẹ̀síbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláé
    tàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”
    ni Olúwa, ẹni tí ó ṣíjú àánú wò ọ́ wí.

11 (H)Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kiri
    tí a kò sì tù nínú,
Èmi yóò fi òkúta Tikuosi kọ́ ọ
    àti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú safire.
12 Èmi yóò fi iyùn ṣe odi rẹ,
    àwọn ẹnu-ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,
    àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.
13 (I)Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,
    àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.
14 Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀
    ìwà ipá yóò jìnnà sí ọ
o kò ní bẹ̀rù ohunkóhun
    Ìpayà la ó mú kúrò pátápátá;
    kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.
15 Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ mi;
    ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.

16 “Kíyèsi i, èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹ
    tí ń fẹ́ iná èédú iná
tí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.
    Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;
17 Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò lè ṣe nǹkan,
    àti gbogbo ahọ́n tí ó dìde sí ọ ní ìdájọ́
    ni ìwọ ó dá ní ẹ̀bi.
Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,
    èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”
    ni Olúwa wí.

Ìpè sí àwọn tí òrùngbẹ n gbẹ

55 (J)“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ,
    ẹ wá sí ibi omi;
àti ẹ̀yin tí kò ní owó;
    ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!
Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà
    láìsí owó àti láìdíyelé.
Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà
    àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?
Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
(K)Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi
    gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè.
Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ,
    ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.
Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,
    olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.
Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀
    àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,
Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ
    Ẹni Mímọ́ Israẹli
    nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”

Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;
    ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.
Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀
    àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,
    àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.

“Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,
    tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,”
    ni Olúwa wí.
“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,
    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ
    àti èrò mi ju èrò yín lọ.
10 (L)Gẹ́gẹ́ bí òjò àti yìnyín
    ti wálẹ̀ láti ọ̀run
tí kì í sì padà sí ibẹ̀
    láì bomirin ilẹ̀
kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi,
    tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìn
    àti àkàrà fún ọ̀jẹun,
11 bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá;
    kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,
ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́,
    yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.
12 Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀
    a ó sì darí i yín lọ ní àlàáfíà;
òkè ńláńlá àti kéékèèkéé
    yóò bú sí orin níwájú yín
àti gbogbo igi inú pápá
    yóò máa pàtẹ́wọ́.
13 Dípò igi ẹ̀gún ni igi junifa yóò máa dàgbà,
    àti dípò ẹ̀wọ̀n, maritili ni yóò yọ.
Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa,
    fún ààmì ayérayé,
    tí a kì yóò lè parun.”

2 Tẹsalonika 1

(A)Paulu, Sila àti Timotiu,

Sí ìjọ Tẹsalonika, nínú Ọlọ́run Baba wa àti Jesu Kristi Olúwa:

(B)Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa.

Àdúrà àti ìdúpẹ́

(C)Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín sí ara yín ń di púpọ̀. Nítorí náà, àwa tìkára wa ń fi yín ṣògo nínú ìjọ Ọlọ́run, nítorí sùúrù àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà.

Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé nítorí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà. Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú, Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì ṣe nígbà ìfarahàn Jesu Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn angẹli alágbára. (D)Òun yóò fi ìyà jẹ àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí ń ṣe àìgbọ́ràn sí ìhìnrere Jesu Olúwa wa. A ó fi ìparun àìnípẹ̀kun jẹ wọ́n ní yà, a ó sì ṣe wọn mọ̀ kúrò níwájú Olúwa àti inú ògo agbára rẹ̀ 10 Ní ọjọ́ tí yóò jẹ́ ẹni tí a ó yìn lógo nínú àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ àti ẹni àwòyanu ní àárín gbogbo àwọn tí ó ti gbàgbọ́. Èyí kò yọ yín sílẹ̀, nítorí ẹ ti gba ẹ̀rí tí a jẹ́ sí yín gbọ́.

11 (E)Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. 12 Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.