Old/New Testament
Jeremiah àti Paṣuri
20 Ní ìgbà tí àlùfáà Paṣuri ọmọkùnrin Immeri olórí àwọn ìjòyè tẹmpili Olúwa gbọ́ tí Jeremiah ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí. 2 Ó mú kí wọ́n lù wòlíì Jeremiah, kí wọ́n sì fi sínú túbú tí ó wà ní òkè ẹnu-ọ̀nà ti Benjamini ní tẹmpili Olúwa. 3 (A)Ní ọjọ́ kejì tí Paṣuri tú u sílẹ̀ nínú túbú, Jeremiah sì sọ fún un wí pé, “orúkọ Olúwa fun ọ kì í ṣe Paṣuri bí kò ṣe ìpayà. 4 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Juda lé ọba Babeli lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Babeli tàbí kí ó pa wọ́n. 5 Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀tá wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá ọba Juda. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Babeli. 6 Àti ìwọ Paṣuri, gbogbo ènìyàn inú ilé rẹ yóò sì lọ ṣe àtìpó ní Babeli. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí, tí wọn yóò sì sin ọ́ síbẹ̀, ìwọ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tí ìwọ ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ irọ́ fún.”
Ìráhùn Jeremiah
7 Olúwa, o tàn mí jẹ́,
o sì ṣẹ́gun.
Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́,
gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.
8 Nígbàkúgbà tí mo bá sọ̀rọ̀, èmi sì kígbe síta
èmi á sọ nípa ipá àti ìparun.
Nítorí náà, ọ̀rọ̀ Olúwa ti mú àbùkù
àti ẹ̀gàn bá mi ni gbogbo ìgbà.
9 Ṣùgbọ́n bí mo bá sọ pé, “Èmi kì yóò dárúkọ rẹ
tàbí sọ nípa orúkọ rẹ̀ mọ́,
ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń bẹ bi iná tí ń jó nínú mi
nínú egungun mi
Agara dá mi ní inú mi
nítòótọ́ èmi kò lè ṣe é.
10 Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́,
ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo
Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn!
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró
kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé,
Bóyá yóò jẹ́ di títàn,
nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀,
àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”
11 Ṣùgbọ́n Olúwa ń bẹ pẹ̀lú mi gẹ́gẹ́ bí akọni ẹlẹ́rù.
Nítorí náà, àwọn tí ó ń lépa mi yóò kọsẹ̀,
wọn kì yóò sì borí.
Wọn yóò kùnà, wọn yóò sì gba ìtìjú púpọ̀.
Àbùkù wọn kì yóò sì di ohun ìgbàgbé.
12 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ìwọ tí ó ń dán olódodo wò
tí o sì ń ṣe àyẹ̀wò ọkàn àti ẹ̀mí fínní fínní,
jẹ́ kí èmi kí ó rí ìgbẹ̀san rẹ lórí wọn,
nítorí ìwọ ni mo gbé ara mi lé.
13 Kọrin sí Olúwa!
Fi ìyìn fún Olúwa!
Ó gba ẹ̀mí àwọn aláìní
lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.
14 Ègbé ni fún ọjọ́ tí a bí mi!
Kí ọjọ́ tí ìyá mi bí mi má ṣe di ti ìbùkún.
15 Ègbé ni fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún baba mi,
Tí ó mú kí ó yọ̀, tí ó sì sọ wí pé,
“A bí ọmọ kan fún ọ—ọmọkùnrin!”
16 Kí ọkùnrin náà dàbí ìlú
tí Olúwa gbàkóso lọ́wọ́ rẹ̀ láìkáàánú
Kí o sì gbọ́ ariwo ọ̀fọ̀ ní àárọ̀,
ariwo ogun ní ọ̀sán.
17 Nítorí kò pa mí nínú,
kí ìyá mi sì dàbí títóbi ibojì mi,
kí ikùn rẹ̀ sì di títí láé.
18 Èéṣe tí mo jáde nínú ikùn,
láti rí wàhálà àti ọ̀fọ̀
àti láti parí ayé mi nínú ìtìjú?
Ọlọ́run kọ ìbéèrè Sedekiah sílẹ̀
21 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jeremiah wá nígbà tí ọba Sedekiah rán Paṣuri ọmọ Malkiah àti àlùfáà Sefaniah ọmọ Maaseiah sí i; wọ́n wí pé: 2 “Wádìí lọ́wọ́ Olúwa fún wa nítorí Nebukadnessari ọba Babeli ń kọlù wá. Bóyá Olúwa yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”
3 Ṣùgbọ́n Jeremiah dáhùn wí pé, “Sọ fún Sedekiah, 4 ‘Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá ọba àti àwọn ará Babeli tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí. 5 Èmi gan an yóò sì bá yín jà pẹ̀lú ohun ìjà olóró nínú ìbínú àti ìrunú líle. 6 Èmi yóò sì lu gbogbo ìlú yìí, ènìyàn àti ẹranko, gbogbo wọn ni àjàkálẹ̀-ààrùn yóò kọlù tí wọn yóò sì kú. 7 Olúwa sọ pé lẹ́yìn èyí, èmi yóò fi Sedekiah ọba Juda, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ènìyàn, àti àwọn tí ó kù ní ìlú yìí lọ́wọ́ àjàkálẹ̀-ààrùn àti lọ́wọ́ idà, àti lọ́wọ́ ìyàn; èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́, àti lé ọwọ́ àwọn ọ̀tá wọn, àti lé ọwọ́ àwọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn, òun yóò sì fi ojú idà pa wọ́n, kì yóò sì dá wọn sí, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ní ìyọ́nú tàbí ṣàánú wọn.’
8 “Síwájú sí i, sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó sọ: Wò ó, Èmi ń fi ọ̀nà ìyè àti ikú hàn yín. 9 Ẹnikẹ́ni tí ó bá dúró sí ìlú yìí yóò ti ipa idà, ìyàn tàbí àjàkálẹ̀-ààrùn kú. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jáde tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún àwọn Babeli tí ó ń lépa yín yóò sì yè. Òun yóò sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀. 10 Mo ti pinnu láti jẹ ìlú yìí ní yà, ni Olúwa wí. A ó sì gbé e fún ọba Babeli, yóò sì run ún pẹ̀lú iná.’
11 “Ẹ̀wẹ̀, wí fún ìdílé ọba Juda pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 12 Ilé Dafidi èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa sọ:
“ ‘Ṣe ìdájọ́ tí ó tọ́ ní àràárọ̀;
yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹni tí ó ń ni í lára
ẹni tí a ti jà lólè
bí bẹ́ẹ̀ kọ́ ìbínú mi yóò jáde síta, yóò sì jó bí iná.
Nítorí ibi tí a ti ṣe yóò sì jó
láìsí ẹni tí yóò pa á.
13 Mo kẹ̀yìn sí ọ, Jerusalẹmu
ìwọ tí o gbé lórí àfonífojì
lórí òkúta tí ó tẹ́jú, ni Olúwa wí.
Ìwọ tí o ti wí pé, “Ta ni ó le dojúkọ wá?
Ta ni yóò wọ inú ibùgbé wa?”
14 Èmi yóò jẹ ọ ní ìyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀
ni Olúwa wí.
Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀;
yóò si jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”
4 Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. 2 Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. 3 Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. 4 Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán. 5 Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.
6 Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. 7 Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́; 8 Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀.
Àwọn àkíyèsí ti ara ẹni
9 Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. 10 (A)Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia. 11 Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. 12 Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu. 13 Aṣọ òtútù tí mo fi sílẹ̀ ní Troasi lọ́dọ̀ Karpu, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mú un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ.
14 Aleksanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀: 15 Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀.
16 Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn. 17 Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. 18 Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín.
Àwọn ìkíni ìkẹyìn
19 Kí Priska àti Akuila, àti ilé Onesiforu.
20 Erastu wà ní Kọrinti: ṣùgbọ́n mo fi Tirofimu sílẹ̀ ni Miletu nínú àìsàn. 21 Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù.
Eubulu kí ọ, àti Pudeni, àti Linu, Klaudia, àti gbogbo àwọn arákùnrin.
22 Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.