Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 23-25

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Tire

23 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Tire:

Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi!
    Nítorí a ti pa Tire run
láìsí ilé tàbí èbúté.
    Láti ilẹ̀ Saipurọsi ni
    ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn.

Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù
    àti ẹ̀yin oníṣòwò ti Sidoni,
    ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀.
Láti orí àwọn omi ńlá
    ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá
ìkórè ti odò Naili ni owóòná Tire,
    òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún
    àwọn orílẹ̀-èdè.

Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ Sidoni àti ìwọ
    àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun,
nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀:
    “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí
Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin
    tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.”
Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé Ejibiti,
    wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa
    ìròyìn láti Tire.

Kọjá wá sí Tarṣiṣi;
    pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù.
Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín,
    ògbólógbòó ìlú náà,
èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ
    láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré.
Ta ló gbèrò èyí sí Tire,
    ìlú aládé,
àwọn oníṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé
    tí àwọn oníṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká
    ní orílẹ̀ ayé?
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀,
    láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba
àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá
    ilé ayé sílẹ̀.

10 Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò Ejibiti,
    Ìwọ ọmọbìnrin Tarṣiṣi,
    nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́.
11 Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun
    ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì.
Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan Kenaani
    pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run.
12 Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́”
    ìwọ wúńdíá ti Sidoni, tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí!

“Gbéra, rékọjá lọ sí Saipurọsi,
    níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.”
13 Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli,
    àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí
Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di
    ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù;
wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè,
    wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò
    wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.

14 Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
    wọ́n ti pa odi rẹ̀ run!

15 Ní àkókò náà a ó gbàgbé Tire fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí Tire gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè:

16 “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú,
    Ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé;
lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin,
    kí a lè ba à rántí rẹ.”

17 (B)Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá Tire jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé. 18 Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

Ìparun Olúwa lórí ilẹ̀ ayé

24 Kíyèsi i, Olúwa yóò sọ ohun
    gbogbo dòfo ní ilẹ̀ ayé
yóò sì pa á run
    òun yóò pa ojú u rẹ̀ rẹ́
    yóò sì fọ́n àwọn olùgbé ibẹ̀ káàkiri—
bákan náà ni yóò sì rí
    fún àlùfáà àti àwọn ènìyàn,
fún ọ̀gá àti ọmọ ọ̀dọ̀,
    fún ìyá-ilé àti ọmọbìnrin,
fún olùtà àti olùrà,
    fún ayáni àti atọrọ
    fún ayánilówó àti onígbèsè.
Ilé ayé ni a ó sọ di ahoro pátápátá
    a ó sì jẹ gbogbo rẹ̀ run.
    Olúwa ni ó ti sọ ọ̀rọ̀ yìí.

Ilẹ̀ ayé ti gbẹ ó sì sá,
    ayé ń ṣòjòjò, àárẹ̀ mú un,
    àwọn ẹni gíga ilẹ̀ ayé wà nínú ìpọ́njú
àwọn ènìyàn ayé ti bà á jẹ́;
    wọ́n ti pa àwọn òfin run
wọ́n ṣe lòdì sí àwọn ìlànà
    wọ́n sì ti ba májẹ̀mú ayérayé jẹ́.
Nítorí náà, ègún kan ti jẹ ayé run;
    àwọn ènìyàn rẹ̀ ní láti ru ẹ̀bi wọn.
Nítorí náà, àwọn olùgbé ayé ti gbiná dànù,
    àwọn ẹ̀tàhóró ló sì kù.
Wáìnì tuntun ti gbẹ, àjàrà sì ti rọ,
    gbogbo àwọn aláríyá sì kérora.
(C)Àríyá ti ṣaworo ti dákẹ́
    ariwo àwọn tí ń ṣàjọyọ̀ ti dáwọ́ dúró
    ayọ̀ dùùrù ti dákẹ́ jẹ́ẹ́.
Kò ṣe é ṣe fún wọn láti máa mu wáìnì pẹ̀lú orin kíkọ mọ́
    ọtí líle ti di ìkorò fún àwọn ọ̀mu.
10 Ìlú tí a run ti dahoro,
    ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé kọ̀ọ̀kan ni a dí pa.
11 Ní òpópónà ni wọ́n ti ń kígbe fún wáìnì
    gbogbo ayọ̀ ọ wọn ti di ìbànújẹ́,
    gbogbo àríyá ni a lé kúrò lórí ilẹ̀ ayé.
12 Ìlú ni a ti fi sílẹ̀ ní ahoro,
    ìlẹ̀kùn rẹ̀ ni a sì tì pa bámú bámú.
13 Bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí ní orí ilẹ̀ ayé
    àti láàrín àwọn orílẹ̀-èdè pẹ̀lú,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a lu igi olifi,
    tàbí gẹ́gẹ́ bí i pàǹtí tí ó ṣẹ́kù lẹ́yìn
    tí a kórè èso tán.

14 Wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì hó fún ayọ̀;
    láti ìwọ̀-oòrùn ni wọn yóò ti polongo
    ọláńlá Olúwa.
15 Nítorí náà ní ìlà-oòrùn ẹ fi ògo fún Olúwa;
    gbé orúkọ Olúwa ga, àní
Ọlọ́run Israẹli,
    ní àwọn erékùṣù ti inú Òkun,
16 Láti òpin ayé wá ni a ti gbọ́ orin;
    “Ògo ni fún olódodo n nì.”
    Ṣùgbọ́n mo wí pé, “Mo ṣègbé, mo ṣègbé!

“Ègbé ni fún mi!
    Alárékérekè dalẹ̀!
    Pẹ̀lú ìhàlẹ̀ ni àgàbàgebè fi dalẹ̀!”
17 Ìpayà, isà òkú, àti ìdẹ̀kùn ń dúró dè ọ́,
    ìwọ ènìyàn ilẹ̀ ayé.
18 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá nítorí ariwo ìpayà
    yóò ṣubú sínú ihò,
ẹnikẹ́ni tí ó bá sì yọ́ jáde nínú ihò
    ni ìdẹ̀kùn yóò gbámú.

Ibodè ọ̀run ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀
    Ìpìlẹ̀ ayé mì tìtì.
19 Ilẹ̀ ayé ti fọ́
    ilẹ̀ ayé ti fọ́ dànù,
    a ti mi ilẹ̀ ayé rìrìrìrì.
20 Ilẹ̀ ayé yí gbiri bí ọ̀mùtí,
    ó bì síwá sẹ́yìn bí ahéré nínú afẹ́fẹ́;
Ẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ ń pa á lẹ́rù
    tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣubú láìní lè dìde mọ́.

21 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò jẹ ẹ́ ní yà
    gbogbo agbára tí ó wà lókè lọ́run
    àti àwọn ọba tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé.
22 A ó sì kó wọn jọ pọ̀,
    gẹ́gẹ́ bí ará túbú jọ sínú ihò,
a ó tì wọ́n mọ́ inú túbú,
    a ó sì bẹ̀ wọ́n wò lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́.
23 A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn;
    nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba
ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu,
    àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.

Ẹ yin Olúwa

25 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi;
    Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì
fi ìyìn fún orúkọ rẹ
    nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́
o ti ṣe ohun ńlá,
    àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.
Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,
    ìlú olódi ti di ààtàn,
ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;
    a kì yóò tún un kọ́ mọ́.
Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò
    bọ̀wọ̀ fún ọ;
àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú
    yóò bu ọlá fún ọ.
Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì
    ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀
ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì
    bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.
Nítorí pé èémí àwọn ìkà
    dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri
àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù.
    O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,
gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù,
    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    yóò ti pèsè
àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn
    àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́
ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì
    tí ó gbámúṣé.
Ní orí òkè yìí ni yóò pa
    aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,
    abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀;
(D)Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.
    Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,
kúrò ní ojú gbogbo wọn;
    Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò
ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
    Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,

    “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;
àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.
    Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,
    ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”
10 (E)Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí
    ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;
    gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.
11 Wọn yóò na ọwọ́ wọn jáde nínú rẹ̀,
    gẹ́gẹ́ bí òmùwẹ̀ tí ń na ọwọ́ rẹ̀
jáde láti lúwẹ̀ẹ́.
    Ọlọ́run yóò mú ìgbéraga wọn wálẹ̀
    bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣeféfé wà ní ọwọ́ wọn.
12 Òun yóò sì bi gbogbo ògiri gíga alágbára yín lulẹ̀
    wọn yóò sì wà nílẹ̀
Òun yóò sì mú wọn wá si ilẹ̀,
    àní sí erùpẹ̀ lásán.

Filipi 1

(A)Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi.

Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì.

(B)Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi.

Àdúrà àti Ọpẹ́

Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín: Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìhìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí. (C)Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé:

(D)Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìhìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi. Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.

Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, 10 kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi: 11 Lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

Ìrírí Paulu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́

12 (E)Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi jásí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìhìnrere. 13 (F)Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi. 14 Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

15 Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é. 16 Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi: 17 Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìhìnrere. 18 Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí.

Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀, 19 (G)nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi, 20 (H) Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú. 21 (I)Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. 22 Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. 23 Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: 24 Síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. 25 Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, 26 kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.

27 Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan; 28 (J)Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe ààmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. 29 Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú: 30 (K)Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.