Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 20-22

Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Ejibiti àti Kuṣi

20 Ní ọdún tí olórí ogun, tí Sagoni ọba Asiria rán an, wá sí Aṣdodu, ó kọlù ú ó sì kó o— ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.

Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí ààmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ọba Asiria yóò kó àwọn ìgbèkùn Ejibiti lọ ní ìhòhò àti láì wọ bàtà pẹ̀lú àwọn àtìpó Kuṣi, ọ̀dọ́ àti àgbà, pẹ̀lú ìbàdí ìhòhò—bí àbùkù Ejibiti. Gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Kuṣi tí wọ́n sì ń fi Ejibiti yangàn ni ẹ̀rù yóò dé bá tí a ó sì dójútì wọ́n. Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn tí ó ń gbé ní etí Òkun yóò wí pé, ‘Wo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ti gbẹ́kẹ̀lé, àwọn tí a sá tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ láti ọwọ́ ọba Asiria! Báwo ni a ó ṣe sálà?’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Babeli

21 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan aginjù lẹ́bàá Òkun:

Gẹ́gẹ́ bí ìjì líle ti í jà kọjá ní gúúsù,
    akógunjàlú kan wá láti aginjù,
    láti ilẹ̀ ìpayà.

Ìran tí a ń fojú ṣọ́nà fún ni a ti fihàn mí
    ọlọ̀tẹ̀ ti tu àṣírí, fọ́lé fọ́lé ti kẹ́rù.
Elamu kojú ìjà! Media ti tẹ̀gùn!
    Èmi yóò mú gbogbo Ìpayínkeke dópin,
ni ó búra.

Pẹ̀lú èyí, ìrora mu mi lára gírígírí,
    ìrora gbá mi mú, gẹ́gẹ́ bí i ti
obìnrin tí ń rọbí,
    Mo ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nítorí ohun tí mo gbọ́,
    ọkàn mi pòruurù nípa ohun tí mo rí.
Ọkàn mí dàrú,
    ẹ̀rù mú jìnnìjìnnì bá mi,
ìmọ́lẹ̀ tí mo ti ń fẹ́ ẹ́ rí
    ti wá di ìpayà fún mi.

Wọ́n tẹ́ tábìlì,
    wọ́n tẹ́ ẹní àtẹ́ẹ̀ká,
wọ́n jẹ, wọ́n mu!
    Dìde nílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ-aládé,
    ẹ fi òróró kún asà yín!

Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:

“Lọ, kí o bojúwòde
    kí o sì wá sọ ohun tí ó rí.
Nígbà tí ó bá rí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
    àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin,
àwọn tó ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
    tàbí àwọn tí ó gun ìbákasẹ,
jẹ́ kí ó múra sílẹ̀,
    àní ìmúra gidigidi.”

Òun sì kígbe pé, kìnnìún kan;

“Láti ọjọ́ dé ọjọ́, olúwa mi, mo dúró lórí ilé ìṣọ́ ní ọ̀sán,
    a sì fi mí ìṣọ́ mi ní gbogbo òru.
Wò ó, ọkùnrin kan ni ó ń bọ̀ wá yìí
    nínú kẹ̀kẹ́ ogun
àti àkójọpọ̀ àwọn ẹṣin.
    Ó sì mú ìdáhùn padà wá:
‘Babeli ti ṣubú, ó ti ṣubú!
    Gbogbo àwọn ère òrìṣà rẹ̀
    ló fọ́nká sórí ilẹ̀!’ ”

10 Ẹ̀yin ènìyàn mi, tí a gún mọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ ìpakà,
    mo sọ ohun tí mo ti gbọ́
láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Israẹli.

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Edomu

11 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Dumahi:

Ẹnìkan ké sí mi láti Seiri wá
    “Alóre, kí ló kù nínú òru náà?”
12 Alóre náà dáhùn wí pé,
    “Òwúrọ̀ súnmọ́ tòsí, àti òru náà pẹ̀lú.
Bí ìwọ yóò bá béèrè, béèrè
    kí o sì tún padà wá.”

Àsọtẹ́lẹ̀ tó lòdì sí Arabia

13 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Arabia:

Ẹ̀yin ẹgbẹ́ èrò ti Dedani,
    tí ó pàgọ́ sínú igbó Arabia,
14 gbé omi wá fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ;
    ẹ̀yin tí ó ń gbé Tema,
    gbé oúnjẹ wá fún àwọn ìsáǹsá.
15 Wọ́n sá kúrò lọ́wọ́ idà,
    kúrò lọ́wọ́ idà tí a fàyọ,
kúrò lọ́wọ́ ọrun tí a fàyọ
    àti kúrò nínú ìgbóná ogun.

16 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Láàrín ọdún kan, gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ọgbà, í ti í kà á, gbogbo ògo Kedari yóò wá sí òpin. 17 Àwọn tafàtafà tí ó sálà, àwọn jagunjagun Kedari kò ní tó nǹkan.” Olúwa, Ọlọ́run Israẹli ni ó ti sọ̀rọ̀.

Àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Jerusalẹmu

22 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó jẹ mọ́ Àfonífojì ìran:

Kí ni ó ń dààmú yín báyìí,
    tí gbogbo yín fi gun orí òrùlé lọ?
Ìwọ ìlú tí ó kún fún rúkèrúdò,
    ìwọ ìlú àìtòrò òun rògbòdìyàn
a kò fi idà pa àwọn òkú rẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni wọn kò kú ní ojú ogun.
Gbogbo àwọn olórí i yín ti jùmọ̀ sálọ;
    a ti kó wọn nígbèkùn láìlo ọfà.
Ẹ̀yin tí a mú ni a ti kó lẹ́rú papọ̀,
    lẹ́yìn tí ẹ ti sá nígbà tí ọ̀tá ṣì wà
    lọ́nà jíjìn réré.
Nítorí náà ni mo wí pé, “Yípadà kúrò lọ́dọ̀ mi:
    jẹ́ kí n sọkún kíkorò.
Má ṣe gbìyànjú àti tù mí nínú
    nítorí ìparun àwọn ènìyàn mi.”

Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ọjọ́ kan
    tí rúkèrúdò, rògbòdìyàn àti ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀
    ní Àfonífojì ìmọ̀,
ọjọ́ tí a ń wó ògiri lulẹ̀
    àti sísun ẹkún lọ sí àwọn orí òkè.
Elamu mú apó-ọfà lọ́wọ́,
    pẹ̀lú àwọn agun-kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹṣin,
    Kiri yọ àpáta rẹ̀ síta.
Àyànfẹ́ Àfonífojì rẹ kún fún kẹ̀kẹ́ ogun,
    àwọn ẹlẹ́ṣin ni a gbá jọ sí ẹnu-bodè ìlú.

Gbogbo ààbò Juda ni a ti ká kúrò.
Ìwọ sì gbójú sókè ní ọjọ́ náà
    sí àwọn ohun ìjà ní ààfin ti inú aginjù,
Ìwọ rí i pé ìlú u Dafidi
    ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ààyè níbi ààbò rẹ̀,
ìwọ ti tọ́jú omi
    sínú adágún ti ìsàlẹ̀.
10 Ìwọ ka àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu
    ó sì wó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé lulẹ̀ láti fún ògiri lágbára.
11 Ìwọ mọ agbemi sí àárín ògiri méjì
    fún omi inú adágún àtijọ́,
ṣùgbọ́n ìwọ kò wo ẹni tí ó ṣe é tẹ́lẹ̀
    tàbí kí o kọbi ara sí ẹni tí ó
    gbèrò rẹ̀ ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.

12 Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    pè ọ́ ní ọjọ́ náà
láti sọkún kí o sì pohùnréré,
    kí o tu irun rẹ dànù kí o sì
    da aṣọ ọ̀fọ̀ bora.
13 Ṣùgbọ́n Wò ó, ayọ̀ àti ayẹyẹ wà
    màlúù pípa àti àgùntàn pípa,
ẹran jíjẹ àti ọtí wáìnì mímu!
    “Jẹ́ kí a jẹ kí a mu,” ni ẹ̀yin wí,
    “nítorí pé lọ́la àwa ó kú!”

14 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ èyí di mí mọ̀ létí ì mi: “Títí di ọjọ́ ikú yín a kò ní ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yìí,” ni Olúwa wí, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

15 Èyí ni ohun tí Olúwa, àní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:

Lọ, sọ fún ìríjú yìí pé,
    fún Ṣebna, ẹni tí ààfin wà ní ìkáwọ́ rẹ̀:
16 Kí ni ohun tí ò ń ṣe níhìn-ín-yìí àti pé
    ta ni ó sì fún ọ ní àṣẹ
láti gbẹ́ ibojì kan fún ara rẹ níhìn-ín-yìí,
    tí ó gbẹ́ ibojì ní ibi gíga
    tí ó sì gbẹ́ ibi ìsinmi rẹ nínú àpáta?

17 “Kíyèsára, Olúwa fẹ́ gbá ọ mú gírígírí
    kí ó sì jù ọ́ nù, Ìwọ ọkùnrin alágbára.
18 Òun yóò ká ọ rúgúdù bí i òkìtì
    yóò sì sọ ọ́ sí orílẹ̀-èdè ńlá kan.
Níbẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí
    àti níbẹ̀ pẹ̀lú ni àwọn kẹ̀kẹ́ ogun
àràmọ̀ǹdà rẹ yóò wà—
    ìwọ di ìtìjú sí ilé ọ̀gá rẹ!
19 Èmi yóò yọ ọ́ kúrò ní ipò rẹ,
    a ó sì lé ọ kúrò ní ipò rẹ.

20 “Ní ọjọ́ náà. Èmi yóò ké sí ọmọ ọ̀dọ̀ mi, Eliakimu ọmọ Hilkiah. 21 Èmi yóò fi aṣọ rẹ wọ̀ ọ́, n ó sì so ẹ̀wọ̀n rẹ mọ́ ọn ní ọrùn, èmi ó sì gbé àṣẹ rẹ lé e lọ́wọ́. Òun yó sì jẹ́ baba fún gbogbo olùgbé e Jerusalẹmu àti fún ilé e Juda. 22 (A)Èmi yóò sì fi kọ́kọ́rọ́ ilé e Dafidi lé e ní èjìká; ohunkóhun tí ó bá ṣí, ẹnikẹ́ni kì yóò lè ti, ohunkóhun tí ó bá sì tì, ẹnikẹ́ni kì yóò le è ṣí. 23 Èmi yóò sì kàn mọ́lẹ̀ bí èèkàn tí ó dúró gírígírí ní ààyè e rẹ̀; òun yóò sì jẹ́ ibùjókòó ọlá fún ilé baba rẹ̀. 24 Gbogbo ògo ìdílé rẹ̀ ni wọn yóò sì fi kọ ní ọrùn: ìran rẹ̀ àti àrọ́mọdọ́mọ rẹ̀, gbogbo ohun èlò ife, títí dé orí ago ọtí.

25 “Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Èèkàn tí a kàn mọ́lẹ̀ gírígírí ní ààyè e rẹ̀ yóò yẹrí, yóò dẹ̀gbẹ́ yóò sì fẹ̀gbẹ́ lélẹ̀ àti ẹrù tí ó létéńté lórí i rẹ̀ ni a ó gé lulẹ̀.” Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

Efesu 6

Àwọn ọmọ àti àwọn òbí

Ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbọ́ tí àwọn òbí i yín nínú Olúwa: nítorí pé èyí ní ó tọ́. (A)“Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ,” èyí tí í ṣe òfin kìn-ín-ní pẹ̀lú ìlérí, (B)“ki ó lé dára fún ọ, àti kí ìwọ lè wà pẹ́ ní ayé.”

Àti ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe mú àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Olúwa.

Àwọn ẹrú àti olówó wọn

Ẹ̀yin ọmọ ọ̀dọ̀, ẹ máa gbọ́ ti àwọn olúwa yín nípá ti ara, pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ìwárìrì, nínú òtítọ́ ọkàn yín, bí ẹni pé sí Kristi. Gbọ́ ọ̀rọ̀ sí wọn lẹ́nu kì í ṣe láti rí ojúrere wọn nígbà tí ojú wọn bá ń bẹ lára rẹ, ṣùgbọ́n bí ẹrú Kristi, ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti inú ọkàn rẹ. Ẹ máa fi gbogbo ọkàn yin ṣe iṣẹ́ ìsìn bí sí Olúwa, kì í sí ṣe sí ènìyàn. Bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé ohun rere tí olúkúlùkù bá ṣe òun náà ní yóò sí gbà padà lọ́dọ̀ Olúwa, ìbá à ṣe ẹrú, tàbí òmìnira.

Àti ẹ̀yin ọ̀gá, ẹ máa ṣe irú ìtọ́jú kan náà sí àwọn ẹrú yin, ẹ máa dín ìbẹ̀rù yín kù bí ẹ̀yin ti mọ̀ pé Olúwa ẹ̀yin tìkára yín ń bẹ ní ọ̀run; kò sì ṣí ojúsàájú ènìyàn lọ́dọ̀ rẹ̀.

Ìhámọ́ra Ọlọ́run

10 Ní àkótán, ara mí, ẹ jẹ́ alágbára nínú Olúwa, àti nínú agbára ipá rẹ̀. 11 Ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè kọ ojú ìjà sí àrékérekè èṣù. 12 Nítorí pé kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ àti ẹran-ara ní àwa ń bá jìjàkadì, ṣùgbọ́n àwọn ìjòyè, àwọn ọlọ́lá, àwọn aláṣẹ ìbí òkùnkùn ayé yìí, àti àwọn ẹ̀mí búburú ní ojú ọ̀run. 13 Nítorí náà, ẹ gbé gbogbo ìhámọ́ra Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ̀yin lè dúró tiiri sí ọjọ́ ibi, nígbà tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ohun gbogbo tan kí ẹ sì dúró. 14 (C)Ẹ dúró nítorí náà lẹ́yìn tí ẹ fi àmùrè òtítọ́ dì ẹ̀gbẹ́ yin, tí ẹ sì ti di ìgbàyà òdodo mọ́ra. 15 (D)Tí ẹ sì ti fi ìmúra ìhìnrere àlàáfíà wọ ẹsẹ̀ yín ní bàtà. 16 Ní àfikún, ẹ mú apata ìgbàgbọ́, nípa èyí tí ẹ̀yin lè máa fi paná gbogbo ọfà iná ẹni ibi náà. 17 Kí ẹ sì mú àṣíborí ìgbàlà, àti idà ẹ̀mí, tí í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

18 Pẹ̀lú gbogbo àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ ni kí ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo nínú Ẹ̀mí, kí ẹ sì máa ṣọ́ra sí i nínú ìdúró ṣinṣin gbogbo àti ẹ̀bẹ̀ fún gbogbo ènìyàn mímọ́. 19 Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún mí pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè fún mí ní ọ̀rọ̀ tí ó yẹ kí èmi lè máa fì ìgboyà sọ àwọn ohun ìjìnlẹ̀ ìhìnrere náà. 20 Nítorí èyí tí èmí jẹ́ ikọ̀ nínú ẹ̀wọ̀n: kí èmi lè máa fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mí láti máa sọ.

Àwọn ìkíni ìkẹyìn

21 (E) Tikiku, arákùnrin olùfẹ́ àti ìránṣẹ́ olóòtítọ́ nínú Olúwa yóò sọ ohun gbogbo dí mí mọ̀ fún yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè mọ̀ bí nǹkan ti rí fún mí àti bí mo tí ń ṣe sí. 22 Ẹni tí mo rán sí yín nítorí èyí náà, kí ẹ lè mọ̀ bí a tí wà, kì òun lè tu ọkàn yín nínú.

23 Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jesu Kristi.

24 Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa wa Jesu Kristi ni àìṣẹ̀tàn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.