Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 56-58

Ìgbàlà fún àwọn mìíràn

56 Èyí ni ohun ti Olúwa sọ:

“Ẹ pa ìdájọ́ mọ́
    ẹ sì ṣe ohun tí ó tọ̀nà,
nítorí ìgbàlà mi súnmọ́ tòsí
    àti òdodo mi ni a ó fihàn láìpẹ́ jọjọ.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣe èyí,
    àti fún ọmọ ènìyàn tí ó dìímú ṣinṣin,
tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́,
    tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi ṣíṣe.”

Má ṣe jẹ́ kí àjèjì kan tí ó ti di ara rẹ̀
    mọ́ Olúwa sọ wí pé,
Olúwa yóò yà mí sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”
Àti kí ìwẹ̀fà kan ṣe àròyé pé,
    “Igi gbígbẹ lásán ni mí.”

Nítorí pé báyìí ni Olúwa wí:

“Sí àwọn ìwẹ̀fà yìí tí ó pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́,
    tí wọ́n yan ohun tí ó dùn mọ́ mi
    tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin
fún wọn ni Èmi yóò fún nínú tẹmpili àti àgbàlá rẹ̀
    ìrántí kan àti orúkọ kan
tí ó sàn ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin
    Èmi yóò fún wọn ní orúkọ ayérayé
    tí a kì yóò ké kúrò.
Àti àwọn àjèjì tí ó so ara wọn mọ́ Olúwa
    láti sìn ín,
láti fẹ́ orúkọ Olúwa
    àti láti foríbalẹ̀ fún un
gbogbo àwọn tí ń pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ láì bà á jẹ́
    àti tí wọ́n sì di májẹ̀mú mi mú ṣinṣin—
(A)àwọn wọ̀nyí ni èmi yóò mú wá òkè mímọ́ mi,
    èmi ó sì fún wọn ní ayọ̀ nínú ilé àdúrà mi.
Ẹbọ sísun wọn àti ìrúbọ wọn,
    ni a ó tẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi;
nítorí a ó máa pe ilé mi ní
    ilé àdúrà fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”
Olúwa Olódùmarè sọ wí pé—
    ẹni tí ó kó àwọn àtìpó Israẹli jọ:
“Èmi yóò kó àwọn mìíràn jọ pẹ̀lú wọn
    yàtọ̀ sí àwọn tí a ti kójọ.”

Ẹ̀sùn tí Ọlọ́run fi kan àwọn ìkà

Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin ẹranko inú pápá,
    ẹ wá jẹ àwọn ẹranko inú igbó run!
10 Àwọn olùṣọ́ Israẹli fọ́jú,
    gbogbo wọn ṣe aláìní ìmọ̀;
Gbogbo wọn jẹ́ adití ajá,
    wọn kò lè gbó;
wọ́n sùn sílẹ̀ wọ́n ń lálàá,
    wọ́n fẹ́ràn láti máa sùn.
11 Wọ́n jẹ́ àwọn ajá tí ó kúndùn púpọ̀;
    wọn kì í ní ànító.
Wọ́n jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn tí kò ní òye;
    olúkúlùkù ń yà ṣọ́nà ara rẹ̀,
    ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn sì wá ère tirẹ̀.
12 “Wá,” ni igbe ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, “fún mi ní ọtí wáìnì!
    Jẹ́ kí a mu ọtí líle wa lámu yó
ọ̀la yóò sì dàbí òní,
    tàbí kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.”

57 Olódodo ṣègbé
    kò sí ẹnìkan tí ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀;
a mú àwọn ẹni mímọ́ lọ,
    kò sì ṣí ẹni tó yé
pé a ti mú àwọn olódodo lọ
    láti yọ wọ́n kúrò nínú ibi.
Gbogbo àwọn tí ń rìn déédé
    ń wọ inú àlàáfíà;
    wọ́n rí ìsinmi bí wọ́n ti ń sùn nínú ikú.

“Ṣùgbọ́n ẹ súnmọ́ ìhìn-ín, ẹ̀yin ọmọ aláfọ̀ṣẹ,
    ẹ̀yin irú-ọmọ panṣágà àti àgbèrè!
Ta ni ó fi ń ṣẹlẹ́yà?
    Ta ni o ń yọ ṣùtì sí
tí o sì yọ ahọ́n síta?
    Ẹ̀yin kì í ha ṣe ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn bí,
    àti ìran àwọn òpùrọ́?
Ẹ gbinájẹ fún ìṣekúṣe láàrín igi óákù
    àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀;
ẹ fi àwọn ọmọ yín rú ẹbọ nínú kòtò jíjìn
    àti lábẹ́ àwọn pàlàpálá òkúta.
Àwọn ère tí ó wà ní àárín òkúta dídán
    wọ́n n nì, nínú kòtò jíjìn ni ìpín in yín;
àwọ̀n ni ìpín in yín.
    Bẹ́ẹ̀ ni, sí wọn ni ẹ ti ta ọrẹ ohun mímu yín sílẹ̀
àti láti ta ọrẹ ìyẹ̀fun.
    Nítorí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó yẹ
    kí n dáwọ́ dúró?
Ìwọ ti ṣe ibùsùn rẹ lórí òkè gíga tí ó rẹwà;
    níbẹ̀ ni ẹ lọ láti lọ ṣe ìrúbọ yín.
Lẹ́yìn àwọn ìlẹ̀kùn yín àti òpó ìlẹ̀kùn yín
    níbẹ̀ ni ẹ fi àwọn ààmì òrìṣà yín sí.
Ní kíkọ̀ mí sílẹ̀, ẹ ṣí ibùsùn yín sílẹ̀,
    ẹ gun orí rẹ̀ lọ, ẹ sì ṣí i sílẹ̀ gbagada;
ẹ ṣe àdéhùn pẹ̀lú àwọn tí ẹ fẹ́ràn ibùsùn wọn,
    ẹ̀yin sì ń wo ìhòhò wọn.
Ẹ̀yin lọ sí Moleki pẹ̀lú òróró olifi
    ẹ sì fi kún òórùn dídùn yín.
Ẹ rán ikọ̀ yín lọ jìnnà réré;
    ẹ sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú!
10 Àwọn ọ̀nà yín gbogbo ti mú àárẹ̀ ba á yín,
ṣùgbọ́n ẹ kò ní sọ pé, ‘kò sí ìrètí mọ́?’
    Ẹ rí okun kún agbára yín,
    nípa bẹ́ẹ̀ òòyì kò kọ́ ọ yín.

11 “Ta ni ó ń pá yín láyà tí ń bà yín lẹ́rù
    tí ẹ fi ń ṣèké sí mi,
àti tí ẹ̀yin kò fi rántí mi
    tàbí kí ẹ rò yí nínú ọkàn yín?
Ǹjẹ́ kì í ṣe nítorí dídákẹ́ jẹ́ẹ́ mi fún ìgbà pípẹ́
    tí ẹ̀yin kò fi bẹ̀rù mi?
12 Èmi yóò ṣí òdodo yín páyà àti iṣẹ́ yín,
    wọn kì yóò sì ṣe yín ní àǹfààní.
13 Nígbà tí ẹ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́
    ẹ jẹ́ kí àkójọ àwọn ère yín gbà yín!
Atẹ́gùn yóò gbá gbogbo wọn lọ,
    èémí lásán làsàn ni yóò gbá wọn lọ.
Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi mí ṣe ààbò rẹ̀
    ni yóò jogún ilẹ̀ náà
    yóò sì jogún òkè mímọ́ mi.”

Ìtùnú fún àwọn oníròbìnújẹ́

14 A ó sì sọ wí pé:

“Tún mọ, tún mọ, tún ọ̀nà náà ṣe!
    Ẹ mú àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ kúrò ní ọ̀nà àwọn ènìyàn mi.”
15 (B)Nítorí èyí ni ohun tí Ẹni gíga àti ọlọ́lá jùlọ wí
    ẹni tí ó wà títí láé, tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́:
“Mo ń gbé ní ibi gíga àti ibi mímọ́,
    ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹni n nì tí ó ní ìròbìnújẹ́ àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀,
láti sọ ẹ̀mí onírẹ̀lẹ̀ náà jí
    àti láti sọ ẹ̀mí oníròbìnújẹ́ n nì jí.
16 Èmi kì yóò fẹ̀sùn kan ni títí láé,
    tàbí kí n máa bínú sá á,
nítorí nígbà náà ni ọkàn ènìyàn yóò
    rẹ̀wẹ̀sì níwájú mi
    èémí ènìyàn tí mo ti dá.
17 Inú bí mi nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀kánjúwà rẹ̀;
    mo fìyà jẹ ẹ́, mo sì fojú mi pamọ́ ní ìbínú
    síbẹ̀, ó tẹ̀síwájú nínú tinú-mi-ni n ó ṣe ọ̀nà rẹ̀.
18 Èmi ti rí ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ṣùgbọ́n Èmi yóò wò ó sàn;
    Èmi yóò tọ́ ọ ṣọ́nà n ó sì mú ìtùnú tọ̀ ọ́ wá,
19 (C)ní dídá ìyìn sí ètè àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Israẹli.
    Àlàáfíà, àlàáfíà fún àwọn tí ó wà lókèèrè àti nítòsí,”
    ni Olúwa wí, “Àti pé Èmi yóò wo wọ́n sàn.”
20 Ṣùgbọ́n àwọn ìkà dàbí i ríru Òkun
    tí kò le è sinmi,
    tí ìgbì rẹ̀ ń rú pẹ̀tẹ̀pẹ́tẹ̀ àti ẹrọ̀fọ̀ sókè.
21 “Kò sí àlàáfíà,” ni Ọlọ́run mi wí, “fún àwọn ìkà.”

Àwẹ̀ tòótọ́

58 “Kígbe rẹ̀ sókè, má ṣe fàsẹ́yìn.
    Gbé ohùn rẹ sókè bí i ti fèrè.
Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún àwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọn
    àti fún ilé Jakọbu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;
    wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,
àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nà
    tí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.
Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkan
    wọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.
‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí,
    ‘tí ìwọ kò sì tí ì rí?
Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,
    tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’

“Síbẹ̀síbẹ̀ ní ọjọ́ àwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yín
    ẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.
Àwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,
    àti lílu ọmọnìkejì ẹni pa pẹ̀lú ìkùùkuu.
Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìí
    kí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.
Ǹjẹ́ èyí ha ni irú àwẹ̀ tí mo yàn bí,
    ọjọ́ kan ṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?
Ó ha jẹ pe kí ènìyàn tẹ orí rẹ̀ ba bí i koríko lásán ni bí
    àti sísùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?
Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní àwẹ̀ nìyí,
    ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

(D)“Ǹjẹ́ irú àwẹ̀ tí mo ti yàn kọ́ ni èyí:
    láti já gbogbo ẹ̀wọ̀n àìṣòdodo
àti láti tú gbogbo okùn àjàgà,
    láti tú gbogbo àwọn ti à ń ni lára sílẹ̀
    àti láti fọ́ gbogbo àjàgà?
Kì í ha á ṣe láti pín oúnjẹ yín fún àwọn tí ebi ń pa
    àti láti pèsè ibùgbé fún àwọn òtòṣì tí ń rìn káàkiri.
Nígbà tí ẹ bá rí ẹni tí ó wà níhòhò, láti daṣọ bò ó,
    àti láti má ṣe lé àwọn ìbátan yín sẹ́yìn?
Nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ rẹ yóò tàn jáde bí òwúrọ̀
    àti ìmúláradá rẹ yóò farahàn kíákíá;
nígbà náà ni òdodo rẹ yóò sì lọ níwájú rẹ,
    ògo Olúwa yóò sì jẹ́ ààbò lẹ́yìn rẹ.
Nígbà yìí ni ẹ̀yin yóò pè, tí Olúwa yóò sì dáhùn;
    ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́, òun yóò sì wí pé: Èmi nìyí.

“Bí ìwọ bá mú àjàgà aninilára,
    nínà ìka àlébù àti sísọ ọ̀rọ̀ asán kúrò láàrín rẹ,
10 àti bí ẹ̀yin bá ná ara yín bí owó nítorí àwọn tí ebi ń pa
    tí ẹ sì tẹ́ ìfẹ́ àwọn tí à ń ni lára lọ́rùn,
nígbà náà ni ìmọ́lẹ̀ yín yóò ràn nínú òkùnkùn,
    àti òru yín yóò dàbí ọ̀sán gangan.
11 Olúwa yóò máa tọ́ ọ yín nígbà gbogbo;
    òun yóò tẹ́ gbogbo àìní yín lọ́rùn ní ilẹ̀ tí oòrùn ń tan ìmọ́lẹ̀
yóò sì fún egungun rẹ lókun.
    Ìwọ yóò sì dàbí ọgbà tí a bomirin dáradára,
    àti bí orísun tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.
12 Àwọn ènìyàn rẹ yóò tún ahoro àtijọ́ kọ́
    wọn yóò sì gbé ìpìlẹ̀ àtijọ́-tijọ́ ró
a ó sì pè ọ́ ní alátúnṣe ògiri tí ó ti wó
    àti olùmúbọ̀sípò àwọn òpópónà tí ènìyàn gbé inú rẹ̀.

13 “Bí ìwọ bá pa ẹsẹ̀ rẹ mọ́ kúrò nínú bíba ọjọ́ ìsinmi jẹ́,
    àti ṣíṣe bí ó ti wù ọ́ ni ọjọ́ mímọ́ mi,
bí ìwọ bá pe ọjọ-ìsinmi ní ohun dídùn
    àti ọjọ́ mímọ́ Olúwa ní ohun ọ̀wọ̀
àti bí ìwọ bá bu ọlá fún un láti máa bá ọ̀nà tìrẹ lọ
    àti láti má ṣe bí ó ti wù ọ́ tàbí
    kí o máa sọ̀rọ̀ aláìníláárí,
14 nígbà náà ni ìwọ yóò ní ayọ̀ nínú Olúwa rẹ,
    èmi yóò sì jẹ́ kí ìwọ kí ó máa gun ibi gíga ilẹ̀ ayé,
àti láti máa jàdídùn ìní ti
    Jakọbu baba rẹ.”
    Ẹnu Olúwa ni ó ti sọ̀rọ̀.

2 Tẹsalonika 2

Ọkùnrin aláìlófin náà

(A)Ní ti bíbọ̀ Jesu Kristi Olúwa wa, àti ti ìpéjọ wa sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa wí fún yín ará, (B)kí ọkàn yín má ṣe àìbalẹ̀, tàbí kí ẹ má ṣe jáyà nípa àsọtẹ́lẹ̀, ìròyìn tàbí lẹ́tà tí ó lè fi ara jọ èyí tí ó le wá láti ọ̀dọ̀ wa, tí yóò máa wí pé ọjọ́ Olúwa ti dé ná. (C)Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kí ó tàn yín jẹ ní ọ̀nàkọnà, nítorí pé ọjọ́ náà kì yóò dé, bí kò ṣe pé ìṣọ̀tẹ̀ bá kọ́ ṣẹlẹ̀, tí a sì fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, tí í ṣe ọmọ ègbé. (D)Òun yóò lòdì sí, yóò sì gbé ara rẹ̀ ga sí gbogbo ohun tí a ń pè ní Ọlọ́run tàbí tí a ń sìn, dé ibi pé yóò gbé ara rẹ̀ jókòó nínú tẹmpili Ọlọ́run, tí yóò sì pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run.

(E)Ṣé ẹ̀yin kò rántí pé nígbà tí mo wà pẹ̀lú yín, mo ń sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún un yín. Àti pé nísinsin yìí, ẹ̀yin mọ ohun tí ń dá a dúró, kí a bá a lè fi í hàn ní àkókò rẹ̀ gan an. Nítorí agbára ìkọ̀kọ̀ ẹni ẹ̀ṣẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ń dènà yóò máa ṣe bẹ́ẹ̀ títí a ó fi mú un kúrò ní ọ̀nà. (F)Nígbà náà ni a ó fi ẹni ẹ̀ṣẹ̀ hàn, ẹni tí Jesu Olúwa yóò fi èémí ẹnu rẹ̀ pa, tí yóò sì fi ọlá ìpadàbọ̀ rẹ̀ parun. (G)Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Satani, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́ ìyanu, àdàmọ̀dì ààmì àti àdàmọ̀dì idán, 10 Ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà. 11 (H)Nítorí ìdí èyí, Ọlọ́run rán ohun tó ń ṣiṣẹ́ ìṣìnà sí wọn kí wọn lè gba èké gbọ́, 12 kí wọn kí ó lè gba ìdálẹ́bi, àní àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́, ṣùgbọ́n tí wọ́n ní inú dídùn nínú ìwà búburú.

Ẹ dúró ṣinṣin

13 (I)Ṣùgbọ́n, ohun tí ó tọ́ fún wa ni láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ará olùfẹ́ ní ti Olúwa, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín sí ìgbàlà nípa ìsọdimímọ́ ti Ẹ̀mí àti nípa gbígba òtítọ́ gbọ́. 14 Òun ti pè yín sí èyí nípa ìhìnrere wa, kí ẹ̀yin kí ó lè pín nínú ògo Jesu Kristi Olúwa wa.

15 (J)Nítorí náà ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì di àwọn ẹ̀kọ́ wọ̀n-ọn-nì tí a kọ́ yín mú, yálà nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tàbí lẹ́tà.

16 (K)Ǹjẹ́ kí Jesu Kristi Olúwa wa tìkálára rẹ̀, àti Ọlọ́run baba wa, ẹni to ti fẹ́ wa, tí ó sì ti fi ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́ fún wa. 17 Kí ó mú ọkàn yín le, kí ó sì kún yín pẹ̀lú agbára nínú iṣẹ́ gbogbo àti ọ̀rọ̀ rere gbogbo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.