Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 3-5

“Bí ọkùnrin kan bá sì kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀
    tí obìnrin náà sì lọ fẹ́ ọkọ mìíràn,
ǹjẹ́ ọkùnrin náà tún lè tọ̀ ọ́ wá?
    Ǹjẹ́ ilẹ̀ náà kò ní di aláìmọ́ bí?
Ṣùgbọ́n ìwọ ti gbé pẹ̀lú onírúurú panṣágà gẹ́gẹ́ bí olùfẹ́,
    ṣé ìwọ yóò tún padà sọ́dọ̀ mi bí?”
    ni Olúwa wí.
“Gbé ojú rẹ sókè sí ibi gíga wọ̀n-ọn-nì,
    kí o sì wò ó ibi kan ha wà tí a kò bà ọ́ jẹ́?
Ní ojú ọ̀nà, ìwọ jókòó de àwọn olólùfẹ́,
    bí i ará Arabia kan nínú aginjù,
ìwọ sì ti ba ilẹ̀ náà jẹ́
    pẹ̀lú ìwà àgbèrè àti ìwà búburú rẹ.
Nítorí náà, a ti fa ọ̀wààrà òjò sẹ́yìn,
    kò sì ṣí òjò àrọ̀kúrò.
Síbẹ̀ ìwọ ní ojú líle ti panṣágà,
    ìwọ sì kọ̀ láti ní ìtìjú.
Ǹjẹ́ ìwọ kò ha a pè mí láìpẹ́ yìí pé,
    ‘Baba mi, ìwọ ọ̀rẹ́ mi láti ìgbà èwe mi.
Ìwọ yóò ha máa bínú títí?
    Ìbínú rẹ yóò ha máa lọ títí láé?’
Báyìí ni o ṣe ń sọ̀rọ̀
    ìwọ ṣe gbogbo ibi tí ìwọ le ṣe.”

Israẹli aláìṣòótọ́

Ní àkókò ìjọba Josiah ọba, Olúwa wí fún mi pé, “Ṣé o ti rí nǹkan tí àwọn Israẹli aláìnígbàgbọ́ ti ṣe? Wọ́n ti lọ sí àwọn òkè gíga àti sí abẹ́ àwọn igi, wọ́n sì ti ṣe àgbèrè níbẹ̀. Mo rò pé nígbà tí wọ́n ti ṣe èyí wọn yóò padà, wọn kò padà, Juda aláìgbàgbọ́ arábìnrin rẹ̀ náà sì rí i. Mo fún Israẹli aláìnígbàgbọ́ ní ìwé ìkọ̀sílẹ̀, mo sì ké wọn kúrò nítorí gbogbo àgbèrè wọn. Síbẹ̀ mo rí pé Juda tí ó jẹ́ arábìnrin rẹ̀ kò bẹ̀rù, òun náà sì jáde lọ láti lọ ṣe àgbèrè. Nítorí ìwà èérí Israẹli kò jọ ọ́ lójú, ó ti ba ilẹ̀ jẹ́, ó sì ti ṣe àgbèrè pẹ̀lú òkúta àti igi. 10 Látàrí gbogbo nǹkan wọ̀nyí Juda arábìnrin rẹ̀ aláìgbàgbọ́ kò padà tọ̀ mí wá pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀, bí kò ṣe nípa fífarahàn bí olóòtítọ́,” ni Olúwa wí.

11 Olúwa wí fún mi pé, “Israẹli aláìnígbàgbọ́ ṣe òdodo ju Juda tí ó ní ìgbàgbọ́ lọ. 12 Lọ polongo ọ̀rọ̀ náà, lọ sí ìhà àríwá:

“ ‘Yípadà, Israẹli aláìnígbàgbọ́,’ ni Olúwa wí.
    ‘Ojú mi kì yóò korò sí ọ mọ́,
nítorí mo jẹ́ aláàánú, ni Olúwa wí.
    Èmi kì yóò sì bínú mọ́ títí láé
13 Sá à ti mọ ẹ̀bi rẹ,
    ìwọ ti ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ìwọ ti wá ojúrere rẹ lọ́dọ̀ ọlọ́run àjèjì
    lábẹ́ gbogbo igikígi tí ó gbilẹ̀,
ẹ̀yin kò gba ohun mi gbọ́,’ ”
    ni Olúwa wí.

14 “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,” ni Olúwa wí, “nítorí èmi ni ọkọ rẹ. Èmi ó yàn ọ́, ọ̀kan láti ìlú àti méjì láti ẹ̀yà. Èmi ó sì mú ọ wá sí Sioni. 15 Lẹ́yìn èyí, èmi ó fún ọ ní àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti inú ọkàn mi, tí wọn yóò ṣáájú yín pẹ̀lú òye àti ìmọ̀. 16 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, tí ẹ̀yin bá pọ̀ sí i lórí ilẹ̀ náà,” ni Olúwa wí, “àwọn ènìyàn kò tún lè sọ pé, ‘Àpótí ẹ̀rí Olúwa’ kò ní wá sí ìrántí wọn mọ́, a kì yóò pàdánù rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sì tún kan òmíràn mọ́. 17 Ní ìgbà náà, wọn yóò pe Jerusalẹmu ní ìtẹ́ Olúwa gbogbo orílẹ̀-èdè yóò péjọ sí Jerusalẹmu láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ Olúwa, wọn kì yóò sì tún tẹ̀lé àyà líle búburú wọn mọ́. 18 Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì ni ilé Juda yóò darapọ̀ mọ́ ilé Israẹli. Wọn yóò sì wá láti ilẹ̀ àríwá wá sí ilẹ̀ tí mo fi fún àwọn baba ńlá yín gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní.

19 “Èmi fúnra mi sọ wí pé,

“ ‘Báwo ni inú mi yóò ti dùn tó, kí èmi kí ó tọ́ ọ bí ọmọkùnrin
    kí n sì fún ọ ní ilẹ̀ tí ó tó.’
Mo rò pé ìwọ yóò pè mí ní ‘Baba mi’
    o kò sì ní ṣàì tọ̀ mí lẹ́yìn.
20 Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi.
Ìwọ ilé Israẹli”
    ni Olúwa wí.

21 A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga,
    ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli,
nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po,
    wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn.

22 “Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,
    Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.”

“Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ
    nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.
23 Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè
    kéékèèkéé àti àwọn òkè gíga;
Nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run
    wa ni ìgbàlà Israẹli wà.
24 Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti
    jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run,
ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn,
    ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
25 Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,
    kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀.
A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa,
    àwa àti àwọn baba wa,
láti ìgbà èwe wa títí di òní
    a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”

“Tí ìwọ yóò bá yí padà, Ìwọ Israẹli,
    padà tọ̀ mí wá,”
    ni Olúwa wí.
“Tí ìwọ yóò bá sì mú ìríra rẹ kúrò níwájú mi,
    ìwọ kí ó sì rìn kiri.
Tí ó bá jẹ́ lóòtítọ́ àti òdodo ni ìwọ búra.
    Nítòótọ́ bí Olúwa ti wà láààyè,
nígbà náà ni orílẹ̀-èdè yóò di alábùkún fún nípasẹ̀ rẹ,
    àti nínú rẹ̀ ni wọn yóò ṣògo.”
Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún àwọn ènìyàn Juda àti Jerusalẹmu.
    “Hú gbogbo ilẹ̀ tí ẹ kò lò rí,
    kí o má sì ṣe gbìn sáàrín ẹ̀gún.”
Kọ ara rẹ ní ilà sí Olúwa
    kọ ọkàn rẹ ní ilà
ẹ̀yin ènìyàn Juda àti gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu,
    bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ìbínú mi yóò ru jáde yóò sì jó bí iná,
nítorí ibi tí o ti ṣe
    kì yóò sí ẹni tí yóò pa á.

Àjálù láti ilẹ̀ gúúsù

“Kéde ní Juda, kí o sì polongo ní Jerusalẹmu, kí o sì wí pé:
    ‘Fun fèrè káàkiri gbogbo ilẹ̀!’
Kí o sì kígbe:
    ‘Kó ara jọ pọ̀!
    Jẹ́ kí a sálọ sí ìlú olódi.’
Fi ààmì láti sálọ sí Sioni hàn,
    sálọ fún ààbò láìsí ìdádúró.
Nítorí èmi ó mú àjálù láti àríwá wá,
    àní ìparun tí ó burú jọjọ.”

Kìnnìún ti sá jáde láti inú ibùgbé rẹ̀,
    apanirun orílẹ̀-èdè sì ti jáde.
Ó ti fi ààyè rẹ̀ sílẹ̀
    láti ba ilẹ̀ rẹ̀ jẹ́.
Ìlú rẹ yóò di ahoro
    láìsí olùgbé.
Nítorí náà, gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀
    káàánú kí o sì pohùnréré ẹkún,
nítorí ìbínú ńlá Olúwa
    kò tí ì kúrò lórí wa.

“Ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí pé,
    “Àwọn ọba àti ìjòyè yóò pàdánù ẹ̀mí wọn,
àwọn àlùfáà yóò wárìrì,
    àwọn wòlíì yóò sì fòyà.”

10 Nígbà náà ni mo sì wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè, báwo ni ìwọ ti ṣe tan àwọn ènìyàn wọ̀nyí àti Jerusalẹmu jẹ nípa sísọ wí pé, ‘Ìwọ yóò wà ní àlàáfíà,’ nígbà tí o jẹ́ wí pé idà wà ní ọ̀fun wa.”

11 Nígbà náà ni a ó sọ fún Jerusalẹmu àti àwọn ènìyàn pé, “Ẹ̀fúùfù líle láti aṣálẹ̀ fẹ́ lu àwọn ènìyàn mi, kì í ṣe láti sọ di mímọ́. 12 Ẹ̀fúùfù líle tí ó wá láti ọ̀dọ̀ mi. Báyìí mo kéde ìdájọ́ mi lórí wọn.”

13 Wò ó! O ń bọ̀ bí ìkùùkuu
    kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sì wá bí ìjì líle
ẹṣin rẹ̀ sì yára ju idì lọ
    Ègbé ni fún wa àwa parun.
14 Ìwọ Jerusalẹmu, mú búburú kúrò lọ́kàn rẹ kí o sì yè
    Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò mú èrò búburú wà ní ọkàn rẹ?
15 Ohùn kan sì ń kéde ní Dani
    o ń kókìkí ìparun láti orí òkè Efraimu wá.
16 “Sọ èyí fún àwọn orílẹ̀-èdè,
    kéde rẹ̀ fún Jerusalẹmu pé:
‘Ọmọ-ogun ọ̀tá ń bọ̀ láti ilẹ̀ jíjìn wá
    wọ́n sì ń kígbe ogun láti dojúkọ ìlú Juda.
17 Wọ́n yí i ká bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin bá ń ṣọ́ pápá,
    nítorí pé ó ti dìtẹ̀ sí mi,’ ”
    ni Olúwa wí.
18 “Ìwà rẹ àti ìṣe rẹ
    ló fa èyí bá ọ
ìjìyà rẹ sì nìyìí,
    Báwo ló ti ṣe korò tó!
    Báwo ló ti ṣe gún ọkàn rẹ sí!”

19 Háà! Ìrora mi, ìrora mi!
    Mo yí nínú ìrora.
Háà, ìrora ọkàn mi!
    Ọkàn mi lù kìkì nínú mi,
n kò le è dákẹ́.
    Nítorí mo ti gbọ́ ohùn ìpè,
    mo sì ti gbọ́ igbe ogun.
20 Ìparun ń gorí ìparun;
    gbogbo ilẹ̀ náà sì ṣubú sínú ìparun
lọ́gán ni a wó àwọn àgọ́ mi,
    tí ó jẹ́ ohun ààbò mi níṣẹ́jú kan.
21 Yóò ti pẹ́ tó, tí èmi yóò rí ogun
    tí èmi yóò sì gbọ́ ìró fèrè?

22 “Aṣiwèrè ni àwọn ènìyàn mi;
    wọn kò mọ̀ mí.
Wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n ọmọ;
    wọ́n sì jẹ́ aláìlóye.
Wọ́n mọ ibi ni ṣíṣe;
    wọn kò mọ bí a ti í ṣe rere.”

23 Mo bojú wo ayé,
    ó sì wà ní júujùu, ó sì ṣófo
àti ní ọ̀run,
    ìmọ́lẹ̀ wọn kò sì ṣí.
24 Mo wo àwọn òkè ńlá,
    wọ́n wárìrì;
    gbogbo òkè kéékèèkéé mì jẹ̀jẹ̀.
25 Mo wò yíká n kò rí ẹnìkan;
    gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ló ti fò lọ.
26 Mo bojú wò, ilẹ̀ eléso, ó sì di aṣálẹ̀
    gbogbo àwọn ìlú inú rẹ̀ sì ṣubú sínú ìparun
    níwájú Olúwa àti níwájú ríru ìbínú rẹ̀.
27 Èyí ni ohun tí Olúwa
    “Gbogbo ìlú náà yóò sì di ahoro,
    síbẹ̀ èmi kì yóò pa á run pátápátá.
28 Nítorí náà, ayé yóò pohùnréré ẹkún
    àwọn ọ̀run lókè yóò ṣú òòkùn
nítorí mo ti sọ, mo sì ti pète rẹ̀
    mo ti pinnu, n kì yóò sì yí i padà.”

29 Nípa ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin àti àwọn tafàtafà
    gbogbo ìlú yóò sálọ.
Ọ̀pọ̀ sálọ sínú igbó;
    ọ̀pọ̀ yóò sì gun orí àpáta lọ.
Gbogbo ìlú náà sì di ahoro;
    kò sì ṣí ẹnìkan nínú rẹ̀.

30 Kí ni ò ń ṣe, ìwọ tí o ti di ìjẹ tán?
    Ìwọ ìbá wọ ara rẹ ní aṣọ òdodo
kí o sì fi wúrà ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.
    Àwọn olólùfẹ́ rẹ kẹ́gàn rẹ
wọ́n sì ń lépa ẹ̀mí rẹ.

31 Mo gbọ́ ìró kan bí i igbe obìnrin tó ń rọbí,
    tí ó ń rọbí, ìrora bí i abiyamọ
ọmọbìnrin Sioni tí ń pohùnréré ẹkún ara rẹ̀.
    Tí ó na ọwọ́ rẹ̀ tí ó sì wí pé,
“Kíyèsi i mo gbé,
    Nítorí a ti fi ẹ̀mí mi lé àwọn apani lọ́wọ́.”

Kò sí ọ̀kan tí o jẹ́ olóòtítọ́

“Lọ sókè àti sódò àwọn òpópó Jerusalẹmu
    wò yíká, kí o sì mọ̀,
kí o sì wá kiri
    Bí o bá le è rí ẹnìkan,
tí ó jẹ́ olóòtítọ́ àti olódodo,
    n ó dáríjì ìlú yìí.
Bí wọ́n tilẹ̀ wí pé, ‘Bí Olúwa ti ń bẹ,’
    síbẹ̀ wọ́n búra èké.”

Olúwa, ojú rẹ kò ha wà lára òtítọ́
    Ìwọ lù wọ́n, kò dùn wọ́n.
Ìwọ bá wọn wí, wọ́n kọ̀ láti yípadà.
    Wọ́n mú ojú wọn le ju òkúta lọ,
    wọ́n sì kọ̀ láti yípadà.
Èmi sì rò pé, “Tálákà ni àwọn yìí;
    wọn jẹ́ aṣiwèrè,
nítorí pé wọn kò mọ ọ̀nà Olúwa,
    àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.
Nítorí náà, èmi yóò tọ àwọn adarí lọ,
    n ó sì bá wọn sọ̀rọ̀;
ó dájú wí pé wọ́n mọ ọ̀nà Olúwa
    àti ohun tí Ọlọ́run wọn ń fẹ́.”
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan, wọ́n ti ba àjàgà jẹ́,
    wọ́n sì ti já ìdè.
Nítorí náà, kìnnìún láti inú igbó yóò kọlù wọ́n,
    ìkookò aginjù yóò sì pa wọ́n run,
ẹkùn yóò máa ṣe ibùba sí ẹ̀bá ìlú yín
    ẹnikẹ́ni tí ó bá jáde ni yóò fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ,
nítorí àìgbọ́ràn yín pọ,
    ìpadàsẹ́yìn wọn sì pọ̀.

“Kí ni ṣe tí èmi ó ṣe dáríjì ọ́?
    Àwọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mí sílẹ̀
àti pé wọ́n ti fi ọlọ́run tí kì í ṣe Ọlọ́run búra.
    Mo pèsè fún gbogbo àìní wọn,
síbẹ̀ wọ́n tún ń ṣe panṣágà
    wọ́n sì kórajọ sí ilé àwọn alágbèrè.
Wọ́n jẹ́ akọ ẹṣin tí a bọ́ yó,
    tí ó lágbára, wọ́n sì ń sọkún sí aya arákùnrin wọn.
Èmi kì yóò ha ṣe ìbẹ̀wò nítorí nǹkan wọ̀nyí?”
    ni Olúwa wí.
    “Èmi kì yóò wá gba ẹ̀san fúnra mi
    lára irú orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

10 “Lọ sí ọgbà àjàrà rẹ̀, kí ẹ sì pa wọ́n run,
    ẹ má ṣe pa wọ́n run pátápátá.
Ya ẹ̀ka rẹ̀ kúrò,
    nítorí àwọn ènìyàn wọ̀nyí kì í ṣe ti Olúwa.
11 Ilé Israẹli àti ilé Juda
    ti jẹ́ aláìṣòdodo sí mi,”
    ni Olúwa wí.

12 Wọ́n ti pa irọ́ mọ́ Olúwa;
    wọ́n wí pé, “Òun kì yóò ṣe ohun kan!
Ibi kan kì yóò sì tọ̀ wá wá;
    àwa kì yóò sì rí idà tàbí ìyàn.
13 Àwọn wòlíì wá dàbí afẹ́fẹ́,
    ọ̀rọ̀ kò sí nínú wọn.
    Nítorí náà, jẹ́ kí ohun tí wọ́n bá sọ ṣẹlẹ̀ sí wọn.”

14 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí:

“Nítorí tí àwọn ènìyàn ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí;
    Èmi yóò sọ ọ̀rọ̀ mi lẹ́nu wọn di iná,
    àti àwọn ènìyàn wọ̀nyí di igi tí yóò jórun.
15 Háà, ẹ̀yin ilé Israẹli,” ni Olúwa wí,
    “Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè láti ọ̀nà jíjìn dìde sí i yín
Orílẹ̀-èdè àtijọ́ àti alágbára nì
    àwọn ènìyàn tí ìwọ kò mọ èdè rẹ̀,
    tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì yé ọ.
16 Apó-ọfà rẹ sì dàbí isà òkú tí a ṣí
    gbogbo wọn sì jẹ́ akọni ènìyàn.
17 Wọn yóò jẹ ìkórè rẹ àti oúnjẹ rẹ,
    àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin àti obìnrin,
wọn yóò sì jẹ agbo àti ẹran rẹ,
    wọn yóò jẹ àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ.
Pẹ̀lú idà ni wọn ó run
    ìlú tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé.

18 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá. 19 Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’

20 “Kéde èyí fún ilé Jakọbu,
    kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.
21 (A)Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,
    tí ó lójú ti kò fi ríran
    tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.
22 Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí.
    “Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?
Mo fi yanrìn pààlà Òkun,
    èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.
Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;
    wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.
23 Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,
    wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
24 Wọn kò sọ fún ara wọn pé,
    ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,
    tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’
25 Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,
    ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.

26 “Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà
    tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,
    àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.
27 Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ,
    ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn.
Wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,
28     Wọ́n sanra wọ́n sì ń dán.
Ìwà búburú wọn kò sì lópin;
    wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀.
    Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.
29 Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?”
    ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi
    lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

30 “Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara
    ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.
31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,
    àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn,
àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí,
    kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?

1 Timotiu 4

Àwọn ẹ̀kọ́ fun Timotiu

Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.

Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé. Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run. Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo. 10 Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.

11 Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni. 12 Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́, 13 Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni. 14 Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.

15 Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn. 16 Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.