Old/New Testament
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ ní ti Damasku
17 (A)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Damasku:
“Kíyèsi i, Damasku kò ní jẹ́ ìlú mọ́
ṣùgbọ́n yóò padà di ààtàn.
2 Àwọn ìlú Aroeri ni a ó kọ̀sílẹ̀
fún àwọn agbo ẹran tí yóò máa sùn síbẹ̀,
láìsí ẹni tí yóò dẹ́rùbà wọ́n.
3 Ìlú olódi ni yóò pòórá kúrò ní Efraimu,
àti agbára ọba kúrò ní Damasku;
àwọn àṣẹ́kù Aramu yóò dá
gẹ́gẹ́ bí ògo ti àwọn Israẹli,”
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
4 “Ní ọjọ́ náà ni ògo Jakọbu yóò sá;
ọ̀rá ara rẹ̀ yóò ṣòfò dànù.
5 Yóò sì dàbí ìgbà tí olùkórè kó àwọn
irúgbìn tí ó dúró jọ
tí ó sì ń kórè irúgbìn pẹ̀lú apá rẹ̀—
àti gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ènìyàn pa ọkà ní Àfonífojì ti Refaimu.
6 Síbẹ̀síbẹ̀ irúgbìn díẹ̀ yóò ṣẹ́kù,
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí a gbọn igi olifi,
tí èso olifi méjì tàbí mẹ́ta ṣẹ́kù
sórí ẹ̀ka tí ó ga jùlọ,
mẹ́rin tàbí márùn-ún lórí ẹ̀ka tí ó so jù,”
ni Olúwa wí, àní Ọlọ́run Israẹli.
7 Ní ọjọ́ náà, àwọn ènìyàn yóò gbójú sókè sí Ẹlẹ́dàá wọn
wọn yóò sì ṣíjú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli.
8 Wọn kò ní wo àwọn pẹpẹ mọ́,
èyí tí í ṣe iṣẹ́ ọwọ́ wọn,
wọn kò sì ní kọbi ara sí ère Aṣerah mọ́
tàbí pẹpẹ tùràrí tí ìka ọwọ́ wọn ti ṣe.
9 Ní ọjọ́ náà àwọn ìlú alágbára rẹ̀, yóò dàbí ẹ̀ka ìkọ̀sílẹ̀, àti ẹ̀ka téńté òkè tí wọ́n fi sílẹ̀ nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Gbogbo wọn yóò sì di ahoro.
10 Nítorí ìwọ ti gbàgbé Ọlọ́run ìgbàlà rẹ;
tí ìwọ kò sì náání àpáta ìgbàlà rẹ̀,
nítorí náà ni ìwọ ti gbin ọ̀gbìn dáradára
ìwọ sì tọ́ àjèjì ẹ̀ka sínú rẹ̀.
11 Nítorí náà, bí ẹ tilẹ̀ mú àṣàyàn igi tí ẹ sì gbin àjàrà tí ó ti òkèrè wá,
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ tí ẹ kó wọn jáde ẹ mú wọn hù jáde,
àti ní òwúrọ̀ tí ẹ gbìn wọ́n
ẹ mú kí wọ́n rúdí,
síbẹ̀síbẹ̀ ìkórè kò ní mú nǹkan wá
ní ọjọ́ ààrùn àti ìrora tí kò gbóògùn.
12 Kíyèsi i, ìrunú àwọn orílẹ̀-èdè—
wọ́n ń runú bí ìgbì Òkun!
Kíyèsi i, rògbòdìyàn tí ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
wọ́n bú ramúramù gẹ́gẹ́ bí ariwo odò ńlá!
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń bú
ramúramù gẹ́gẹ́ bí ìrúmi odò,
nígbà tí ó bá wọn wí wọ́n sálọ jìnnà réré,
a tì wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò ní orí òkè,
àti gẹ́gẹ́ bí ewéko níwájú ìjì líle.
14 Ní aginjù, ìpayà òjijì!
Kí ó tó di òwúrọ̀, a ò rí wọn mọ́!
Èyí ni ìpín àwọn tí ó jí wa lẹ́rù,
àti ìpín àwọn tí ó fi ogun kó wa.
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Kuṣi
18 (B)Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú,
ní àwọn ipadò Kuṣi,
2 tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun
lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe.
Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára,
sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀,
sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri,
orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè,
tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ.
3 Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé,
tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé,
nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè,
ẹ ó rí i,
nígbà tí a bá fun fèrè kan
ẹ ó gbọ́ ọ.
4 Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré
láti ibùgbé e mi wá,
gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn,
gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.”
5 Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀,
nígbà tí ìrudí bá kún,
nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n.
Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun,
yóò sì mu kúrò,
yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀.
6 A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá
àti fún àwọn ẹranko búburú;
àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn
àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.
7 Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun
láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀,
láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo,
orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè,
ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ—
a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè Sioni, ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.
Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Ejibiti
19 (C)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Ejibiti:
Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin
ó sì ń bọ̀ wá sí Ejibiti.
Àwọn ère òrìṣà Ejibiti wárìrì níwájú rẹ̀,
ọkàn àwọn ará Ejibiti sì ti domi nínú wọn.
2 “Èmi yóò rú àwọn ará Ejibiti sókè sí ara wọn
arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà,
aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀,
ìlú yóò dìde sí ìlú,
ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba.
3 Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù,
èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo;
wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀,
àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.
4 Èmi yóò fi Ejibiti lé agbára
àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́,
ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
5 Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ,
gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá.
6 Adágún omi yóò sì di rírùn;
àwọn odò ilẹ̀ Ejibiti yóò máa dínkù
wọn yóò sì gbẹ.
Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ,
7 àwọn igi ipadò Naili pẹ̀lú,
tí ó wà ní orísun odò,
gbogbo oko tí a dá sí ipadò Naili
yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù
tí kò sì ní sí mọ́.
8 Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò,
àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò;
odò náà yóò sì máa rùn.
9 Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú
àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù.
10 Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì,
gbogbo àwọn oníṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe.
11 Àwọn oníṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n,
àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn Farao
ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá.
Báwo ló ṣe lè sọ fún Farao pé,
“Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn,
ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.”
12 Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí?
Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀
ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ti pinnu lórí Ejibiti.
13 Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè,
a ti tan àwọn ọmọ-aládé Memfisi jẹ;
àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ
ti ṣi Ejibiti lọ́nà.
14 Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn;
wọ́n mú Ejibiti ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú
ohun gbogbo tí ó ń ṣe,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀.
15 Kò sí ohun tí Ejibiti le ṣe—
orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò.
16 Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará Ejibiti yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. 17 Ilẹ̀ Juda yóò sì di ẹ̀rù fún Ejibiti; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ Juda létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn.
18 Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ Ejibiti yóò sọ èdè àwọn ará Kenaani, wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun.
19 Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn Ejibiti, àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀. 20 Yóò sì jẹ́ ààmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ Ejibiti. Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. 21 Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará Ejibiti àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ. 22 Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá Ejibiti jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn.
23 Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Asiria yóò lọ sí Ejibiti àti àwọn ará Ejibiti lọ sí Asiria. Àwọn ará Ejibiti àti ará Asiria yóò jọ́sìn papọ̀. 24 Ní ọjọ́ náà Israẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú Ejibiti àti Asiria, àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé. 25 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún Ejibiti ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti Israẹli ìní mi.”
17 Nítorí náà, ẹ má ṣé jẹ aláìlóye, ṣùgbọ́n ẹ máa mòye ohun tí ìfẹ́ Olúwa jásí. 18 Ẹ má sí ṣe mú wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí rúdurùdu wà; ṣùgbọ́n ẹ kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. 19 (A)Ẹ sì máa bá ara yín sọ̀rọ̀ nínú Saamu, àti orin ìyìn, àti orin Ẹ̀mí, ẹ máa kọrin, kí ẹ sì máa kọrin dídùn ní ọkàn yín sí Olúwa. 20 Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo fún ohun gbogbo lọ́wọ́ Ọlọ́run, àní Baba, ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wá.
Àwọn aya àti ọkọ
21 Ẹ máa tẹríba fún ara yín ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run.
22 (B)Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa. 23 Nítorí pé ọkọ ni ó ń ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí i ṣe orí ìjọ, tí òun si ń ṣe ara rẹ̀, Òun sì ni Olùgbàlà rẹ̀. 24 Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ tí i tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ní kì àwọn aya máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo.
25 Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. 26 Kí òun lè sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó tí fi ọ̀rọ̀ wẹ̀ ẹ́ nínú agbada omí. 27 Kí òun lé mú un wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ bí ìjọ tí ó ní ògo ní àìlábàwọ́n, tàbí àlébù kan, tàbí irú nǹkan bá-wọ̀n-ọn-nì: ṣùgbọ́n kí ó lè jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù. 28 Bẹ́ẹ̀ ní ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin máa fẹ́ràn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnrawọn. 29 Nítorí kò sì ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bí kò ṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ. 30 Nítorí pé àwa ni ẹ̀yà ara rẹ̀, àti tí ẹran-ara rẹ̀, àti egungun ara rẹ̀. 31 (C)Nítorí èyí ní ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. 32 Àṣírí ńlá ní èyí: ṣùgbọ́n èmí ń sọ nípá ti Kristi àti tí ìjọ. 33 Ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù yín fẹ́ràn aya rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun fúnrarẹ̀; kí aya kí ó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.