Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 30-31

30 “Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,”
    ni Olúwa wí,
“Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi,
    tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi,
    tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;
tí wọ́n lọ sí Ejibiti
    láìṣe fún mi,
tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò,
    sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi.
Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín,
    òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.
Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani,
    tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi,
gbogbo wọn ni a ó dójútì,
    nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn,
tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá,
    bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù:

Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú,
    ti kìnnìún àti abo kìnnìún
ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró,
    àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀
wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
    àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ,
    sí orílẹ̀-èdè aláìlérè,
sí Ejibiti tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
    kò wúlò rárá.
Nítorí náà mo pè é ní
    Rahabu aláìlẹ́ṣẹ̀ nǹkan kan.

Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn,
    tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká,
pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀
    kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.
Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn
    àti ẹlẹ́tanu ọmọ,
àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí
    ìtọ́ni Olúwa.
10 Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé,
    “Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!”
Àti fún àwọn wòlíì,
    “Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́!
Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa,
    ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.
11 Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,
    ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí
ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá
    pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!”

12 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí:

“Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,
    ẹ gbára lé ìnilára
    kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn,
13 ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ
    gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì
    tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
14 Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì
    tí a fọ́ pátápátá
àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,
    fún mímú èédú kúrò nínú ààrò
    tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”

15 Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí:

“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,
    ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,
    ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
16 Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’
    Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá!
Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’
    Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára!
17 Ẹgbẹ̀rún yóò sá
    nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;
nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún
    gbogbo yín lẹ ó sálọ,
títí a ó fi yín sílẹ̀
    àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè,
    gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”

18 Síbẹ̀síbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ ṣíjú àánú wò ọ́;
    ó dìde láti ṣàánú fún ọ.
Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.
    Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!

19 Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn. 20 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn. 21 Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.” 22 Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”

23 Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú. 24 Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi àmúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀. 25 Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀mí wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò sàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré. 26 Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

27 Kíyèsi i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wá
    pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kurukuru
èéfín tí ó nípọn;
    ètè rẹ̀ kún fún ìbínú
    ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.
28 Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára,
    tí ó rú sókè dé ọ̀run.
Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀;
    ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn
    láti ṣì wọ́n lọ́nà.
29 Ẹ̀yin ó sì kọrin
    gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,
ọkàn yín yóò yọ̀
    gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lú fèrè
sí orí òkè Olúwa,
    àní sí àpáta Israẹli.
30 Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀
    yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀
pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,
    pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.
31 Ohùn Olúwa yóò fọ́ Asiria túútúú,
    pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.
32 Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn
    pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀
yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù,
    gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun
    pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀.
33 A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́,
    a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba.
Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀,
    pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná;
èémí Olúwa,
    gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.

Ègbé ni fún àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti

31 Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí
    Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́,
tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin
    tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn
àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn,
    ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì,
    tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.
Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá;
    òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ.
Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà,
    àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.
Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti
    wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.
    Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde,
ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀,
    ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;
    àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.

Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:

“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké
    àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀
bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn
    tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀,
ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn
    akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá
    láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè
    Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu,
Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀
    Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”

Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Israẹli.

Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe.
“Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá;
    idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n.
Wọn yóò sì sá níwájú idà náà
    àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.
Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù;
    àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù asia náà,”
    ni Olúwa wí,
ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Sioni,
    ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.

Filipi 4

Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú

Èmi ń bẹ̀ Euodia, mo sì ń bẹ Sintike, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa. (A)Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìhìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.

Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. (B)Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. (C)Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.

Àwọn ọpẹ́ fún àwọn ẹ̀bùn wọn

10 (D)Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa pé, nísinsin yìí, ẹ̀yin tún ti sọjí nínú àníyàn ọkàn yín sí mi, nítòótọ́ ọkàn yín ń fàmọ́ mi ṣùgbọ́n ẹ kò ní àǹfààní tó. 11 Kì í ṣe pé èmi ń sọ nítorí àìní: nítorí pé ni ipòkípò tí mo bá wà, mo tí kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú rẹ̀. 12 Mo mọ̀ ohun tí o jẹ láti wa nínú àìní, mo sì mọ ohun tí ó jẹ láti ni lọ́pọ̀lọpọ̀. Nínú ohunkóhun àti nínú ohun gbogbo mo ti kọ́ àṣírí láti máa jẹ́ àjẹyó tàbí láti wà ni àìjẹun, láti máa ni ànító àti láti ṣe aláìní. 13 (E)Èmi le ṣe ohun gbogbo nínú Kristi ẹni ti ń fi agbára fún mi.

14 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ṣeun gidigidi ní ti pé ẹ̀yin ṣe alábápín nínú ìpọ́njú mi. 15 Ẹ̀yin pàápàá sì mọ̀ pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Filipi, pé ni ìbẹ̀rẹ̀ ìhìnrere, nígbà tí mo kúrò ni Makedonia, kò sí ìjọ kan ti ó bá mi ń ṣe alábápín ní ti gbígbà àti fífún ni, bí kò ṣe ẹ̀yin nìkan ṣoṣo. 16 (F)Nítorí ní Tẹsalonika ẹ̀yin fi nǹkan ránṣẹ́, lẹ́ẹ̀kan fún àìní mi. 17 Kì í ṣe nítorí ti èmi ń fẹ́ ẹ̀bùn náà: ṣùgbọ́n èmi ń fẹ́ èso ti yóò máa di púpọ̀ nítorí yín 18 Ṣùgbọ́n mo ní ohun gbogbo, mo sì ti di púpọ̀: mo sì tún ni lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà ti mo tí gba nǹkan wọ̀nyí lọ́wọ́ Epafiroditu tí a ti rán wá láti lọ́dọ̀ yín, ọrẹ olóòórùn dídùn, ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà, tì í ṣe inú dídùn gidigidi sí Ọlọ́run. 19 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kristi Jesu.

20 Ṣùgbọ́n ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba wa láé àti láéláé. Àmín.

Ọ̀rọ̀ ìkíni ìkẹyìn

21 Ẹ kí olúkúlùkù ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu.

Àwọn ará tí ó wà pẹ̀lú mi kí yín.

22 Gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ kí yín, pàápàá àwọn tí ń ṣe ti agbo ilé Kesari.

23 (G)Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.