Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 12-14

Ọ̀rọ̀ Jeremiah

12 Olúwa, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà,
    nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá.
Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ.
    Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé?
    Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn?
Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀,
    wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso.
Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn,
    o jìnnà sí ọkàn wọn.
Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní Olúwa,
    o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò.
Wọ, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa.
    Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.
Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà,
    tí gbogbo ewéko igbó sì ń rọ?
Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀.
    Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé,
pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé,
    “Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa.”

Ìdáhùn Ọlọ́run

Bí ìwọ bá ń bá ẹlẹ́ṣẹ̀ sáré,
    tí àárẹ̀ sì mú ọ,
báwo ni ìwọ yóò ṣe bá ẹṣin díje?
    Bí ìwọ bá kọsẹ̀ ní ilẹ̀ àlàáfíà,
    bí ìwọ bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé,
    kí ni ìwọ ó ṣe nínú ẹkùn odò Jordani?
Àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn
    ìdílé—
ti dà ọ́, kódà wọ́n ti kẹ̀yìn sí ọ
    Wọ́n ti hó lé ọ lórí;
Má ṣe gbà wọ́n gbọ́
    bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ dáradára.

Èmi yóò kọ ilé mi sílẹ̀,
    èmi yóò fi ìní mi sílẹ̀.
Èmi yóò fi ẹni tí mo fẹ́
    lé àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́wọ́.
Ogún mi ti rí sí mi
    bí i kìnnìún nínú igbó.
Ó ń bú ramúramù mọ́ mi;
    nítorí náà mo kórìíra rẹ̀.
Ogún mi kò ha ti rí sí mi
    bí ẹyẹ kannakánná
tí àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ dòyì ka, tí wọ́n sì kọjú ìjà sí i?
    Ẹ lọ, kí ẹ sì kó gbogbo ẹranko igbó jọ,
    ẹ mú wọn wá jẹ.
10 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùṣọ́-àgùntàn ni yóò sì ba ọgbà àjàrà mi jẹ́,
    tí wọn yóò sì tẹ oko mi mọ́lẹ̀;
Wọ́n ó sọ oko dídára mi di
    ibi tí a ń da ìdọ̀tí sí.
11 A ó sọ ọ́ di aṣálẹ̀ ilẹ̀
    tí kò wúlò níwájú mi,
gbogbo ilẹ̀ ni yóò di ahoro
    nítorí kò sí ẹnìkankan tí yóò náání.
12 Gbogbo ibi gíga tí ó wà nínú aṣálẹ̀
    ni àwọn apanirun ti gorí,
nítorí idà Olúwa yóò pa
    láti ìkangun kìn-ín-ní dé ìkangun èkejì ilẹ̀ náà;
    kò sí àlàáfíà fún gbogbo alààyè.
13 Àlìkámà ni wọn yóò gbìn, ṣùgbọ́n ẹ̀gún ni wọn yóò ká,
    wọn yóò fi ara wọn ṣe wàhálà, ṣùgbọ́n òfo ni èrè wọn.
Kí ojú kí ó tì yín nítorí èrè yín,
    nítorí ìbínú gbígbóná Olúwa.

14 Èyí ni ohun tí Olúwa wí: “Ní ti gbogbo àwọn aládùúgbò mi búburú tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé ogún tí mo fún àwọn ènìyàn Israẹli mi, Èmi yóò fà wọ́n tu kúrò lórí ilẹ̀ wọn, èmi yóò fa ìdílé Juda tu kúrò ní àárín wọn. 15 Ṣùgbọ́n tí mo bá fà wọ́n tu tán, Èmi yóò padà yọ́nú sí wọn. Èmi yóò sì padà fún oníkálùkù ní ogún ìní rẹ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ ìní oníkálùkù. 16 Bí wọ́n bá sì kọ ìwà àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì fi orúkọ mi búra wí pé, ‘níwọ̀n bí Olúwa ń bẹ láààyè,’ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ́ àwọn ènìyàn mi láti fi Baali búra, nígbà náà ni a ó gbé wọn ró láàrín àwọn ènìyàn mi. 17 Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kan kò bá gbọ́, Èmi yóò fà á tu pátápátá, èmi yóò sì pa wọ́n run,” ni Olúwa wí.

Owe aṣọ funfun

13 Èyí ni ohun tí Olúwa wí fún mi: “Lọ kí o sì ra àmùrè aṣọ ọ̀gbọ̀, kí o sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o má sì ṣe jẹ́ kí omi kí ó kàn án.” Bẹ́ẹ̀ ni mo ra àmùrè gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí, mo sì dì í mọ́ ẹ̀gbẹ́ mi.

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá nígbà kejì: Mú àmùrè tí o rà, kí o sì fiwé ẹ̀gbẹ́ rẹ, kí o sì lọ sí Perati, kí o lọ pa á mọ́ sí pàlàpálá òkúta. Nígbà náà ni mo lọ pa á mọ́ ní Perati gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti wí fún mi.

Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Olúwa sọ fún mi: Lọ sí Perati kí o lọ mú àmùrè tí mo ní kí o pamọ́ síbẹ̀. Nígbà náà ni mo lọ sí Perati mo lọ wá àmùrè mi níbi tí mo pa á mọ́ sí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àmùrè náà ti bàjẹ́, kò sì wúlò fún ohunkóhun mọ́.

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Bákan náà ni èmi yóò run ìgbéraga Juda àti ìgbéraga ńlá ti Jerusalẹmu. 10 Àwọn ènìyàn búburú tí ó kùnà láti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, tí wọ́n ń lo agídí ọkàn wọn, tí ó sì ń rìn tọ àwọn òrìṣà láti sìn wọ́n, àti láti foríbalẹ̀ fún wọn, yóò sì dàbí àmùrè yìí tí kò wúlò fún ohunkóhun. 11 Nítorí bí a ti lẹ àmùrè mọ́ ẹ̀gbẹ́ ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni a lẹ agbo ilé Israẹli àti gbogbo ilé Juda mọ́ mi,’ ni Olúwa wí, ‘kí wọn kí ó lè jẹ́ ènìyàn ògo àti ìyìn fún mi, ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ gbọ́.’

Ọtí Wáìnì

12 “Sọ fún wọn, ‘Èyí ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ Israẹli wí: Gbogbo ìgò ni à ó fi ọtí wáìnì kún.’ Bí wọ́n bá sì sọ fún ọ pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìgò ni ó yẹ láti bu ọtí wáìnì kún?’ 13 Nítorí náà sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Èmi yóò fi ìmutípara kún gbogbo olùgbé ilẹ̀ yìí pẹ̀lú ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì gbogbo àwọn tó ń gbé ní Jerusalẹmu. 14 Èmi yóò ti èkínní lu èkejì, àwọn baba àti ọmọkùnrin pọ̀ ni Olúwa wí: Èmi kì yóò dáríjì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú, èmi kì yóò ṣe ìyọ́nú láti máa pa wọ́n run.’ ”

Ìkìlọ̀ oko ẹrú

15 Gbọ́ kí o sì fetísílẹ̀,
    ẹ má ṣe gbéraga,
    nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.
16 Ẹ fi ògo fún Olúwa Ọlọ́run yín,
    kí ó tó mú òkùnkùn wá,
àti kí ó tó mú ẹsẹ̀ yín tàsé
    lórí òkè tí ó ṣókùnkùn,
Nígbà tí ẹ̀yin sì ń retí ìmọ́lẹ̀,
    òun yóò sọ ọ́ di òjìji yóò sì ṣe bi òkùnkùn biribiri.
17 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fetísílẹ̀,
    Èmi yóò sọkún ní ìkọ̀kọ̀
nítorí ìgbéraga yín;
    Ojú mi yóò sun ẹkún kíkorò,
tí omi ẹkún, yóò sì máa sàn jáde,
    nítorí a kó agbo Olúwa lọ ìgbèkùn.

18 Sọ fún ọba àti ayaba pé,
    “Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀,
ẹ sọ̀kalẹ̀ láti orí ìtẹ́ yín,
    adé ògo yín bọ́ sí ilẹ̀ láti orí yín.”
19 Àwọn ìlú tí ó wà ní gúúsù ni à ó tì pa,
    kò sì ní sí ẹnikẹ́ni láti ṣí wọn.
Gbogbo Juda ni a ó kó lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn,
    gbogbo wọn ni a ó kó lọ ní ìgbèkùn pátápátá.

20 Gbé ojú rẹ sókè,
    kí o sì wo àwọn tí ó ń bọ̀ láti àríwá.
Níbo ni agbo ẹran tí a fi sí abẹ́ àkóso rẹ wà;
    àgùntàn tí ò ń mú yangàn.
21 Kí ni ìwọ yóò wí nígbà tí Olúwa bá dúró lórí rẹ
    àwọn tí o mú bí ọ̀rẹ́ àtàtà.
Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìrora fún ọ
    bí aboyún tó ń rọbí?
22 Tí o bá sì bi ara rẹ léèrè
    “Kí ni ìdí rẹ̀ tí èyí fi ṣẹlẹ̀ sí mi?”
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ tí o ṣẹ̀
    ni aṣọ rẹ fi fàya
    tí a sì ṣe é ní ìṣekúṣe.
23 Ǹjẹ́ Etiopia le yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
    Tàbí ẹkùn lè yí àwọ̀ rẹ̀ padà?
Bí èyí kò ti lè rí bẹ́ẹ̀
    náà ni ẹ̀yin tí ìwà búburú bá ti mọ́ lára kò lè ṣe rere.

24 “N ó fọ́n ọn yín ká bí i ìyàngbò
    tí ẹ̀fúùfù ilẹ̀ aṣálẹ̀ ń fẹ́.
25 Èyí ni ìpín tìrẹ;
    tí mo ti fi sílẹ̀ fún ọ,”
    ni Olúwa wí,
“Nítorí ìwọ ti gbàgbé mi
    o sì gbẹ́kẹ̀lé àwọn ọlọ́run àjèjì.
26 N ó sí aṣọ lójú rẹ,
    kí ẹ̀sín rẹ le hàn síta—
27 ìwà àgbèrè àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́,
    àìlójútì panṣágà rẹ!
Mo ti rí ìwà ìríra rẹ,
    lórí òkè àti ní pápá.
Ègbé ni fún ọ ìwọ Jerusalẹmu!
    Yóò ti pẹ́ tó tí o ó fi máa wà ní àìmọ́?”

Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà

14 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:

“Juda káàánú,
    àwọn ìlú rẹ̀ kérora
wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,
    igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,
    wọ́n lọ sí ìdí àmù
ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.
    Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;
ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,
    wọ́n sì bo orí wọn.
Ilẹ̀ náà sán
    nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
    wọ́n sì bo orí wọn.
Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá
    fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
    torí pé kò sí koríko.
Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo
    wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò
ojú wọn kò ríran
    nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,
    wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.
Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,
    a ti ṣẹ̀ sí ọ.
Ìrètí Israẹli;
    ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,
èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà
    bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?
Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,
    bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?
Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,
    orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;
    má ṣe fi wá sílẹ̀.

10 Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:

“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;
    wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.
Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;
    yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,
    yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

11 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 12 (A)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”

13 Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”

14 Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn. 15 Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn. 16 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

17 “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:

“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé
    ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;
nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,
    ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá
    pẹ̀lú lílù bolẹ̀.
18 Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,
    Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.
Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,
    èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.
Wòlíì àti Àlùfáà
    ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”

19 Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?
    Ṣé o ti ṣá Sioni tì?
Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú
    tí a kò fi le wò wá sàn?
A ń retí àlàáfíà
    ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,
ní àsìkò ìwòsàn
    ìpayà là ń rí.
20 Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa
    àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;
    lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.
21 Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;
    má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.
Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá
    kí o má ṣe dà á.
22 Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?
    Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnrarẹ̀ rọ òjò bí?
Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.
    Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,
nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.

2 Timotiu 1

Ọ̀rọ̀ ìkíni

Paulu, aposteli ti Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè ti ń bẹ nínú Kristi Jesu.

Sí Timotiu, ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n:

Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kristi Jesu Olúwa wa.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú láti jẹ́ onígbàgbọ́

Mo dá ọpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹni tí èmi ń sìn pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn baba mi ti í ṣe, pé ni àìsimi lọ́sàn án àti lóru ni mo ń ṣe ìrántí rẹ nínú àdúrà mi. Bí mo ti rántí omijé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni mo ń fẹ́ láti rí ọ kí èmi kí ó lè kún fún ayọ̀. (A)Nígbà ti mo bá rántí ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn rẹ, èyí ti ó kọ́kọ́ ń bẹ nínú Loisi ìyá ńlá rẹ, àti nínú Eunike ìyá rẹ̀ àti, èyí tí ó dá mi lójú pé ó ń gbé inú rẹ̀ pẹ̀lú.

Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń ran ọ létí pé kí ó máa rú ẹ̀bùn Ọlọ́run sókè èyí ti ń bẹ nínú rẹ nípa ìgbọ́wọ́lé mi. Nítorí pé Ọlọ́run kò fún wa ni ẹ̀mí ìbẹ̀rù, bí kò ṣe ti agbára, àti ti ìfẹ́, àti ti ìsẹ́ra-ẹni ti ó yè kooro. Nítorí náà, má ṣe tijú láti jẹ́rìí nípa Olúwa wa, tàbí èmi òǹdè rẹ̀; ṣùgbọ́n kí ìwọ ṣe alábápín nínú ìpọ́njú ìhìnrere nípa agbára Ọlọ́run, ẹni ti ó gbà wá là, ti ó si pè wá sínú ìwà mímọ́—kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí a ṣe ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ète àti oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀. Oore-ọ̀fẹ́ yìí ni a fi fún wa nínú Kristi Jesu láti ìpìlẹ̀ ayérayé, 10 ṣùgbọ́n tí a fihàn nísinsin yìí nípa ìfarahàn Jesu Kristi Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ìhìnrere. 11 Fún ti ìhìnrere tí a yàn mi láti jẹ oníwàásù àti aposteli àti olùkọ́. 12 Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí: nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.

13 Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kristi Jesu. 14 Pa ohun rere ti a ti fi lé ọ lọ́wọ́ mọ́ nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ti ń gbé inú wa.

15 Èyí ni ìwọ mọ̀ pé, gbogbo àwọn ti ó wà ni agbègbè Asia ti fi mí sílẹ̀, nínú àwọn ẹni tí Figeliu àti Hamogene gbé wà.

16 Kí Olúwa fi àánú fún ilé Onesiforu; nítorí ti ó máa ń tù mi lára nígbà púpọ̀, ẹ̀wọ̀n mi kò sì tì í lójú. 17 Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wà ni Romu, ó fi ẹ̀sọ̀ wá mi, ó sì rí mi. 18 Kí Olúwa fi fún un kí ó lè rí àánú lọ́dọ̀ Olúwa ni ọjọ́ náà! Ìwọ tìkára rẹ sá à mọ̀ ọ̀nà gbogbo tí ó gbà ràn mí lọ́wọ́ ni Efesu.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.