Old/New Testament
45 “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ẹni òróró rẹ̀,
sí Kirusi, ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí mo dì mú
láti dojú àwọn orílẹ̀-èdè bolẹ̀ níwájú rẹ̀
àti láti gba ohun ìjà àwọn ọba lọ́wọ́ wọn,
láti ṣí àwọn ìlẹ̀kùn níwájú rẹ̀
tí ó fi jẹ́ pé a kì yóò ti àwọn ẹnu-ọ̀nà.
2 Èmi yóò lọ síwájú rẹ
èmi ó sì tẹ́ àwọn òkè ńlá pẹrẹsẹ
Èmi yóò fọ gbogbo ẹnu-ọ̀nà idẹ
èmi ó sì gé ọ̀pá irin.
3 Èmi yóò sì fún ọ ní àwọn ọrọ̀ ibi òkùnkùn,
ọrọ̀ tí a kó pamọ́ sí àwọn ibi tí ó fi ara sin,
Tó bẹ́ẹ̀ tí ìwọ yóò fi mọ̀ pé Èmi ni Olúwa,
Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ.
4 Nítorí Jakọbu ìránṣẹ́ mi
àti Israẹli ẹni tí mo yàn
Mo pè ọ́ pẹ̀lú orúkọ rẹ,
mo sì gbé oyè kan kà ọ́ lórí
bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ kò gbà mí.
5 Èmi ni Olúwa, àti pé kò sí ẹlòmíràn;
yàtọ̀ sí èmi kò sí ọlọ́run kan,
Èmi yóò fún ọ ní okun,
bí o kò tilẹ̀ tí ì gbà mí,
6 tí o fi jẹ́ pé láti ìlà-oòrùn
títí dé ibi ìwọ̀ rẹ̀
kí ènìyàn le mọ̀, kò sí ẹnìkan lẹ́yìn mi.
Èmi ni Olúwa, lẹ́yìn mi kò sí ẹlòmíràn mọ́.
7 Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn
mo mú àlàáfíà wá, mo sì dá àjálù;
Èmi Olúwa ni ó ṣe nǹkan wọ̀nyí.
8 “Ìwọ ọ̀run lókè rọ òjò òdodo sílẹ̀;
jẹ́ kí àwọsánmọ̀ kí ó rọ̀ ọ́ sílẹ̀.
Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó yanu gbagada,
jẹ́ kí ìgbàlà kí ó dìde sókè,
jẹ́ kí òdodo kí ó dàgbà pẹ̀lú rẹ̀;
Èmi Olúwa ni ó ti dá a.
9 (A)“Ègbé ni fún ènìyàn tí ó ń bá Ẹlẹ́dàá rẹ̀ jà,
ẹni tí òun jẹ́ àpáàdì kan láàrín àwọn àpáàdì tí ó wà lórí ilẹ̀.
Ǹjẹ́ amọ̀ lè sọ fún amọ̀kòkò, pé:
‘Kí ni ohun tí ò ń ṣe?’
Ǹjẹ́ iṣẹ́ rẹ lè sọ pé,
‘Òun kò ní ọwọ́?’
10 Ègbé ni fún ẹni tí ó sọ fún baba rẹ̀ pé,
‘Kí ni o bí?’
tàbí sí ìyá rẹ̀,
‘Kí ni ìwọ ti bí?’
11 “Ohun tí Olúwa wí nìyìí
Ẹni Mímọ́ Israẹli, àti Ẹlẹ́dàá rẹ̀:
Nípa ohun tí ó ń bọ̀,
ǹjẹ́ o ń bi mí léèrè nípa àwọn ọmọ mi,
tàbí kí o pàṣẹ fún mi nípa iṣẹ́ ọwọ́ mi bí?
12 Èmi ni ẹni tí ó dá ilẹ̀ ayé
tí ó sì da ọmọ ènìyàn sórí i rẹ̀.
Ọwọ́ mi ni ó ti ta àwọn ọ̀run
mo sì kó àwọn àgbájọ ìràwọ̀ rẹ̀ síta
13 Èmi yóò gbé Kirusi sókè nínú òdodo mi:
Èmi yóò mú kí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.
Òun yóò tún ìlú mi kọ́
yóò sì tú àwọn àtìpó mi sílẹ̀,
ṣùgbọ́n kì í ṣe fún owó tàbí ẹ̀bùn kan,
ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
14 (B)Ohun tí Olúwa wí nìyìí:
“Àwọn èròjà ilẹ̀ Ejibiti àti àwọn ọjà ilẹ̀ Kuṣi,
àti àwọn Sabeani—
wọn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
wọn yóò sì jẹ́ tìrẹ;
wọn yóò máa wọ́ tẹ̀lé ọ lẹ́yìn,
wọn yóò máa wá lọ́wọ̀ọ̀wọ́.
Wọn yóò máa foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀,
wọn yóò sì máa bẹ̀bẹ̀ níwájú rẹ pé,
‘Nítòótọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ kò sì ṣí ẹlòmíràn;
kò sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
15 Nítòótọ́ ìwọ jẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ara rẹ̀ pamọ́,
Ìwọ Ọlọ́run àti Olùgbàlà Israẹli
16 Gbogbo àwọn tí ó ń gbẹ́ ère ni ojú yóò tì
wọn yóò sì kan àbùkù;
gbogbo wọn ni yóò bọ́ sínú àbùkù papọ̀.
17 (C)Ṣùgbọ́n Israẹli ni a ó gbàlà láti ọwọ́ Olúwa
pẹ̀lú ìgbàlà ayérayé;
a kì yóò kàn yín lábùkù tàbí kí a dójútì yín,
títí ayé àìnípẹ̀kun.
18 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí—
ẹni tí ó dá àwọn ọ̀run,
Òun ni Ọlọ́run;
ẹni tí ó mọ tí ó sì dá ayé,
Òun ló ṣe é;
Òun kò dá a láti wà lófo,
ṣùgbọ́n ó ṣe é kí a lè máa gbé ibẹ̀—
Òun wí pé:
“Èmi ni Olúwa,
kò sì ṣí ẹlòmíràn.
19 Èmi kò sọ̀rọ̀ níbi tí ó fi ara sin,
láti ibìkan ní ilẹ̀ òkùnkùn;
Èmi kò tí ì sọ fún àwọn ìran Jakọbu pé
‘Ẹ wá mi lórí asán.’
Èmi Olúwa sọ òtítọ́;
Mo sì sọ èyí tí ó tọ̀nà.
20 “Ẹ kó ara yín jọ kí ẹ sì wá;
ẹ kórajọ, ẹ̀yin ìsáǹsá láti àwọn
orílẹ̀-èdè wá.
Aláìmọ̀kan ni àwọn tí ó ń ru ère igi káàkiri,
tí wọ́n gbàdúrà sí àwọn òrìṣà tí kò le gba ni.
21 (D)Jẹ́ kí a mọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀, fihàn wá
jẹ́ kí wọn jọ dámọ̀ràn papọ̀.
Ta ló ti sọ èyí lọ́jọ́ tí o ti pẹ́,
ta ló ti wí èyí láti àtètèkọ́ṣe?
Kì í ha á ṣe Èmi, Olúwa?
Àti pé kò sí Ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi,
Ọlọ́run olódodo àti olùgbàlà;
kò sí ẹlòmíràn àfi èmi.
22 “Yípadà sí mi kí a sì gbà ọ́ là,
ẹ̀yin ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé;
nítorí Èmi ni Ọlọ́run kò sì ṣí ẹlòmíràn.
23 (E)Nípa èmi tìkára mi ni mo ti búra,
ẹnu mi ni ó ti sọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ipá mi,
ọ̀rọ̀ náà tí a kì yóò lè parẹ́:
Níwájú mi ni gbogbo orúnkún yóò wólẹ̀;
nípa mi ni gbogbo ahọ́n yóò búra.
24 Wọn yóò sọ ní ti èmi, ‘Nínú Olúwa nìkan ni
òdodo àti agbára wà.’ ”
Gbogbo àwọn tí ó ti bínú sí;
yóò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ a ó sì dójútì wọn.
25 Ṣùgbọ́n nínú Olúwa gbogbo àwọn ìran Israẹli
ni a ó rí ní òdodo, a o sì gbé wọn ga.
Àwọn Ọlọ́run Babeli
46 Beli tẹrí i rẹ̀ ba, Nebo bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀;
àwọn ère wọn ni àwọn ẹranko rù.
Àwọn ère tí wọ́n ń rù káàkiri ti di
àjàgà sí wọn lọ́rùn,
ẹrù fún àwọn tí àárẹ̀ mú.
2 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì foríbalẹ̀ papọ̀;
wọn kò lè gba ẹrù náà,
àwọn pẹ̀lú ni a kó lọ ní ìgbèkùn.
3 “Tẹ́tí sí mi, ìwọ ilé Jakọbu,
Gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́kù nínú ilé Israẹli,
Ìwọ tí mo ti gbéró láti ìgbà tí o ti wà nínú oyún,
tí mo sì ti ń pọ̀n láti ìgbà tí a ti bí ọ.
4 Pẹ̀lúpẹ̀lú sí àwọn arúgbó àti ewú orí yín
Èmi ni ẹni náà, Èmi ni ẹni tí yóò gbé ọ ró.
Èmi ti mọ ọ́, èmi yóò sì gbé ọ;
Èmi yóò dì ọ́ mú èmi ó sì gbà ọ́ sílẹ̀.
5 “Ta ni ìwọ yóò fi mí wé tàbí ta ni èmi yóò bá dọ́gba?
Ta ni ìwọ yóò fi ṣe àkàwé mi
tí àwa yóò jọ fi ara wé ara?
6 Ọ̀pọ̀ da wúrà sílẹ̀ nínú àpò wọn
wọ́n sì wọn fàdákà lórí òṣùwọ̀n;
wọ́n bẹ alágbẹ̀dẹ lọ́wẹ̀ láti fi wọ́n ṣe òrìṣà,
wọn sì tẹríba láti sìn ín.
7 Wọ́n gbé e lé èjìká wọn, wọ́n rù wọ́n,
wọ́n sì gbé e sí ààyè rẹ̀ níbẹ̀ ni ó sì dúró sí.
Láti ibẹ̀ náà kò le è paradà
Bí ènìyàn tilẹ̀ pariwo lé e lórí, òun kò le è dáhùn;
òun kò lè gbà á nínú ìyọnu rẹ̀.
8 “Rántí èyí, fi í sí ọkàn rẹ,
fi sí ọkàn rẹ, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀.
9 Rántí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá, àwọn ti àtijọ́-tijọ́;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sì sí ẹlòmíràn;
Èmi ni Ọlọ́run, kò sí ẹlòmíràn bí ì mi.
10 Mo fi òpin hàn láti ìbẹ̀rẹ̀ wá,
láti àtètèkọ́ṣe, ohun tí ó sì ń bọ̀ wá.
Mo wí pé: Ète mi yóò dúró,
àti pé èmi yóò ṣe ohun tí ó wù mí.
11 Láti ìlà-oòrùn wá ni mo ti pe ẹyẹ ajẹran wá;
láti ọ̀nà jíjìn réré, ọkùnrin kan tí yóò mú ète mi ṣẹ.
Ohun tí mo ti sọ, òun ni èmi yóò mú ṣẹ;
èyí tí mo ti gbèrò, òun ni èmi yóò ṣe.
12 Gbọ́ tèmi, ẹ̀yin alágídí ọkàn,
ìwọ tí ó jìnnà sí òdodo.
13 Èmi ń mú òdodo mi bọ̀ nítòsí,
kò tilẹ̀ jìnnà rárá;
àti ìgbàlà mi ni a kì yóò dádúró.
Èmi yóò fún Sioni ní ìgbàlà
ògo mi fún Israẹli.
Timotiu
3 (A)Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ara mi kò gbà á mọ́, mo pinnu láti nìkan dúró ní ìlú Ateni. 2 (B)Awa sì rán Timotiu, arákùnrin àti alábáṣiṣẹ́pọ̀ wa nínú Ọlọ́run nínú ìhìnrere Kristi, láti fi ẹsẹ yín múlẹ̀, àti láti tù yín nínú ní ti ìgbàgbọ́ yín. 3 (C)Láìsí àní àní, ẹ mọ̀ gbangba pé, irú ìṣòro báwọ̀nyí wà nínú ètò Ọlọ́run fún àwọn tí ó gbàgbọ́, kí a má ba dààmú. 4 (D)Tó bẹ́ẹ̀ tí a fi kìlọ̀ fún yín pé ìjìyà inúnibíni yóò dé. Ó sì rí bẹ́ẹ̀ nítòótọ́. 5 (E)Bí mo wí tẹ́lẹ̀, nígbà tí ara mi kò gba á mọ́, mo sì ránṣẹ́ kí èmi kí ó lè mọ́ ìgbàgbọ́ yín, kí olùdánwò nì má ba à dán an yín wò lọ́nàkọnà, kí làálàá wa sì jásí asán.
Ọ̀rọ̀ ìyànjú Timotiu nínú ìròyìn
6 (F)Nísinsin yìí, Timotiu ti dé pẹ̀lú ìròyìn ayọ̀ wí pé, ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ yín ṣì lágbára bí i ti àtẹ̀yìnwá. Inú wa dùn láti gbọ́ wí pé ẹ ṣì ń rántí ìbágbé wa láàrín yín pẹ̀lú ayọ̀. Timotiu tún fi yé wa pé bí ó ti mú wa lọ́kàn tó láti rí i yín, ni ó ṣe ẹ̀yin pàápàá. 7 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, inú wá dùn jọjọ nínú gbogbo ìyọnu àti ìjìyà wa níbí nítorí pé àwa mọ̀ nísinsin yìí pé, ẹ̀yin dúró gbọningbọnin fún Olúwa. 8 Nítorí àwa yè nísinsin yìí, bí ẹ̀yin bá dúró ṣinṣin nínú Olúwa. 9 Kò ṣe é ṣe fún wa láti dá ọpẹ́ tán lọ́wọ́ Ọlọ́run nítorí ayọ̀ àti ìfẹ́ tí ó máa ń kún ọkàn wa nípa àdúrà wa fún un yín. 10 Nítorí pé àwa ń gbàdúrà fún un yín lọ̀sán-án àti lóru. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àtúnṣe ibi tí ìgbàgbọ́ yín bá kù sí.
11 À ń gbàdúrà wí pé, kí ó wu Ọlọ́run pàápàá àti Olúwa wa Jesu Kristi láti rán wa padà sí ọ̀dọ̀ yín lẹ́ẹ̀kan sí í. 12 A sì béèrè pé, kí Ọlọ́run ràn yín lọ́wọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí ìfẹ́ yín yóò fi gbòòrò tí yóò sì sàn kan olúkúlùkù yín. Èyí yóò jẹ́ àpẹẹrẹ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ àwa náà ṣe sàn kan ẹ̀yin náà. 13 (G)Kí ó lè fi ọkàn yín balẹ̀ ní àìlábùkù nínú ìwà mímọ́ níwájú Ọlọ́run àti Baba wa. Nígbà náà, ẹ ó ní ìgboyà láti dúró níwájú rẹ̀ láìṣẹ̀, ní ọjọ́ tí Olúwa wa Jesu Kristi yóò padà wá pẹ̀lú àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.