Old/New Testament
Ẹ̀ṣẹ̀, ìjẹ́wọ́ àti ìràpadà
59 Lódodo ọwọ́ Olúwa kò kúrú láti gbàlà,
tàbí kí etí rẹ̀ wúwo láti gbọ́.
2 Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ yín ló ti yà yín kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run yín;
Ẹ̀ṣẹ̀ yín ti fi ojú u rẹ̀ pamọ́ fún un yín
tó bẹ́ẹ̀ tí òun kò fi le gbọ́.
3 Nítorí ọwọ́ yín di aláìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀,
àti ìka ọwọ́ yín fún ẹ̀bi.
Ètè yín ń pa irọ́ púpọ̀,
ahọ́n yín sì ń sọ̀rọ̀ nǹkan ibi.
4 Kò sí ẹni tí ó béèrè fún ìdájọ́ òdodo;
kò sí ẹni tí ó ro ẹjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú òtítọ́.
Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé àwíjàre asán àti ọ̀rọ̀ irọ́;
wọ́n lóyún ìkà, wọn sì bí wàhálà
5 Wọn ń pa ẹ̀yin paramọ́lẹ̀
wọn sì ń ta owú aláǹtakùn.
Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹyin wọn yóò kú,
àti nígbà tí a pa ọ̀kan, paramọ́lẹ̀ ni ó jáde.
6 Òwú wọn kò wúlò fún aṣọ rírán;
wọn kò lè fi aṣọ tí wọ́n hun bo ara wọn.
Iṣẹ́ wọn jẹ́ ti ibi, ìwà jàǹdùkú sì kún ọwọ́ wọn.
7 (A)Ẹsẹ̀ wọn yára bọ́ sínú ẹ̀ṣẹ̀;
wọ́n yára láti ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.
Èrò wọn sì jẹ́ èrò ibi;
ìparun àti ìdahoro ni ó wà ní ṣíṣe ààmì ọ̀nà wọn.
8 Ọ̀nà àlàáfíà èyí ni wọn kò mọ̀;
kò sí òdodo ní ojú ọ̀nà wọn
wọ́n ti sọ wọ́n dì ọ̀nà kọ́rọkọ̀rọ,
kò sí ẹni tí ó tọ ọ̀nà yìí tí yóò rí àlàáfíà.
9 Nítorí èyí ni ẹ̀tọ́ fi jìnnà sí wa,
àti tí òdodo kò fi tẹ̀ wá lọ́wọ́.
A ń wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ jẹ́ òkùnkùn;
ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n à ń rìn nínú òjìji.
10 Gẹ́gẹ́ bí afọ́jú à ń táràrà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri
tí a ń wá ọ̀nà wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí kò ní ojú.
Ní ọ̀sán gangan ni à ń kọsẹ̀ bí ẹni pé alẹ́ ni;
láàrín alágbára àwa dàbí òkú.
11 Gbogbo wa là ń ké bí i beari;
àwa pohùnréré ẹkún bí àdàbà
A ń wá ìdájọ́ òdodo ṣùgbọ́n kò sí; à ń wọ́nà
fún ìtúsílẹ̀, ṣùgbọ́n ó jìnnà réré.
12 Nítorí àwọn àṣìṣe wa pọ̀ níwájú rẹ,
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa sì ń jẹ́rìí takò wá.
Àwọn àìṣedéédéé wa sì wà pẹ̀lú wa,
àwa pẹ̀lú sì mọ àìṣedéédéé wa,
13 ọ̀tẹ̀ àti àrékérekè wa sí Olúwa,
kíkọ ẹ̀yìn wa sí Ọlọ́run,
dídá yánpọnyánrin àti ìnilára sílẹ̀,
pípààrọ̀ tí ọkàn wa ti gbèrò síta.
14 Nítorí èyí ni a ṣe lé ìdájọ́ òdodo sẹ́yìn,
àti ti òdodo dúró lókèèrè;
òtítọ́ ti ṣubú ní òpópó ọ̀nà,
òdodo kò sì le è wọlé.
15 A kò rí òtítọ́ mọ́,
àti ẹni tí ó bá sá fun ibi tì di ìjẹ.
Olúwa wò ó ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́
pé kò sí ìdájọ́ òdodo.
16 Òun rí i pé kò sí ẹnìkan,
àyà fò ó pé kò sí ẹnìkan láti ṣèrànwọ́;
nítorí apá òun tìkára rẹ̀ ló ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún ara rẹ̀,
àti òdodo òun tìkára rẹ̀ ló gbé e ró.
17 (B)Ó gbé òdodo wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbàyà rẹ̀,
àti àṣíborí ìgbàlà ní orí rẹ̀;
ó gbé ẹ̀wù ẹ̀san wọ̀
ó sì yí ara rẹ̀ ní ìtara bí ẹ̀wù.
18 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n ti ṣe,
bẹ́ẹ̀ ni yóò san án
ìbínú fún àwọn ọ̀tá rẹ̀
àti ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;
òun yóò san án fún àwọn erékùṣù ẹ̀tọ́ wọn.
19 (C)Láti ìwọ̀-oòrùn, àwọn ènìyàn yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa,
àti láti ìlà-oòrùn, wọn yóò bọ̀wọ̀ fún ògo rẹ̀.
Nítorí òun yóò wá gẹ́gẹ́ bí i rírú omi
èyí tí èémí Olúwa ń tì lọ.
20 (D)“Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni,
sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó
ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.
21 “Àti fún èmi, májẹ̀mú mi pẹ̀lú wọn nìyìí,” ni Olúwa wí, “Ẹ̀mí mi, tí ó wà nínú yín, àti ọ̀rọ̀ mi tí mo ti fi sí ẹnu yín, kì yóò kúrò lẹ́nu yín, tàbí lẹ́nu àwọn ọmọ yín, tàbí láti ẹnu àwọn ìrandíran wọn láti àkókò yìí lọ àti títí láéláé” ni Olúwa wí.
Ògo Sioni
60 “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,
ògo Olúwa sì ràdàbò ọ́.
2 Kíyèsi i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé
òkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,
ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́
ògo rẹ̀ sì farahàn lórí i rẹ.
3 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,
àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.
4 “Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò:
Gbogbo wọn ṣa ara jọ pọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;
àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin yóò wá láti ọ̀nà jíjìn,
àwọn ọmọ rẹ obìnrin ni a ó tọ́jú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ.
5 Nígbà náà ni ìwọ yóò wò tí ojú rẹ yóò máa dán,
ọkàn rẹ yó fò, yó sì kún fún ayọ̀;
ọrọ̀ inú Òkun ni a ó kò wá sọ́dọ̀ rẹ,
sí ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá.
6 (E)Ọ̀wọ́ ìbákasẹ yóò bo gbogbo ilẹ̀ rẹ,
àwọn ọ̀dọ́ ìbákasẹ Midiani àti Efani.
Àti gbogbo wọn láti Ṣeba yóò wá,
wọn yóò mú wúrà àti tùràrí lọ́wọ́
tí wọn yóò sì máa kéde ìyìn Olúwa.
7 Gbogbo agbo ẹran Kedari ni a ó kójọ sọ́dọ̀ rẹ,
àwọn àgbò ti Nebaioti yóò sìn ọ́;
wọn yóò jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà lórí i pẹpẹ mi,
bẹ́ẹ̀ ni n ó sì ṣe tẹmpili ògo mi lọ́ṣọ̀ọ́.
8 “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí ń fò lọ bí i kurukuru,
gẹ́gẹ́ bí àwọn àdàbà sí ìtẹ́ wọn?
9 Lóòtítọ́ àwọn erékùṣù bojú wò mí;
ní ìṣíwájú ni àwọn ọkọ̀ ojú omi Tarṣiṣi;
mú àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ wá láti ọ̀nà jíjìn,
pẹ̀lú fàdákà àti wúrà wọn,
fún ti ọlá Olúwa Ọlọ́run rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli,
nítorí òun ti fi ohun dídára ṣe ó lọ́ṣọ̀ọ́.
10 “Àwọn àjèjì yóò tún ògiri rẹ mọ
àwọn ọba wọn yóò sì sìn ọ́.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ní ìbínú ni mo lù ọ́,
ní àánú èmi yóò ṣe inú rere sí ọ.
11 (F)Gbogbo ẹnu-bodè rẹ ni yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀,
a kì yóò tì wọ́n ní ọ̀sán àti ní òru,
tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọkùnrin yóò le è kó
ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè wá
tí àwọn ọba wọn yóò ṣáájú ní
ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ ìṣẹ́gun.
12 Nítorí pé orílẹ̀-èdè tàbí ilẹ̀ ọba tí kì yóò sìn ọ́ ni yóò parun;
pátápátá ni yóò sì dahoro.
13 “Ògo Lebanoni yóò wá sí ọ̀dọ̀ rẹ,
igi junifa, firi àti sípírẹ́ṣì papọ̀,
láti bu ọlá fún ilé ìsìn mi;
àti pé èmi yóò sì ṣe ibi ẹsẹ̀ mi lógo.
14 (G)Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò
wá foríbalẹ̀ fún ọ;
gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ
wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa,
Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.
15 “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kórìíra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,
láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,
Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayé
àti ayọ̀ àtìrandíran.
16 Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀-èdè
a ó sì fun ọ́ ni ọmú àwọn ọba.
Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,
èmi ni Olùgbàlà rẹ,
Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jakọbu.
17 Dípò idẹ, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,
dípò fàdákà èmi ó mú irin wá. Dípò igi yóò mú idẹ wá fún ọ,
àti irin dípò òkúta.
Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe àwọn ìjòyè rẹ
àti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.
18 A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,
tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,
ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlà
àti àwọn ẹnu-bodè rẹ ní ìyìn.
19 Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,
tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,
nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,
àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.
20 Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,
àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́;
Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,
àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.
21 Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodo
àwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.
Àwọn ni irúgbìn tí mo ti gbìn,
iṣẹ́ ọwọ́ mi,
láti fi ọláńlá mi hàn.
22 Èyí tí ó kéré jù nínú yín yóò di ẹgbẹ̀rún kan,
èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀-èdè ńlá.
Èmi ni Olúwa;
ní àkókò rẹ̀ Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”
Ọdún ojúrere Olúwa
61 (H)Ẹ̀mí Olúwa Olódùmarè wà lára mi
nítorí Olúwa ti fi ààmì òróró yàn mí
láti wàásù ìhìnrere fún àwọn tálákà.
Ó ti rán mi láti ṣe àwòtán oníròbìnújẹ́
láti kéde ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn
àti ìtúsílẹ̀ kúrò nínú òkùnkùn fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n,
2 Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa
àti ọjọ́ ẹ̀san ti Ọlọ́run wa,
láti tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú,
3 àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni
láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú,
òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀,
àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn.
A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo,
irúgbìn Olúwa
láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.
4 Wọn yóò tún àwọn ahoro àtijọ́ kọ́
wọn yóò sì mú àwọn ibi ìparun àtijọ́-tijọ́ náà bọ̀ sípò;
wọn yóò jí àwọn ahoro ìlú náà padà
tí a ti parun láti ìrandíran sẹ́yìn.
5 Àwọn àjèjì ni yóò máa da ọ̀wọ́ ẹran rẹ;
àwọn àlejò yóò sì ṣiṣẹ́ nínú oko àti ọgbà àjàrà rẹ.
6 A ó sì máa pè yín ní àlùfáà Olúwa,
a ó pè yín ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run wa.
Ẹ ó máa jẹ nínú ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè
àti nínú ọrọ̀ wọn ni ẹ̀yin yóò máa ṣògo.
7 Dípò àbùkù wọn
àwọn ènìyàn mi yóò gba ìlọ́po méjì,
àti dípò àbùkù wọn
wọn yóò yọ̀ nínú ìní wọn;
bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jogún ìlọ́po méjì ní ilẹ̀ wọn,
ayọ̀ ayérayé yóò sì jẹ́ tiwọn.
8 “Nítorí Èmi, Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òdodo;
mo kórìíra olè jíjà àti ẹ̀ṣẹ̀
Ní òtítọ́ mi èmi yóò sẹ̀san fún wọn
èmi yóò sì dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú wọn.
9 A ó mọ ìrandíran wọn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
àti àwọn ìran wọn láàrín àwọn ènìyàn
Gbogbo àwọn tí ó bá rí wọn yóò mọ̀ pé
wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí Olúwa ti bùkún.”
10 Èmi yọ̀ gidigidi nínú Olúwa;
ọkàn mi yọ̀ nínú Ọlọ́run mi.
Nítorí ó ti wọ̀ mí ní aṣọ ìgbàlà
ó sì ṣe mí lọ́ṣọ̀ọ́ nínú aṣọ òdodo;
gẹ́gẹ́ bí ọkọ ìyàwó ti ṣe orí rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ bí àlùfáà,
àti bí ìyàwó ṣe ń ṣe ara rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́.
11 Gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ti í mú irúgbìn jáde
àti bí ọgbà ṣe ń mú irúgbìn dàgbà,
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Olódùmarè yóò ṣe mú òdodo àti ìyìn
kí ó ru sókè níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè.
Ẹ̀bẹ̀ àdúrà
3 (A)Ní àkótán, ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa, kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè máa tàn káàkiri, kí ó sì jẹ́ èyí tí a bu ọlá fún, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọ̀dọ̀ yín. 2 (B)Kí ẹ sì máa gbàdúrà fún wa kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìkà àti àwọn ènìyàn búburú, nítorí pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló ní ìgbàgbọ́. 3 (C)Ṣùgbọ́n olódodo ni Olúwa, ẹni tí yóò fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóò sì pa yín mọ́ kúrò nínú ibi. 4 Àwa sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ní ti ohun tí ẹ ń ṣe, àti pé àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a pàṣẹ fún un yín ni ẹ̀yin ń ṣe. 5 Kí Olúwa máa tọ́ ọkàn yín ṣọ́nà sí ìfẹ́ Ọlọ́run àti sínú sùúrù Kristi.
Ìkìlọ̀ ní ṣíṣe ìmẹ́lẹ́
6 (D)Ní orúkọ Jesu Kristi Olúwa wa, àwa pàṣẹ fún un yín ará, pé kí ẹ yẹra fún gbogbo àwọn arákùnrin yín tí ń ṣe ìmẹ́lẹ́, tí kò sì gbé ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀kọ́ tí ẹ gbà ní ọ̀dọ̀ wa. 7 (E)Nítorí ẹ̀yin náà mọ̀ bí ó ṣe yẹ kí ẹ máa fi ara wé wa. Àwa kì í ṣe ìmẹ́lẹ́ nígbà tí a wà ní ọ̀dọ̀ yín. 8 (F)Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán tòru kí a má ba à di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn. 9 (G)Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti béèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé. 10 (H)Nítorí nígbà tí àwa wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”
11 (I)A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrín yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlékiri. 12 (J)Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jesu Kristi Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ. 13 (K)Ṣùgbọ́n ní tiyín ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí agara dá yín ní rere ṣíṣe.
14 Bí ẹnikẹ́ni kò bá sì pa òfin wa nínú lẹ́tà yìí mọ́, ẹ ṣààmì sí ẹni náà. Ẹ má ṣe bá a kẹ́gbẹ́ kí ojú bà á le tì í. 15 Síbẹ̀, ẹ má ṣe kà á sí ọ̀tá, ṣùgbọ́n ẹ máa kìlọ̀ fún un gẹ́gẹ́ bí arákùnrin yín.
Ìkíni ìkẹyìn
16 (L)Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnrarẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.
17 (M)Èmi Paulu fi ọwọ́ ara mi kọ lẹ́tà ìkíni yìí, èyí ṣe ààmì ìdámọ̀ nínú gbogbo lẹ́tà. Bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyìí.
18 (N)Kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa wà pẹ̀lú yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.