Add parallel Print Page Options

33 (A)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:

“Kíyèsi, mo gbé òkúta ìkọ̀sẹ̀ kalẹ̀ ní Sioni
    àti àpáta tí ó mú wọn ṣubú,
ẹnikẹ́ni ti ó bá sì gbà a gbọ́, ojú kì yóò tì í.”

Read full chapter

11 (A)Nítorí ìwé Mímọ́ wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà a gbọ́ ojú kò yóò tì í.”

Read full chapter

Àpáta iyè àti ènìyàn tí a yàn

(A)Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye. Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi. (B)Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe:

“Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn,
    iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni:
ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́
    ojú kì yóò tì í.”

Read full chapter