Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 9-10

A bí ọmọ kan fún wa

(A)Síbẹ̀síbẹ̀, kò ní sí ìpòrúru kankan mọ́ fún àwọn tí ó wà nínú ìbànújẹ́. Nígbà kan rí ó rẹ ilẹ̀ Sebuluni sílẹ̀ àti ilẹ̀ Naftali pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú, yóò bu ọ̀wọ̀ fún Galili ti àwọn aláìkọlà, ní ọ̀nà Òkun, ní ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ Jordani.

Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn
    ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá;
Lórí àwọn tí ń gbé nínú ilẹ̀ òjìji ikú,
    ní ara wọn ni ìmọ́lẹ̀ mọ́ sí.
Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè di ńlá;
    wọ́n sì yọ̀ níwájú rẹ
gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ti í yọ ayọ̀ ìkórè,
    gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ti í yọ̀
    nígbà tí à ń pín ìkógun.
Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a ṣẹ́gun Midiani,
    ìwọ ti fọ́ ọ túútúú
àjàgà ti ń pa wọ́n lẹ́rù,
    ọ̀pá tí ó dábùú èjìká wọn,
    ọ̀gọ aninilára wọn.
Gbogbo bàtà jagunjagun tí a ti lò lójú ogun
    àti gbogbo ẹ̀wù tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀,
ni yóò wà fún ìjóná,
    àti ohun èlò iná dídá.
Nítorí a bí ọmọ kan fún wa,
    a fi ọmọkùnrin kan fún wa,
ìjọba yóò sì wà ní èjìká rẹ̀.
    A ó sì máa pè é ní: Ìyanu
Olùdámọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára
    Baba ayérayé, Ọmọ ọba aládé Àlàáfíà.
Ní ti ìgbòòrò Ìjọba rẹ̀ àti àlàáfíà rẹ̀ ni kì yóò ní ìpẹ̀kun.
    Yóò jẹ ọba lórí ìtẹ́ Dafidi
àti lórí ẹ̀kún un rẹ̀ gbogbo,
    nípa ìfìdímúlẹ̀ àti ìgbéró rẹ̀,
pẹ̀lú òtítọ́ àti òdodo
    láti ìgbà náà lọ àti títí láéláé.
Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ni yóò mú èyí ṣẹ.

Ìbínú Olúwa Sí Israẹli

Olúwa ti dojú iṣẹ́ kan kọ Jakọbu;
    Yóò sì wá sórí Israẹli.
Gbogbo ènìyàn ni yóò sì mọ̀ ọ́n—
    Efraimu àti gbogbo olùgbé Samaria—
tí ó sọ pẹ̀lú ìgbéraga
    àti gààrù àyà pé.
10 Àwọn bíríkì ti wó lulẹ̀
    ṣùgbọ́n a ó tún un kọ́ pẹ̀lú òkúta dídán,
a ti gé àwọn igi sikamore lulẹ̀
    ṣùgbọ́n igi kedari ní a ó fi dípò wọn.
11 Ṣùgbọ́n Olúwa fún àwọn ọ̀tá Resini ní agbára láti dojúkọ wọ́n
    ó sì ti rú àwọn ọ̀tá wọn sókè.
12 Àwọn ará Aramu láti ìlà-oòrùn àti Filistini láti ìwọ̀-oòrùn.
Wọ́n sì fi gbogbo ẹnu jẹ Israẹli run.

    Ní gbogbo èyí ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
    Ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.

13 Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tí ì yípadà
    sí ẹni náà tí ó lù wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
14 Nítorí náà ni Olúwa yóò ṣe ké àti orí àti ìrù
    kúrò ní Israẹli,
    àti ọ̀wá ọ̀pẹ àti koríko odò ní ọjọ́ kan ṣoṣo,
15 Àwọn àgbàgbà, àti àwọn gbajúmọ̀ ní orí,
    àwọn wòlíì tí ń kọ́ni ní irọ́ ni ìrù.
16 Àwọn tí ó ń tọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣì wọ́n lọ́nà
    Àwọn tí a sì tọ́ ni a ń sin sí ìparun.
17 Nítorí náà, Olúwa kì yóò dunnú sí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin
    tàbí kí ó káàánú àwọn aláìní baba àti opó,
nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ ìkà àti aláìmọ Ọlọ́run,
    ibi ni ó ti ẹnu wọn jáde.

Síbẹ̀, fún gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò
    ọwọ́ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

18 Nítòótọ́ ìwà búburú ń jóni bí iná,
    yóò jó ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún run,
yóò sì rán nínú pàǹtí igbó,
    tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi gòkè lọ bí ọ̀wọ́n èéfín ti í gòkè.
19 Nípasẹ̀ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    ilẹ̀ náà yóò di gbígbẹ
àwọn ènìyàn yóò sì di ohun ìdáná,
    ẹnìkan kì yóò sì dá arákùnrin rẹ̀ sí.
20 Ní apá ọ̀tún wọn yóò jẹrun,
    síbẹ̀ ebi yóò sì máa pa wọ́n,
ní apá òsì, wọn yóò jẹ
    ṣùgbọ́n, kò ní tẹ́ wọn lọ́rùn.
    Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò sì máa jẹ ẹran-ara apá rẹ̀.
21 Manase yóò máa jẹ Efraimu, nígbà tí Efraimu yóò jẹ Manase
    wọn yóò parapọ̀ dojúkọ Juda.

Síbẹ̀síbẹ̀, ìbínú un rẹ̀ kò yí kúrò
    Ọwọ́ọ rẹ̀ sì wà ní gbígbéró.

10 Ègbé ni fún àwọn ti ń ṣe òfin àìṣòdodo
láti dún àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn
    àti láti fa ọwọ́ ìdájọ́ sẹ́yìn kúrò
níwájú àwọn olùpọ́njú ènìyàn mi,
    Wọ́n sọ àwọn ọ̀pọ̀ di ìjẹ fún wọn.
    Wọ́n sì ń ja àwọn aláìní baba lólè.
Kí ni ìwọ yóò ṣe ní ọjọ́ ìṣirò
    nígbà tí ìparun bá ti ọ̀nà jíjìn wá?
Ta ni ìwọ yóò sá tọ̀ fún ìrànlọ́wọ́?
    Níbo ni ìwọ yóò fi ọrọ̀ rẹ sí?
Ohunkóhun kò ní ṣẹ́kù mọ́ bí kò ṣe láti tẹ̀ ba láàrín àwọn ìgbèkùn
    tàbí kí o ṣubú sáàrín àwọn tí a pa.

Pẹ̀lú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ìbínú rẹ̀ kò kúrò,
    ọwọ́ rẹ̀ sì tún gbé sókè.

Ìdájọ́ Ọlọ́run Lórí Asiria

(B)“Ègbé ni fún àwọn ará Asiria, ọ̀gọ ìbínú mi,
    ní ọwọ́ ẹni tí kùmọ̀ ìbínú mi wà!
Mo rán an sí orílẹ̀-èdè aláìní Ọlọ́run
    Mo dojú rẹ̀ kọ àwọn ènìyàn tí ó mú mi bínú
láti já ẹrù gbà, àti láti kó ìkógun
    láti tẹ̀ mọ́lẹ̀ bí amọ̀ ní ojú òpópó.
Ṣùgbọ́n, èyí kì í ṣe ohun tí ó fẹ́ ṣe,
    èyí kọ́ ni ohun tí ó ní lọ́kàn;
èrò rẹ̀ ni láti parun,
    láti fi òpin sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.
‘Kì í ha ṣe pé ọba ni gbogbo àwọn aláṣẹ mi?’ ni Olúwa wí.
‘Kì í ha ṣe pé Kalno dàbí i Karkemiṣi?
    Hamati kò ha dàbí i Arpadi,
    àti Samaria bí i Damasku?
10 Gẹ́gẹ́ bí ọwọ́ mi ti gbá ìjọba àwọn òrìṣà mú,
    ìjọba tí ère rẹ̀ pọ̀ ju ti Jerusalẹmu àti Samaria lọ.
11 Èmi kì yóò a bá Jerusalẹmu wí àti àwọn ère rẹ̀?’ ”
    Gẹ́gẹ́ bí mo ṣe ṣe sí Samaria àti àwọn ère rẹ̀?

12 Nígbà tí Olúwa ti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ sí òkè Sioni àti Jerusalẹmu, yóò sọ wí pé, “Èmi yóò fi ìyà jẹ ọba Asiria nítorí gààrù àyà rẹ̀ àti ìgbéraga ojú rẹ̀. 13 Nítorí ó sọ pé:

“ ‘Pẹ̀lú agbára ọwọ́ mi ni mo fi ṣe èyí
    àti pẹ̀lú ọgbọ́n ọ̀n mi, nítorí mo ní òye.
Mo mú ààlà àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,
    Mo sì ti kó ìṣúra wọn.
    Gẹ́gẹ́ bí alágbára kan, mo borí àwọn ọba wọn.
14 Bí ènìyàn ti í tọwọ́ bọ ìtẹ́ ẹyẹ,
    bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi tẹ ọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.
Bí ènìyàn ti í kó ẹyin tí a kọ̀sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni mo kó àwọn orílẹ̀-èdè
kò sí èyí tí ó fi apá lu apá,
    tàbí kí ó ya ẹnu láti dún.’ ”

15 Ǹjẹ́ àáké le gbé ara rẹ̀ sókè kọjá ẹni tí ó ń fì í,
    tàbí kí ayùn fọ́nnu sí ẹni tí ó ń lò ó?
Àfi bí ẹni pé ọ̀pá ó na ẹni tí ó gbé e sókè,
    tàbí kí kùmọ̀ lu èyí tí kì í ṣe igi.
16 Nítorí náà, ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    yóò rán ààrùn ìrẹ̀dànù sórí
àwọn akíkanjú jagunjagun,
    lábẹ́ ògo rẹ̀ ni iná kan yóò ti sọ
    gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun.
17 Ìmọ́lẹ̀ Israẹli yóò di iná,
    Ẹni Mímọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ọ̀wọ́-iná,
ní ọjọ́ kan ṣoṣo yóò jó yóò sì run
    àti ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n.
18 Gbogbo ẹwà igbó o rẹ̀, àti àwọn pápá ọlọ́ràá
    gbogbo rẹ̀ ni yóò run pátápátá,
gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ṣàìsàn ti í ṣòfò dànù.
19 Àwọn igi tí yóò kù nínú igbó o rẹ̀
    yóò kéré níye,
    tí ọ̀dọ́mọdé yóò fi le kọ̀ wọ́n sílẹ̀.

Àwọn ìyókù Israẹli

20 Ní ọjọ́ náà, àwọn tí ó ṣẹ́kù ní Israẹli,
    Àwọn tí ó yè ní ilé e Jakọbu,
kò ní gbẹ́kẹ̀lé ẹni náà
    tí ó lù wọ́n bolẹ̀,
ṣùgbọ́n ní òtítọ́ yóò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa
    Ẹni Mímọ́ Israẹli.
21 Àwọn ìyókù yóò padà, àwọn ìyókù ti Jakọbu
    yóò padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Alágbára.
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ Israẹli
    dàbí yanrìn ní Òkun,
ẹni díẹ̀ ni yóò padà.
    A ti pàṣẹ ìparun
    àkúnwọ́sílẹ̀ àti òdodo.
23 Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni yóò mú un ṣẹ,
    ìparun tí a ti pàṣẹ rẹ̀ lórí
    gbogbo ilẹ̀ náà.

24 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí,

    “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí ó ń gbé Sioni,
Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn Asiria,
    tí ó ń fi ọ̀pá lù yín,
tí wọ́n sì ń gbé ọ̀gọ tì yín bí
    Ejibiti ti ṣe.
25 Láìpẹ́, ìbínú mi sí i yín yóò wá sí òpin
    n ó sì dojú ìrunú mi kọ wọ́n,
    fún ìparun wọn.”

26 Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò nà wọ́n ní ẹgba.
    Gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lu Midiani
ní òkè Orebu,
    yóò sì gbé ọ̀pá rẹ̀ lé orí omi
    gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Ejibiti.
27 Ní ọjọ́ náà, a ó gbé ẹrù wọn kúrò ní èjìká a yín,
    àti àjàgà a wọn kúrò ní ọrùn un yín
a ó fọ́ àjàgà náà,
    nítorí pé ẹ̀yin ó ti sanra.

28 Wọ́n wọ Aiati,
    Wọ́n gba Migroni kọjá
    Wọ́n kó nǹkan pamọ́ sí Mikmasi.
29 Wọ́n ti rékọjá ọ̀nà, wọ́n wí pé,
    “Àwa ó tẹ̀dó sí Geba lóru yìí.”
Rama mì tìtì
    Gibeah ti Saulu sálọ.
30 Gbé ohùn rẹ sókè, ìwọ ọmọbìnrin Galimu!
    Dẹ etí sílẹ̀, ìwọ Laiṣa!
    Ìwọ òtòṣì Anatoti!
31 Madmena ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ
    Àwọn ènìyàn Gebimu ti fi ara pamọ́.
32 Ní ọjọ́ yìí, wọn yóò dúró ní Nobu
    wọn yóò kan sáárá,
ní òkè ọmọbìnrin Sioni
    ní òkè Jerusalẹmu.

33 Wò ó, Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    yóò kán ẹ̀ka náà sọnù pẹ̀lú agbára.
Àwọn igi ọlọ́lá ni a ó gé lulẹ̀
    àwọn tí ó ga gogoro ni a ó rẹ̀ sílẹ̀.
34 Òun yóò gé igbó dídí pẹ̀lú àáké,
    Lebanoni yóò ṣubú níwájú Alágbára náà.

Efesu 3

Paulu jẹ́ oníwàásù sí àwọn aláìkọlà

Nítorí èyí náà ni èmi Paulu ṣe di òǹdè Jesu Kristi nítorí ẹ̀yin aláìkọlà.

(A)Lóòtítọ́ ẹ̀yin tilẹ̀ ti gbọ́ ti iṣẹ́ ìríjú oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, tí a fi fún mi fún yín; bí ó ti ṣe pé nípa ìfihàn ni ó ti fi ohun ìjìnlẹ̀ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí mo ti kọ ṣáájú ni ṣókí, Nígbà tí ẹ̀yin bá kà á, nípa èyí tí ẹ̀yin o fi lè mọ òye mi nínú ìjìnlẹ̀ Kristi. Èyí tí a kò í tí ì fihàn àwọn ọmọ ènìyàn rí nínú ìran mìíràn gbogbo, bí a ti fi wọ́n hàn nísinsin yìí fún àwọn aposteli rẹ̀ mímọ́ àti àwọn wòlíì nípa Ẹ̀mí; (B)pé, àwọn aláìkọlà jẹ́ àjùmọ̀jogún àti ẹ̀yà ara kan náà, àti alábápín ìlérí nínú Kristi Jesu nípa ìhìnrere.

Ìránṣẹ́ èyí tí a fi mi ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fi fún mi, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀. Fún èmi tí o kéré jùlọ nínú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ní a fi oore-ọ̀fẹ́ yìí fún, láti wàásù àwámárídìí ọ̀rọ̀ Kristi fún àwọn aláìkọlà; (C)àti láti mú kí gbogbo ènìyàn rí ohun tí iṣẹ́ ìríjú ohun ìjìnlẹ̀ náà jásí, èyí tí a ti fi pamọ́ láti ìgbà àtijọ́ nínú Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ohun gbogbo nípa Jesu Kristi: 10 Kí a bá à lè fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú ọgbọ́n Ọlọ́run hàn nísinsin yìí fún àwọn ìjòyè àti àwọn alágbára nínú àwọn ọ̀run, nípasẹ̀ ìjọ, 11 gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ayérayé tí ó ti pinnu nínú Kristi Jesu Olúwa wa: 12 Nínú ẹni tí àwa ní ìgboyà, àti ọ̀nà pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé nípa ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀. 13 Nítorí náà, mo bẹ̀ yín kí àárẹ̀ má ṣe mú yín ni gbogbo wàhálà mi nítorí yín, èyí tí ṣe ògo yín.

Àdúrà fún àwọn ará Efesu

14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.

20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.