Old/New Testament
Ọgbọ́n n fi ìpè síta
8 (A)Ǹjẹ́ ọgbọ́n kò ha ń kígbe síta?
Òye kò ha ń gbé ohùn rẹ sókè?
2 Ní ibi gíga ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà
ní ìkóríta, ní ó dúró;
3 Ní ẹgbẹ́ ibodè tí ó wọ ìlú,
ní ẹnu ibodè ni ó ń kígbe sókè:
4 Sí i yín ẹ̀yin ènìyàn, ní mo ń kígbe pè;
Mo gbé ohun mi sókè sí gbogbo ènìyàn,
5 Ẹ̀yin aláìmọ̀kan, ẹ kọ́gbọ́n;
ẹ̀yin aṣiwèrè, ẹ gba òye.
6 Ẹ gbọ́, nítorí tí èmi ó sọ̀rọ̀ ohun iyebíye;
Èmí ṣí ètè mi láti sọ ohun tí ó tọ́,
7 Ẹnu mi ń sọ ohun tí í ṣe òtítọ́,
nítorí ètè mi kórìíra ibi.
8 Gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi ni ó tọ́,
kò sí èyí tí ó jẹ́ ẹ̀tàn tàbí àyídáyidà níbẹ̀
9 Fún olóye gbogbo rẹ̀ ni ó tọ̀nà;
wọ́n jẹ́ aláìlẹ́gàn fún gbogbo ẹni tí ó ní ìmọ̀.
10 Yan ẹ̀kọ́ mi dípò fàdákà,
ìmọ̀ dípò o wúrà àṣàyàn,
11 Nítorí ọgbọ́n ṣe iyebíye jù iyùn lọ,
kò sí ohun tí ọkàn rẹ̀ fẹ́ tí a sì le fiwé e.
12 “Èmi, ọgbọ́n ń gbé pẹ̀lú òye;
mo ní ìmọ̀ àti ọgbọ́n-inú.
13 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìkórìíra ibi
mo kórìíra ìgbéraga àti agídí,
ìwà ibi àti ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.
14 Ìmọ̀ràn àti ọgbọ́n tí ó yè kooro jẹ́ tèmi
mo ní òye àti agbára.
15 Nípasẹ̀ mi ni ọba ń ṣàkóso
tí àwọn aláṣẹ sì ń ṣe òfin tí ó dára
16 Nípasẹ̀ mi àwọn ọmọ-aládé ń ṣàkóso
àti gbogbo ọlọ́lá tí ń ṣàkóso ilẹ̀ ayé.
17 Mo fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn mi
àwọn tí ó sì wá mi rí mi.
18 Lọ́dọ̀ mi ni ọrọ̀ àti ọlá wà
ọrọ̀ tí í tọ́jọ́ àti ìgbéga rere.
19 Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ;
ohun tí mò ń mú wá ju àṣàyàn fàdákà lọ.
20 Mò ń rìn ní ọ̀nà òdodo,
ní ojú ọ̀nà òtítọ́,
21 Mò ń fi ọrọ̀ fún gbogbo àwọn tí ó fẹ́ràn mi
mo sì ń mú kí ilé ìṣúra wọn kún.
22 “Èmi ni Olúwa kọ́kọ́ dá nínú iṣẹ́ rẹ̀.
Ṣáájú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ àtijọ́;
23 A ti yàn mí láti ayérayé,
láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, kí ayé tó bẹ̀rẹ̀.
24 Nígbà tí kò tí ì sí Òkun, ni a ti bí mi
nígbà tí kò tí ì sí ìsun tí ó ní omi nínú;
25 kí a tó fi àwọn òkè sí ipò wọn,
ṣáájú àwọn òkè ni a ti bí mi,
26 kí ó tó dá ilẹ̀ ayé tàbí àwọn oko rẹ̀
tàbí èyíkéyìí nínú eruku ayé.
27 Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn,
nígbà tí ó fi òṣùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
28 Nígbà tí ó ṣẹ̀dá òfúrufú lókè
tí ó sì fi orísun ibú omi sí ipò rẹ̀ láì le è yẹsẹ̀,
29 Nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun
kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀,
àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.
30 Nígbà náà èmi ni gbẹ́nàgbẹ́nà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀
mo kún fún inú dídùn lójoojúmọ́,
mo ń yọ̀ nígbà gbogbo níwájú rẹ̀.
31 Mo ń yọ̀ nínú gbogbo àgbáyé tí ó dá
mo sì ní inú dídùn sí àwọn ọmọ ènìyàn.
32 “Nítorí náà báyìí, ẹ̀yin ọmọ mi,
ìbùkún ni fún àwọn tí ó pa ọ̀nà mi mọ́,
33 Fetí sí ìtọ́sọ́nà mi kí o sì gbọ́n;
má ṣe pa á tì sápá kan.
34 Ìbùkún ni fún ẹni tí ó fetísílẹ̀ sí mi,
tí ń ṣọ́nà ní ẹnu-ọ̀nà mi lójoojúmọ́,
tí ń dúró ní ẹnu-ọ̀nà mi.
35 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi rí ìyè
ó sì rí ojúrere gbà lọ́dọ̀ Olúwa.
36 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ láti rí ń pa ara rẹ̀ lára
gbogbo ẹni tí ó kórìíra mi fẹ́ ikú.”
Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n
9 Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,
ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
2 ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.
Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
3 ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,
láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
4 “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”
Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé
5 “Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi
sì mu wáìnì tí mo ti pò.
6 Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;
rìn ní ọ̀nà òye.
7 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù
ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
8 Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.
Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
9 kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i
kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,
ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.
11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:
bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;
ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.
14 Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,
15 ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,
tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
16 “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”
Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
17 “Omi tí a jí mu dùn
oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
18 Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀,
pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.
3 (A)Àwa ha tún bẹ̀rẹ̀ láti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí láti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe? 2 Ẹ̀yin fúnrayín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. 3 (B)Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.
4 Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run: 5 Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà; 6 Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè.
Ògo tó wà nínú májẹ̀mú tuntun
7 (C)Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ); 8 yóò ha ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù? 9 Nítorí pé bi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo. 10 Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ. 11 Nítorí pé bí èyí ti ń kọjá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo!
12 Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fi ìgboyà púpọ̀ sọ̀rọ̀. 13 Kì í sì í ṣe bí Mose, ẹni tí ó fi ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Israẹli má ba à lè tẹjúmọ́ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ 14 Ṣùgbọ́n ojú inú wọn fọ́; nítorí pé títí fi di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mú láéláé, ìbòjú kan náà ṣì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kristi ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò. 15 Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbàkúgbà ti a bá ń ka Mose, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kàn wọn. 16 Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò. 17 (D)Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbi tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnira gbé wà 18 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjìji, a sì ń pa wa dà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.