Old/New Testament
Orin ọgbà àjàrà náà
5 (A)Èmi yóò kọrin fún ẹni tí mo fẹ́ràn
orin kan nípa ọgbà àjàrà rẹ̀;
Olùfẹ́ mi ní ọgbà àjàrà kan
ní ẹ̀gbẹ́ òkè ẹlẹ́tù lójú.
2 Ó tu ilẹ̀ rẹ̀, ó ṣa òkúta ibẹ̀ kúrò
ó sì gbin àyànfẹ́ àjàrà sí i.
Ó kọ́ ilé ìṣọ́ sí inú rẹ̀
ó sì ṣe ìfúntí kan síbẹ̀ pẹ̀lú.
Lẹ́yìn náà, ó ń retí èso àjàrà dáradára,
ṣùgbọ́n èso búburú ni ó ti ibẹ̀ wá.
3 “Ní ìsinsin yìí ẹ̀yin olùgbé Jerusalẹmu
àti ẹ̀yin ènìyàn Juda
ẹ ṣe ìdájọ́ láàrín èmi àti
ọgbà àjàrà mi.
4 Kín ni ó kù tí n ò bá túnṣe sí ọgbà àjàrà mi.
Ju èyí tí mo ti ṣe lọ?
Nígbà tí mo ń wá èso dáradára,
èéṣe tí ó fi so kíkan?
5 Ní ìsinsin yìí, èmi yóò wí fún ọ
ohun tí n ó ṣe sí ọgbà àjàrà mi:
Èmi yóò gé igi inú rẹ̀ kúrò,
a ó sì pa á run,
Èmi yóò wó ògiri rẹ̀ lulẹ̀
yóò sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀.
6 Èmi yóò sì sọ ọ́ di ahoro
láì kọ ọ́ láì ro ó,
ẹ̀wọ̀n àti ẹ̀gún ni yóò hù níbẹ̀.
Èmi yóò sì pàṣẹ fún kurukuru
láti má ṣe rọ̀jò sórí i rẹ̀.”
7 Ọgbà àjàrà Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ni ilé Israẹli
àwọn ọkùnrin Juda
sì ni àyànfẹ́ ọgbà rẹ̀.
Ó retí ìdájọ́ ẹ̀tọ́ ṣùgbọ́n, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ ni ó rí,
Òun ń retí òdodo ṣùgbọ́n ó gbọ́ ẹkún ìpayínkeke.
Ègún àti ìdájọ́
8 Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé
tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀
tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù
tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.
9 Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:
“Ó dájú pé àwọn ilé ńláńlá
yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.
10 Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú
ìkòkò wáìnì kan wá,
nígbà tí òṣùwọ̀n homeri kan yóò mú
agbọ̀n irúgbìn kan wá.”
11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde
ní kùtùkùtù òwúrọ̀
láti lépa ọtí líle,
tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́
títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.
12 Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,
ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,
ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
13 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò
lọ sí ìgbèkùn
nítorí òye kò sí fún wọn,
ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ
yóò sì gbẹ.
14 Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,
ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,
nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí
pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.
15 Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
17 Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.
18 Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,
àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,
19 sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,
jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,
jẹ́ kí ó súnmọ́ bí
jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,
kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”
20 Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,
tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,
tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.
21 Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn
tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.
22 Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu
àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
23 tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.
24 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ahọ́n iná ṣe ń jó àgékù koríko run
àti bí koríko ṣe rẹlẹ̀ wẹ̀sì nínú iná,
bẹ́ẹ̀ ni egbò wọn yóò jẹrà
tí òdodo wọn yóò sì fẹ́ lọ bí eruku:
nítorí pé wọ́n ti kọ òfin Olúwa àwọn ọmọ-ogun sílẹ̀
wọ́n sì gan ọ̀rọ̀ Ẹni mímọ́ Israẹli.
25 Nítorí náà, ìbínú Olúwa gbóná si àwọn ènìyàn rẹ̀,
ó ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó sì lù wọ́n bolẹ̀.
Àwọn òkè sì wárìrì,
òkú wọn sì dàbí ààtàn ní àárín ìgboro.
Pẹ̀lú gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò yí kúrò,
ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ rẹ̀ sì ná jáde síbẹ̀.
26 Yóò sì gbé ọ̀págun sókè sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà,
yóò sì kọ sí wọn tí ó wà ní ìpẹ̀kun ilẹ̀.
Sì kíyèsi, wọ́n yóò yára wá kánkán.
27 Kò sí ẹni tí yóò rẹ̀ nínú wọn, tàbí tí yóò kọsẹ̀,
kò sí ẹni tí yóò tòògbé tàbí tí yóò sùn;
bẹ́ẹ̀ ni àmùrè ẹ̀gbẹ́ wọn kì yóò tú,
bẹ́ẹ̀ ni okùn sálúbàtà wọn kì yóò ja.
28 Àwọn ọfà wọn múná,
gbogbo ọrun wọn sì le;
pátákò àwọn ẹṣin wọn le bí òkúta akọ,
àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọn sì dàbí ìjì líle.
29 Bíbú wọn dàbí tí kìnnìún,
wọ́n bú bí ẹgbọrọ kìnnìún,
wọ́n ń kọ bí wọ́n ti di ẹran ọdẹ wọn mú
tí wọn sì gbé e lọ láìsí ẹni tí yóò gbà á là.
30 Ní ọjọ́ náà, wọn yóò hó lé e lórí
gẹ́gẹ́ bí i rírú omi Òkun.
Bí ènìyàn bá sì wo ilẹ̀,
yóò rí òkùnkùn àti ìbànújẹ́;
pẹ̀lúpẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn pẹ̀lú kurukuru rẹ̀.
Ìpè sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ Isaiah
6 Ní ọdún tí ọba Ussiah kú, mo rí Olúwa tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga tí a gbé sókè, ìṣẹ́tí aṣọ ìgúnwà rẹ̀ sì kún inú tẹmpili. 2 Àwọn Serafu wà ní òkè rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ìyẹ́ mẹ́fà, wọ́n fi ìyẹ́ méjì bo ojú wọn, wọ́n fi méjì bo ẹsẹ̀ wọn, wọ́n sí ń fi méjì fò. 3 (B)Wọ́n sì ń kọ sí ara wọn wí pé:
“Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”
4 (C)Nípa ìró ohùn un wọn, òpó ìlẹ̀kùn àti gbogbo ògiri ilé náà sì mì tìtì, gbogbo inú tẹmpili sì kún fún èéfín.
5 Mo kígbe pé “Ègbé ni fún mi! Mo ti gbé!” Nítorí mo jẹ́ ènìyàn aláìmọ́ ètè, mo sì ń gbé láàrín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ètè, ojú mi sì ti rí ọba, Olúwa àwọn ọmọ-ogun jùlọ.
6 Nígbà náà ni ọ̀kan nínú àwọn Serafu wọ̀nyí fò wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀yín iná ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó ti fi ẹ̀mú mú ní orí pẹpẹ. 7 Èyí ni ó fi kàn mí ní ẹnu tí ó sì wí pé, “Wò ó, èyí ti kan ètè rẹ; a ti mú ẹ̀bi rẹ kúrò, a sì ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.”
8 Nígbà náà ni mo sì gbọ́ ohùn Olúwa wí pé, “Ta ni èmi yóò rán? Ta ni yóò sì lọ fún wa?”
Nígbà náà ni èmi sì wí pé, “Èmi nìyí, rán mi!”
9 (D)Òun sì wí pé, “Tọ àwọn ènìyàn yìí lọ kí o sì wí fún wọn pé:
“ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́, kì yóò sì yé e yín;
ní rí rí ẹ̀yin yóò ri, ẹ̀yin kì yóò mọ òye.’
10 Mú kí àyà àwọn ènìyàn wọ̀nyí yigbì,
mú kí etí wọn kí ó wúwo,
kí o sì dìwọ́n ní ojú.
Kí wọn kí ó má ba fi ojú wọn ríran,
kí wọn kí ó má ba fi etí wọn gbọ́rọ̀,
kí òye kí ó má ba yé ọkàn wọn,
kí wọn kí ó má ba yípadà
kí a má ba mú wọn ní ara dá.”
11 Nígbà náà ni mo wí pé, “Báwo ni yóò ti pẹ́ tó Olúwa?”
Òun sì dáhùn pé:
“Títí àwọn ìlú ńlá yóò fi dahoro,
láìsí olùgbé nínú rẹ̀ mọ́,
títí tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ènìyàn,
títí tí ilẹ̀ yóò fi dahoro pátápátá.
12 Títí tí Olúwa yóò fi rán gbogbo wọn jìnnà réré
tí ilẹ̀ náà sì di ìkọ̀sílẹ̀ pátápátá.
13 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdámẹ́wàá ṣẹ́kù lórí ilẹ̀ náà,
yóò sì tún pàpà padà di rírun.
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí igi tẹrẹbinti àti igi óákù,
ti í fi kùkùté sílẹ̀ nígbà tí a bá gé wọn lulẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni irúgbìn mímọ́ náà yóò di kùkùté ní ilẹ̀ náà.”
1 Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,
Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:
2 Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.
Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi
3 (A)Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. 4 Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ 5 Ẹni tí Ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀ 6 (B)fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí Ó ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀: 7 (C)Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run 8 èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, 9 Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 10 (D)èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.
11 Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12 kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. 13 Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìhìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 14 (E)èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.
Ìdúpẹ́ àti àdúrà
15 (F)Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 16 (G)Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi; 17 Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 18 (H)Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19 àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, 20 (I)èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. 21 (J)Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. 22 (K)Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, 23 (L)èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.